Pelumi Nubi, ọ̀dọ́bìnrin tó ǹ dá wa ọkọ̀ bọ̀ láti London sí Naijiria, ní ìjàmbá mọ́tò

Oríṣun àwòrán, PẸLUMI NUBI/INSTAGRAM
Ọdọmọbinrin, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, Pelumi Nubi, to n da wa ọkọ bọ lati ilu London si Naijiria, ti ni ijamba ọkọ.
Ninu fọnran kan to gbe sori ayelujara Instagram rẹ , Nubi rọ awọn eeyan ati awọn ololufẹ rẹ lati gba adura fun un.
Fọnran naa safihan bi awọn osisẹ pajawiri ṣe sure lọ ba ti wọn si gbe lọ si ile iwosan fun itọju.
Bakan naa fọnran tun ṣe afihan bi o ṣe n gba itọju ni ile iwosan to wa bayii.
Botilẹ jẹ pe a ko tii le sọ pato orilẹ-ede ti ijamba ọkọ naa ti waye, tabi ipo ti ilera ara rẹ wa bayii, ikede ti Arabinrin Nubi fi sita kẹyin ṣaaju iroyin ijamba ọhun, fihan pe o ti de si orilẹ-ede Liberia.
Ninu fidio naa to fi sita ni irọlẹ ọjọ Aje, lo ti sọ pe oun ṣi n wa ọkọ kaakiri orilẹ-ede naa lati mọ si nipa rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Taa ni Pelumi Nubi?
Odu ni Pẹlumi, kii ṣaimọ foloko nibi ka rin irin ajo afẹ ti ko wọpọ, to si ti lọ kaakiri orileede ti ko din ni ọgọrin lagbaye.
Pelumi gbera niluu London to si ti n bọ wa si ipinlẹ Eko, Naijiria, ki isẹlẹ ijamba ọkọ to waye.
Igbesẹ Nubi lo lagbara ju awọn ti atẹyinwa lọ. Eyi to ni o maa gba asiko, bẹẹ lo si maa gba owo to pọ diẹ.
“Mo ti rin irin ajo lo si awọn orileede to yatọ si ara wọn, bi a ba si ni ka wo o, ko din ni orileede mẹtadinlogun ti mo maa gba kọja ko to di pe mo de ilẹ Afrika ti mo n lọ.
“Kii ṣe pe ki n wa ọkọ nikan, mo tun fẹẹ ni iriri nipa awọn orileede ati ilu ti mo ba n de ninu irin ajo yii.
Irinajo naa yẹ ko gbe e gba awọn orilẹede bii France, spain, Morocco, igbo Sahara Dessert, Mauritania, Senegal, Gambia, Guinea-Bissau, Guinea, Sierra Leone, Liberia, Mali, Burkina Faso, Cote d’Iboire, , Ghana, Togo, Benin, ati Naijiria.
Igba wo ni Pelumi ṣe ipinnu yii?
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọdun kan ati oṣu diẹ sẹyin ni Pẹlumi ti n gbaradi lati gbe igbesẹ akikanju yii.
Ọpọ iwadii ni Pẹlumi ti ṣe lori ki irin ajo yii le ni aṣeyọri, bẹẹ lo ti fọrọ wa awọn to ti rin iru irin ajo bayii lẹnu wo, lati mọ iriri wọn.
Nigba to n sọrọ, Pẹlumi sọ pe ọkan kii balẹ nigba toun ba ranti nipa igbesẹ yii, ṣugbọn to maa tun gbe ọkan rẹ kuro wi pe ko sohun ti ko le ṣẹlẹ bi eeyan ba ti ni igboya.
Kini Pelumi fi gbaradi?
Lara awọn igbaradi ti Pẹlumi ṣe ni pe, o lọ ṣe ọkọ rẹ ni eyi ti yoo mu ki irin ajo rẹ rọrun.
Ninu ọkọ naa, aaye idana ounjẹ, aaye ibusun, aaye ifọbọ ati ifọsọ wa nibẹ pẹlu.
“Mo ti n palẹmọ lati bi ọdun kan le diẹ sẹyin, mo ti ba awọn to ti rin iru irin ajo bayii sọrọ lati mọ iriri wọn ati awọn iṣoro ti wọn la kọja. Mo tunm ti ṣe awọn iwadii kun iwadii lori igbesẹ ti mo fẹẹ gbe yii.
“Mo ti lọ ṣe iwadii iye ti yoo na mi lati rin irin ajo yii, ati awọn ọna ti maa gba, to fi mọ bi maa ṣe gba awọn ilu ati orileede kan kọja, bẹẹ ni mo tun ti ṣe iwadii awọn ọna to dara lati rin nitori eto aabo.
“Abẹlẹ ni mo ti n ṣe awọn iwadii wọnyi. Igba miran maa fẹ pariwo ara mi sita, igba miran ọkan mi ko tun ni balẹ lori irin ajo yii.
“Ṣugbọn nigba miran mo maa n rii pe nnkan to ṣee ṣe ni, nnkan to si le ṣẹlẹ ni, ohun ti mo si fẹ ki awọn eeyan mọ gan-an niyẹn wi pe ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ laye yii.
“Eleyii yatọ, bo tilẹ jẹ pe mo ti ṣe awọn kekeeke kan sẹyin, ṣugbọn eyi ti mo dawọ le















