You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Atiku ní ìbò àwọn ọmọ Nàìjíríà ló máa sọ̀rọ̀ lọ́dún 2027, kìí ṣe ìbuwọ́lù àwọn gómìnà
Igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà tó tún jẹ́ èèkàn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratc Party, PDP, Alhaji Atiku Abubakar tib u ẹnu àtẹ́ lu báwọn gómìnà àtàwọn èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ṣe ń jáde láti sọ pé àwọn fi òǹtẹ̀ jàn-án pé kí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lọ fún sáà kejì.
Atiku ní ìwà náà ṣàfihàn pé ọkàn wọn kò balẹ̀ lórí ìdìbò ọdún 2027 tó ń bọ̀ ni.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbìyànjú láti parapọ̀ pẹ̀lú àwọn míì láti borí ẹgbẹ́ òṣèlú APC níbi ètò ìdíbò ọdún 2027, Atiku fi ìgbàgbọ́ hàn nínú ìgbésẹ̀ náà.
Ó ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni àwọn ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà àti ìṣèjọba Tinubu kò tẹ́ lọ́rùn.
"Àwọn ọmọ Nàìjíríà ló máa ṣe ìdájọ́, ẹni tí wọ́n bá jàn lóǹtẹ̀ ló máa sọ bí èsì ìbò ṣe máa rí, kìí ṣe àwọn olóṣèlú tí wọ́n ń tan ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́"
Olùbádámọ̀ràn Atiku lórí ètò ìròyìn, Mazi Paul Ibe sọ pé gbogbo ìbuwọ́lù táwọn kan ń ṣe fún Tinubu kò lè kó àárẹ̀ ọkàn bá ìgbìyànjú àwọn nítorí àwọn ti ń gbáradì gidi.
Ó ní ọ̀rọ̀ àwọb dàbí akẹ́kọ̀ọ́ tó ń gbáradì fún ìdánwò, ó ní ẹni tó bá ti gbáradì dáadáa ṣáájú ìdánwò le sun oorun àsùnatan nígbà tí ìdánwò bá ku àárọ̀.
Ó ní àwọn ti ń gbáradì kalẹ̀ báyìí kí àwọn le dùn dáadáa nígbà tí ètò ìdìbò bá wọlé.
"Àwọn ọmọ Nàìjíríà ló máa ṣe ìdájọ́. Ẹni tí wọ́n bá jàn lóǹtẹ̀ ló máa sọ bí èsì ìbò ṣe máa rí, kìí ṣe àwọn olóṣèlú tí wọ́n ń tan ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́.
"Àìsí ààbò ti peléke sí báwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ń gba ilẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Borno àtàwọn ibòmíràn. Ìgbé ayé kò rọrùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́, ọ̀pọ̀ ẹbí ló ń tiraka láti jẹun, rí àǹfàní ètò ìlera tàbí ran ọmọ lọ sílé ẹ̀kọ́."
Ó ní pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà yìí, ìjọba kò gbí ìgbésẹ̀ tó láti kojú àwọn ìṣòro yìí dípò bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ òṣèlú ni wọ́n gbájúmọ́.
Bákan náà ló tún fẹ̀sùn kàn ìṣèjọba Tinubu pé ó lo àwọn àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu láti fi dẹ́rùba àwọn alátakò láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Ó wòye pé kìí ṣe gbogbo àwọn tó ń darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló wù wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí ní ìgboyà nínú àwọn ètò wọn.
"Ọ̀pọ̀ wọn ni wọ́n ń fi ìwà àjẹbánu kàn tó sì jẹ́ dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni ọ̀nà àbáyọ fún wọn tó fi mọ́ àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀ rí àtàwọn tó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́.
"Irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Delta láìpẹ́ yìí nìyẹn. Kódà, èyí tó fẹ́ darapọ̀ mọ́ APC láìpẹ́ jẹ́ láti fi san ìwà tí ẹni tó gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ hù ni.
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, akọ̀wé adarí ètò gbogbo ní PDP, Alhaji Umar Bature ní bíbuwọ́lu kò túmọ̀ sí pé wọ́n máa jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò.
Ó ṣe ìràntí pé gómìnà mọ́kànlélógún ló buwọ́lu Goodluck Jonathan lọ́dún 2014 àmọ́ tó fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò gbogbogbò lọ́dún 2015.
Bature ní ojú rèé, ìran rèé lọ́rọ̀ náà àti pé nígbà tó bá tó àkókó iṣẹ́ tí oníkálukú bá ṣe ló máa sọ ipò táwọn èèyàn máa fi sí lásìkò ìbò.
"Ìbuwọ́lù kò jẹ́ nǹkankan, nígbà tí èèyàn bá mọ̀ pé òun kò ṣe ìfẹ́ àwọn èèyàn tó ń ṣojú ni wọ́n máa ń wá ọ̀nà láti máa fi ìbuwọ́lù bojú."