Ìjọba kéde kónílé gbélé ni Kano lẹ́yìn ìdájọ́ Tribunal

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Kano ti kéde òfin kónílé gbé lé fún ọjọ́ kan lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ náà gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kano, Mohammed Usaini Gumel rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà láti tẹ̀lé òfin yìí nítorí pé àwọn ti da àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mìíràn sí ìgboro láti ṣe àmójútó òfin náà.

Gumel ní ìgbésẹ̀ ṣíṣe òfin kónílé gbélé yìí ń wáyé láti tẹ̀lé àṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Ó ṣàlàyé pé ní aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ni òfin kónílé gbélé náà yóò wá sópin àti pé àwọn tó bá lòdì sí òfin náà yóò fojú winá òfin.

Kọmíṣọ́nà náà ṣàlàyé pé ojúṣe ọlọ́pàá ni láti ri dájú pé ààbò tó péye wà nílùú.

Iléẹjọ́ ti yọ gómìnà Kano Abba Kabir Yusuf nípò, wọ́n ní Nasir Gawuna APC ló wọlé

Ile ẹjọ to n ri si awuyewuye lori eto idibo ti yọ gomina ipinlẹ Kano, Abba Kabir Yusuf nipo.

Ileẹjọ naa ni Nasir Gawuna to jẹ oludije ẹgbẹ osẹlu APC lo wọle ibo gomina ipinlẹ naa.

Ajọ eleto idibo INEC kede Yusuf to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu NNPP gẹgẹ ni oludije to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Kano loṣu Kẹta pẹlu ibo 1,019,602 nigba ti ajọ naa ni ibo 890,705 ni Gawuna ni ninu ibo ọhun.

Bakan naa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun tun gba iwe ẹri moyege ti ajọ INEC fun gomina Yusuf lẹyin to kede rẹ gẹgẹ bi oludije to wọle ibo gomina ipinlẹ Kano.

Lẹyin naa ti igbimọ olugbẹjọ ẹlẹni mẹta paṣẹ pe ki Gawuna gba ẹri moyege naa.

Ilẹ ẹjọ naa yọ ibo 165,663 kuro ninu gbogbo ibo ti Yusuf pẹlu alaye wi pe ko si ontẹ tabi ibuwọlu lori awọn ibo naa.

Gbogbo ẹsun mẹtẹẹta ti APC fi kan NNPP lori eto idibo ọjọ kọkanla oṣu Kẹta ni igbimọ igbẹjọ naa da APC lare lori wọn.

Yatọ si awọn ẹgbẹẹgbẹrun ibo ti wọn ko buwọlu, ẹgbẹ APC tun sọ fun ileẹjọ pe Yusuf ko koju oṣuwọn to gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ naa lati dupo gomina, bakan naa ni APC ti sọ pe bi INEC ṣe kede Yusuf tako ilana ofin eto idibo.

Ṣáájú kí ìdájọ́ tó wáyé ni ẹgbẹ́ òṣèlú tó wà nípò ìyẹn NNPP àti ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, All Progressives Congress (APC) ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àdúrà láti lè jẹ́ kí ìdájọ́ náà rí bí wọ́n ṣe ń fẹ́.

Adájọ́ Flora Azinge tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Adájọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà fẹ̀sùn kàn pé àwọn kan ń fi mílíọ̀nù náírà lọ òun gẹ́gẹ́ bí owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti da ẹjọ́ rú.

Adájọ́ Osadebay ti ṣáájú jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn máa ṣe òtítọ́ àti òdodo lórí ìdájọ́ tí àwọn máa dá ní ìbámu pẹ̀lú òfin.

Ìdájọ́ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC, Gawuna ní òun gba àbájáde èsì ìbò tí INEC gbé jáde lọ́jọ́ kìíní oṣù Kẹta ọdún 2023 pé Abba Kabir Yusuf ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò gómìnà náà.

Guwana ní gẹ́gẹ́ bí Mùsùlùmí òdodo, òun gbọ́dọ̀ gba àbájáde èsì ìbò náà bó ṣe wá.

Ó ní òun kò ní pe ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ń sọ fun pé kó lọ sí ilé ẹjọ́.

A máa pe ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn

Ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria Peoples Party (NNPP) ti ní àwọn kò gba ìdájọ́ tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò dá pé Abba Kabir Yusuf kọ́ ló wọlé ìbò gómìnà Kano.

Ladipo Johnson tó jẹ́ agbenusọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà sọ fún BBC pé ìdájọ́ náà kò sí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó wà nílẹ̀.

Ó ní ohun tó fojú hàn ni pé àwọn máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn níwájú ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn.

"A ò gba ìdájọ́ náà rárá, ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ló máa báwa parí rẹ̀.