Bayowa fèsì padà fún Busola Oke Eleyele

Gbajugbaja oṣere tiata, Gbenga Adewusi ti ọpọ mọ si Bayowa ti fesi si ẹsun gbajugbaja olori ẹmi, Busola Oke ti ọpọ mọ si Ẹlẹyẹle fi kan, to si ni ọrọ ko ro ibẹ.

Bayowa, ninu atẹjade to fi lade loju opo ayelujara rẹ salaye pe oun gbe Busayo Oke kuro ilẹlẹ si ibi to de lonii.

“Ọdun mọkanla si mẹwaa bayii ni Busayo Oke ti kuro labẹ ileeṣe mi lẹyin ti mo ra ọkọ bọgini mii fun un.

“N ko le kiri ko pada si ileeṣẹ mi. O gbe awo orin mẹta jade fun ontaja orin mii, ti oun gan gan si tun gbe orin jade fun ara rẹ lẹyin to kuro ni Bayowa Films”

Owo ti n awọn eeyan da fun Mohbad lo wọ Busola loju to fi n ba orukọ mi jẹ

Adewusi ni oun ko le sọ idi ti Busola fi pariwo oun to si n sunkun lẹyin ọsun mẹwaa ti oun ti foju kan sẹyin.

“O n lo pari igbesi aye ara rẹ, o wa fẹ lo bi akoko iku Mohbad yii lati fi wa oju rere awọn eeyan lati le da owo fun lati si tun le ba orukọ mi jẹ.

“N ko ti ṣetan lati sọ ọrọ tabi gbe fọnran jade lati fi da lohun lori irọ to pa mọ mi.

“Ti mo ba sọrọ lori nnkan ti Busola Oke ṣe ni Canada Tour lọdun 2019, bi o ṣe fẹ gbajugbaja agbeorin larugẹ niluu London, to si tun bimọ fun, eyi to fa ọpọlọpọ wahala pẹlu iyawo ile ẹni ọhun, ti fihan pe oun gan lo fa gbogbo ajalu to de ba.”

Bayowa wa rọ Busola Oke lati lọ ṣe atunṣe awọn igbesẹ to ti gbe sẹyin lati le pada si ni ṣe daada fun ara rẹ.

Àwọn ohun tí ojú mi rí lábẹ́ Bayowa kò kéré, mo ta ilé, ta dúkìá - Busola Oke Eleyele

Gbajúmọ̀ olórin ẹ̀mí, Busola Oke tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Eleyele ti sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí alágbàtà fíìmù àti orin nígbà kan, Gbenga Adewusi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bayowa Fillms and Record International.

Busola Oke nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn tó máa ń gbé àwọn olórin lárugẹ ṣe máa ń lò wọ́n láti fi pa owó sí àpò ara wọn láì fún àwọn olórin náà ní àǹfàní láti jẹ èrè iṣẹ́ wọn.

Nínú fídíò kan tí Busola Oke tó ṣe lórí TikTok rẹ̀ ní ojú òun rí tó lọ́wọ́ Bayowa nítorí òun kò rí àǹfàní kankan jẹ lórí àwọn orin tí òun ṣe lábẹ́ ilé iṣẹ́ rẹ̀.

Ó ní òun ta ilé àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá òun nítorí òun kò ì tíì bọ́ lọ́wọ́ àkóbá tí Bayowa ṣe fún òun nígbà tí òun wà lábẹ́ rẹ̀.

Ó gba àwọn olórin tó bá ń dìde lásìkò yìí láti la ojú wọn sílẹ̀ dáradára kí wọ́n má ba à kósí ọwọ́ àwọn tí wọ́n máa ba ògo wọn jẹ́.

Ó kọminú pé òun kò rí ẹnìkankan ta òun lólobó nígbà tí òun fẹ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Bayowa pé oore ẹ̀dẹ ni òun fẹ́ gbà pé òun kò bá má ti torí bọ̀ ọ́ tàbí kó sí abẹ́ rẹ̀.

Busola Oke ṣàlàyé pé lẹ́yìn tí àwọn ṣe orin ìkẹyìn fún olóògbé Gbenga Adeboye ni Bayowa pe òun pé kí òun wá ṣe orin fún iléeṣẹ́ òun.

Ó tẹ̀síwájú pé ìgbà náà ni òun ṣàlàyé fún pé òun ní orin kan tí òun ṣe lọ́wọ́ tó sì ní kí òun wá àwọn orin mìíràn mọ́ tí òun sì ṣe bẹ́ẹ̀.

“Tí wọ́n bá sọ wí pé àwọn nǹkan báyìí ni mo ti kójọ nílé ayé mi níbi tí àwọn àwo orin tí mo ṣe fún Bayowa tà dé, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

“Nǹkan tí àwọn promoter máa ;ń ṣe ni pé wọ́n máa ń sọ ènìyàn di ẹrú títí ayérayé, tí ènìyàn yóò máa sìn wọ́n títí tó máa fi kú.”

“Nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárín èmi àti Bayowa nìyí, ó fẹ́ sọ mí di ẹrú ayérayé ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ wà lọ́wọ́ Ọlọ́run.”

Bákan náà ló kọminú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni ó yẹ kí òun ti gbéṣe ṣùgbọ́n tí òun kò lè ṣe tí àwọn kan sì ń fi òógùn òun jẹ ayé.

Ó ní òun gbà pé Ọlọ́run nìkan ló máa dájọ́ láàárín òun àti Bayowa fún gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn.

Òkú Mohbad kò gbọdọ̀ sùn títí ìdájọ́ òdodo máa fi wáyé lórí ikú rẹ̀

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ikú Mohbad, Busola Oke ní òkú Mohbad kò gbọdọ̀ sùn títí tí yóò fi gbẹ̀san lára àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú rẹ̀.

Ó ní òkú rẹ̀ gbọ́dọ̀ ri dájú pé gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò rẹ̀ sí bó ṣe tètè dágbére fáyé ni ó gbọdọ̀ jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

“Lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti ṣẹ́gun, tí o ti gbẹ̀san lára àwọn oníṣẹ́ ibi tán, tí o ti ṣẹ́gun, o lè wá lọ sínmi ní àyà Olùgbàlà.”