You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tí ẹ̀yin gómìnà bá fọwọ́ lẹ́rán, Yorùbá yóò já fún ara wọn - Ooni
Ọọni Ile-Ife, Ọba Enitan Ogunwusi Ọjaja Kejì ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tí àwọn agbébọn kan ṣe sí àwọn ènìyàn ní ilé ìjọsìn Aguda St Francis Church tó wà ní Owa-luwa, Owo, ìpínlẹ̀ Ondo.
Ọba Ogunwusi tó ṣe ìrántí pé lánàá ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹfa, ọdún 2022 ló pé ọdún kan géérégé ní àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ìlú Igangan ní ìpínlẹ̀ Oyo.
Ọọni wòye wí pé gbogbo àwọn ìkọlù yìí sí ilẹ̀ Yorùbá fẹ́ sọ ilẹ́ Yorùbá dí ilé ogún.
Ọba aláyé náà ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àwọn ènìyàn ilẹ̀ Yorùbá fẹ́ràn láti máa gba àláfíà ní àyè ní ibikíbi tí wọ́n bá wà kò túmọ̀ sí wí pé wọn kò ní agbára àti ohun gbogbo tó yẹ láti fi kojú gbogbo àwọn oníṣẹ́ láabi yìí.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ Ọọni Ogunwusi, Otunba Moses Olafare ní kí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run tó ń ṣekúpa àwọn mẹ̀kúnù tó ń fara káṣá ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tí wọ́n ń gbé kojú ilẹ̀ Yorùbá ṣọ́ra gidi tí wọn kò bá fẹ́ ri ìbínú àwọn Yorùbá.
“Mo fẹ́ rán wa léti pé àná tí àwọn iníṣẹ́ láabi yìí ṣe ìkọlù sí ilé ìjọsìn ní Owo ló pé ọdún kan tí àwọn darandaran lọ pa awọn ènìyàn tó lé lógún ní ìlú Igangan, ìjọba ìbílẹ̀ Ibarapa, ìpínlẹ̀ Oyo.”
Ọọni fi kun pé bí àwọn agbébọn ṣe pa àwọn ènìyàn láìsí ìdíwọ́ kankan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ́jú ṣàfihàn rẹ̀ wí pé ètò ààbò Nàìjíríà ti forí sọ́pọ́n pátápátá.
Ó wá pàrọwà sí gbogbo àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá àti Ààrẹ Muhammadu Buhari láti jí gìrì sí ojúṣe wọn nítorí tí wọ́n bá kọ̀ láti ṣe ojúṣe wọn, àwọn ènìyàn kò ní kọ̀ láti dìde gbèjà ara wọn.
Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà tún ti ró àwọn ènìyàn lágbára láti mọ́ wí pé ojú ni alákàn fi ń ṣọ́rí ni ọ̀rọ̀ Nàìjíríà báyìí.
Ọba Ogunwusi wá bá Ọlọwọ tí ìlú Owo, Ọba Ajibade Gbadegesin àti gbogbo ènìyàn ìlú Owo kẹdun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú náà.
Aáyan Akeredolu láti jẹ́ kí ipò ààrẹ wà sílẹ̀ Yorùbá ló fa ìkọlù agbébọn l‘Ondo - Afenifere
Ẹgbẹ́ ajafẹtọ ọmọ ilẹ Yoruba Afẹnifẹre ti ṣapejuwe ikọlu awọn agbebọn si ilẹ ijọsin ni ilu Owo gẹgẹ bi ikọlu ogun awọn agbesunmọmi si ilẹ kaarọ ojiire.
Ninu atẹjade ti alukoro ẹgbẹ naa Jare Ajayi fi sita ni orukọ olori ẹgbẹ naa alagba Ayo Adebanjo Afẹnifẹre ni kawọn ipinlẹ iwọ oorun Guusu Naijiira kede idaro ọlọjọ mẹta ni iranti awọn to ku.
Afẹnifẹre sọ pe ikọlu yi tawọn agbebọn naa se pẹlu nkan ija oloro lo buru julọ ni paapa bi ilẹ Yoruba ko se si ninu ogun pẹlu ẹnikẹni.
O ni ikọlu naa fihan pe awọn to hu iwa yi ti n ‘’gbaradi lọjọ pipẹ ki wọn to ṣe ikọlu naa’’
Atẹjade naa mẹnu ba ọrọ ti olori Afẹnifẹre Ayo Adebanjo sọ ni nkan bi osu meloo kan sẹyin pe awọn agbebọn ti n rọ yika ilẹ Yoruba.
O ni Ayo Adebanjọ fi ikilọ si sita nigba naa lọhun ṣugbọn ijọba Naijiria kọ eti ikun si ikilọ rẹ.
“Pẹlu ikọlu to waye ni Owo yi, o fi han pe awọn kan fẹ tọwọ bọ awọn Yoruba lẹnu ki wọn baa le lọ sogun ni nitori wọn mọ pe awọn agbebọn ti yi ilẹ Yoruba ka''
Adebanjo wa sọ pe gbogbo igbiyanju lati da wahala silẹ Yoruba lawọn yoo tako.
''Wọn ko le bori ilẹ Oodua.Ko ni waye nisinyi''
Adebanjo tun kilọ fawọn to ba ni iru ero yi lọkan lati gbagbe rẹ ki wọn si tọ oju ọna irẹpọ ati ibaraẹni gbe igbe alaafia.
Bakan naa ni Afenifẹre sọ pe o jẹ ohun ibanujẹ pe ajọ isọkan agbaye ti n ko orileede Naijria ati awọn orileede mii ti nkan ko rọgbọ si abẹ isọri kan naa.
Wọn ni ikọlu ati aifọkanbalẹ to n waye ni Naijiria ti buru debi pe ''wọn wa n sapejuwe Naijria,Ukraine ati Venezuela gẹgẹ bi awọn orileede ti ẹmi awọn eeyan wa ninu ewu to pọ''
Afẹnifẹre ni apejuwe yi ko jẹ nkan idunnu ni paapa bi Naijiria ko se si ninu ogun .
Wọn wa rọ aarẹ Buhari lati tete wa wọrọkọ fi ṣada ki Naijria to tuka.
Ikọlu yi ni eleyi to buru julọ ti yoo ṣẹlẹ ni ilẹ Yoruba ninu akọsilẹ.
Ilu Ọwọ jẹ ilu ti Gomina keredolu ti wa bakan naa si ni Owo jẹ ilu ti awọn afurasi darandaran kan ti ṣeku pa arabinrin Olufunke to jẹ ọmọ olori ẹgbẹ Yoruba alagba Reuben Fasoranti lọdun 2019.
Lẹnu lọọlọ yi lawọn ikọlu kan ti n waye ni Ondo lati ọwọ awọn ọdaran agbebọn eleyi to mu ki Gomina Rotimi Akeredolu gbe awọn igbesẹ kan nipa ipese aabo fawọn eeyan ipinlẹ naa.
Bakan naa ni Rotimi Akeredolu lewaju nipa jija fawọn ẹtọ kan ti o ni wọn fi n dun ilẹ Yoruba ninu akoso Naijiria.