You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọlọ́run ti dá wa láre, a kò bèèrè fún àtúntò Nàíjíríà mọ́, ọmọ wa ti fẹ́ dépò ààrẹ - YCE
Àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yorùbá ti ń fi èrò wọn hàn lórí ìjẹyọ Asiwaju Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bí olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC.
Tinubu gbégbá orékè níbi ètò ìdìbò abẹ́nú APC tó wáyé ní àná ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ní Eagles Square, Abuja pẹ̀lú ìbò 1,271.
Tinubu, igbákejì Ààrẹ Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo, Rotimi Amaechi, Rochas Okorocha, Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello, Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Ahmed Lawan àti àwọn olùdíje mìíràn ni wọ́n jọ wàákò níbi ètò ìdìbò náà.
Nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀, akọ̀wé ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ àwọn àgbààgbà Yorùbá, Dókítà Kunle Olajide ní inú àwọn dùn si wí pé ọmọ Yorùbá ló ń díje dupò Ààrẹ.
Dókítà Olajide ní àwọn ti ṣetán láti kún Tinubu lọ́wọ́ láti di Ààrẹ Nàìjíríà nítorí oore ńlá ló jẹ́ fún ìran Yorùbá.
Ó ní àsìkò ti tó fún ìran Yorùbá láti tún darí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni Ọlọ́run ṣe fi àṣẹ si tí Tinubu fi jawé olúbóri níbi ìdíje náà.
Bákan náà ló àwọn ti gbáradì tí àwọn sì múra láti ṣe àtìlẹyìn fún Tinubu.
“A ti ṣetán, a sì ti gbáradì láti ṣàtìlẹyìn fún ọmọ wa.”
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ènìyàn tí Tinubu ń bá díje nínú ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn bíi Atiku Abubakar ti ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP àti Peter Obi ti Labour Party, Olajide ni ogun ló délẹ̀ báyìí tí àwọn sì ti ṣetán láti jàá.
“Ogun ló délẹ̀ yìí, a ti múra láti kojú ogun, ẹni tó tó kojú ogun náà la dẹ̀ rán, à á dẹ̀ dúró sẹ́yìn rẹ̀ gbọingbọin”
Lórí ìpè fún àtúntò Nàìjíríà, èèkàn àgbà ilẹ̀ Yorùbá náà ní kò sí ohun tó kù mọ́ ju kí àwọn gbárùkù ti ọmọ àwọn.
“Ọlọ́run ti dá wa láre èwo ni ka máa dúró sí ìpinu ìjà mọ́, ọ̀rọ̀ àná nìyẹn, ọ̀rọ̀ àná ní ilẹ̀ Yorùbá èèyàn máa ń fi sẹ́yìn ni.
Tinubu, ewu ń bẹ níwájú, ṣọ́ra ko má jìn sí ọ̀fìn tí Abiola, Awolowo jìn sí - Fayose
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ ri to si tun jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Ayodele Fayose ti kọ lẹta si oludije ipo aarẹ labẹ asia APC Bola Ahmed Tinubu.
Ninu lẹta yi, o gba Asiwaju ni imọran pe ko sọra ṣe ki o ma baa ja si ọfin tawọn olori Yoruba bi Awolowo ati MKO jasi ninu erongba wọn lati de ipo aarẹ.
Iwe yi to fi soju opo ayelujara rẹ n waye bi idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC ti se ku wakat meloo kan ti yoo waye.
Ayodele Fayose sọ pe lootọ loun ati Tinubu ko jijọ si ninu ẹgbẹ oṣelu kanna ṣugbọn ijẹ ọmọ kaarọ o jiire pẹlu agba oṣelu yi lo mu ki oun fi lẹta y sọwọ.
O ni iwe naa ko sẹyin bi Tinubu ti ṣe fi ibinu sọrọ lasiko to ṣabẹwo si ipinlẹ Ogun eleyi to fi han pe Tinubu gaan ri pe ewu nla n bẹ niwaju.
O ni bakan naa loun ri iru esi tawọn alabaṣe Tinubu lagbo oṣelu lati ariwa ati Guusu Naijiira fọ si ọrọ yi.
Fayose ni tori eleyi loun fi n kilọ pe ewu nla n bẹ fun Tinubu ati ẹmi rẹ.
O ni ''mo ri ewu nla to n bọ''
Awolowo ati MKO Abiola naa jin si ọfin yi, sọra ṣe!
Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Ayodele Fayose mu akawe ọrọ wa ninu itan to niṣe pẹlu Obafemi Awolowo ati Moshood Kasimawo Abiola,MKO.
Ninu akọsilẹ gẹgẹ bo ṣe salaye, awọn to n kọrin maa jo lọ mo n wo ẹyin rẹ lo sin awọn mejeeji yi debi iparun.
''Mo mọ pe iru awọn eeyan to sin Abiola ati Awolowo debi iparun yi naa yoo ma sọ fun ẹ pe ki o keti ikun si amọran mi.Mo ri ọ gẹgẹ bi ẹni ti o n ja fitafita pẹlu awọn baba isalẹ inu ẹgbẹ osleu rẹ.Wọn n gbaradi de gbogbo igbesẹ to ba fẹ gbe bi wọn ṣe gbaradi de Awolowo ati MKO''
''O ṣeni laanu pe ibi ti agbara rẹ tagba de, ko ribi tẹlẹ mọ. Iṣẹlẹ to waye ni Ogun jẹ itọka si nkan ti mo n wi yi''
Lakotan ọrọ rẹ, Fayose fi ẹsẹ bibeli pari rẹ to si ni ki Tinubu hu iwa bi ọlọgbọn ti bibeli sọ pe wọn yoo ri wahala to n bọ ti wọn yoo si yago lọna fun ṣugbọn awọn alailọgbọn eeyan yoo wọnu rẹ ni''