You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Njẹ́ o ti gbọ̀ nípa ààrùn Dengue tó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ Naijiria?
Ajọ to n dena ajakalẹ aarun ni Naijiria, NCDC, ti fidi rẹ mulẹ pe aarun Dengue ti ran awọn eeyan kan nipinlẹ sokoto.
Gẹgẹ bi iroyin ti ajọ ilera l’agbaye, WHO, fi sita, aarun Dengue jẹ eyi to ma n ran eeyan lati ara ẹfọn.
Ajọ NCDC sọ pe eeyan mọkanlelaadọrin ni awọn fura si pe o ti ni aarun naa nipinlẹ Sokoto, wọn ti fidi eeyan mẹtadinlogun mii to ni mulẹ. Amọ ko ti i ṣeku pa ẹnikẹni.
“Lọwọlọwọ, ijọba ibilẹ mẹta nipinlẹ Sokoto, ni wọn ti ri aarun naa”
Sokoto South – 60
Wamako – 3
Dange Shuni – 1
Ajọ NCDC sọ pe oun n ṣe gbogbo nnkan to yẹ, pẹlu ajọṣepọ awọn ajọ miran lori aarun naa. Wọn ni ọwọja aarun naa ko ti i lagbara ju bo ṣe yẹ lọ ni Naijiria, niwọn igba to jẹ pe ipinlẹ Sokoto nikan ṣi lo wa.
“Koda ni Sokoto paapaa, ijọba ibilẹ mẹta ninu mẹrindinlọgbọn ni aarun Dengue wa, ti ko si ti i pa ẹnikẹni.”
Bakan naa ni wọn ni Naijiria ti mura silẹ fun itankalẹ aarun naa.
Awọn apẹẹrẹ ti aarun Dengue ma n fihan
Ajọ World Health Organisation sọ pe Dengue wa lara aarun mẹwaa akọkọ to n dunkooko mọ ilera l’agbaye.
O jẹ ẹyọkan ninu awọn aarun to n yara tan kalẹ lara awọn aarun to n ti ara ẹfọn wa. Ilaji awọn eeyan to wa laye lo si wa ninu ewu lati ni i.
Ẹya ẹfọn ti wọn n pe ni Aedes aegypti ati Aeded albopictus, lo ma n pin aarun Dengue.
Pupọ eeyan to ba ni Dengue, ni kii fi apẹẹrẹ kankan han, tabi ko jẹ apẹẹrẹ diẹ to le waye fun ọjọ meji si meje.
Fun awọn eeyan kan, Dengue ma n di nnkan nla sinu agọ ara wọn pẹlu apẹẹrẹ bi eebi, ki ẹjẹ ma a jade lati inu erigi ẹnu wọn tabi imu. Bakan naa ni ẹdọ wọn le wu.
Itọju pajawiri ni wọn gbọdọ fun ẹni to ba ti n ri iru awọn apẹẹrẹ bayii, nitori pe o le yọri si iku.
Ayẹwo ti wọn n pe ni polymerase chain reaction (PCR) ni wọn le fi da aarun naa mọ, amọ ko ti i si iwosan fun un.
Abẹrẹ ajẹsara kan ti wa fun Dengue, orilẹ-ede diẹ si ti fi ọwọ si lilo rẹ, ṣugbọn ko ti i wọpọ ni Africa.
Bi o ṣe le dena aarun Dengue
Dokita kan ni ileewosan ijọba to wa nilu rigasa nipinlẹ Kaduna, Usman Qalbusunnah, sọ pe ọna lati dena Dengue ko yatọ si idena aisan iba.
Lara awọn ọna na ni lilo áwọn apẹfọn, ati gbigbe ni ayika to mọ, ti ko si ni adagun omi.