You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ni àrùn anthrax, àti pé báwo ni àrùn náà ṣe burú tó?
Ajọ WHO sọ lọjọ Aje pe orilẹ-ede marun un ni ila oorun ati guusu Afrika ni arun anthrax ti ṣẹyọ.
WHO ni nnkan bii ẹgbẹrun kan ati ọgọrun un eeyan ni awọn fura si pe o ti lugbadi arun ọhun, amọ ayẹwo ti fi han pe eeyann mẹtadinlogoji lo ti ni arun naa nigba ti arun ọhun ti mu ẹmi ogun eeyan lọ ni Kenya, Malawi, Uganda, Zambia ati Zimbabwe.
Gẹgẹ bii ohun ti ajọ naa sọ, ọdọdun ni arun ọhun maa n jade lawọn orilẹ-ede naa.
Ninu awọn orilẹ-ede marun un wọnyii, Zabia ni arun ọhun ti milẹ titi julọ lẹyin to ti ṣẹyọ ni mẹsan an ninu ẹkun mẹwaa to wa nibẹ.
Logunjọ, oṣu Kọkanla, odun 2023, eeyan 684 ni igbagbọ wa pe o ni arun naa nigba ti ayẹwo fidi marundinlọgbọn mulẹ, ti eeyan mẹrin si jade laye.
Ki ni arun anthrax maa n ṣe si agọ ara eeyan?
Orukọ antrax yii jẹyọ ọrọ kan nin ninu ede Greek ‘anthrakis’ to n tumọ si eedu latari ohun to maa n ṣe si awọ ara eeyan.
Awọn ohun ọsin ni anthrax ṣaba maa n kọlu amọ o le ran eeyan ti wọn ba fara kan ẹranko to ni arun naa tabi ti wọn ba jẹ ẹran rẹ.
Iwadii fi han pe kokoro ‘Bacillus anthracis’ lo n ṣokunfa anthrax, eyii to maa n farapamọ sinu erupẹ fun ọpọ ọdun ko to wọ agọ ara ẹranko nipa ọgbẹ tabi egbo.
Ki ni awọn apẹrẹ anthrax?
Arun anthrax le farahan ni ọna mẹji gẹgẹ bii ohun ti ajọ WHO sọ:
- Anthrax ni awọ ara – eyii maa n waye ti kokoro arun naa ba wọle lati ipasẹ oju ọgbẹ. Lara apẹrẹ rẹ ni ki eeyan maa bi tabi ko maa ni ẹfọri
- gastrointestinal anthrax maa n jẹyọ bii igba ti eeyan ba jẹ majele ounjẹ amọ o ṣaba maa farahan bii inu rirun, igbẹ gbuuru ati ki eeyan maa bi ẹjẹ lati ẹnu
- pulmonary anthrax lo buru ninu apẹrẹ mẹtẹta to maa n kọkọ farahan bii otutu, eyii to maa n mu ko ṣoro fun eeyan lati mi.
Bawo ni anthrax ṣe buru to?
Awọn to ba fara kasa arun yii gbọdọ lọ sile iwosan, wọn si gbọdọ gba itọju kan ti wọn n pe ni ‘prophylactic treatment.’
Bo tilẹ jẹ pe awọn oogun to n gbogun ti kokoro aifojuri bii penicillin le koju anthrax, ẹnikẹni to ba lugabdi rẹ gbọdọ bẹrẹ itọju ni kankan.
Lai si itọju, ida 20% eeyan to ba lugbadi anthrax lo maa jade laye gẹgẹ bii ọrọ ajọ to n gbọgun ti ajakalẹ arun nilẹ Amẹrika, CDC.
Amọ ṣa nibi ti itọju to peye ba wa, gbogbo awọn to ba lugbadi arun naa ni yoo ye e.
‘Gastrointestinal anthrax’ to buru julọ ninu ẹka arun naa maa n waye ti eeyan ba jẹ ẹran ara ẹranko to ni arun naa lara lai kọkọ se ẹran naa, eyii to le yọri si iku. Lai si itọju, idaji awọn to ni irufẹ anthrax yii maa n ku, ṣugbọn ti wọn ba ri itọju, CDC ni ida 60% ni yoo ye.
‘Inhalation anthrax’ lo buru ju ninu gbogbo wọn, o si le gbẹmi eeyan ti wọn ko ba tọju ẹni to ni lara daadaa amọ ṣa, ida 55% awọn to ko ẹka arun naa lo n ye.
Bawo ni o ṣe le lo anthrax bii ohun ija oloro?
O ṣeeṣe lati sọ anthrax di ohun ija oloro nitori ara ohun ẹlẹmi lo maa n wa, o si ṣeeṣe fun awọn onimọ ijinlẹ lati pelo rẹ ninu laabu.
Ẹni to yoo ba pilẹ rẹ gbọdọ ni awọn irinṣẹ igbalode lati bẹrẹ iṣẹ.
Wọn le yọnda arun naa si agbegbe kan ti ẹnikẹni ko si ni mọ nipa rẹ.
Ẹni to ba fẹ yọnda rẹ si agbegbe le fi sinu ounjẹ, ẹfun ati omi, eyii ti yoo ṣoro lati gboorun.
Lọdun 2001, awọn kọlọrọsi kan fi arun naa ṣọwọ si awọn oloṣelu ilẹ Amẹrika atawọn ileeṣẹ iroyin kan lẹyin ikọlu ẹgbẹ alakakiti ẹsin Al-Qaeda lọdun naa lọhun.