You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé aṣòfin Ondo pàṣẹ̀ fún adájọ́ àgbà láti gbé ìgbìmọ̀ kalẹ̀ tí yóò yọ igbákejì Gómìnà nípò
Ile aṣofin ipinlẹ Ondo ti kọ iwe ipe tuntun ranṣẹ si adajọ agba ipinlẹ naa, adajọ Olusegun Odusola, pe ko ṣe agbende igbimọ ti yoo tọpinpin ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan igbakeji Gomina, Ọgbẹni Lucky Aiyedatiwa.
Iwe naa ti olori ile, Olamide Oladiji buwọlu, salaye pe ile tẹsiwaju lati gbe igbesẹ yiyọ igbakeji Gomina naa lẹyin ti gbendeke aṣẹ ti ile ẹjọ giga gbe kalẹ wa si opin.
Iwe naa sọ pe ''Lọjọ kẹta oṣu kẹwaa ni ile beere pe ki oluwa mi o ṣe agbenede igbimọ ẹlẹni meje, ti yoo ṣe agbeyẹwo ẹsun aṣemaṣe ti ile fi kan Lucky Aiyedatiwa, ni ibamu pẹlu iwe ofin Naijiria.''
O fi kun pe, adajọ agba ipinlẹ naa lo ti fi aake kọri tẹlẹ pe oun ko ni gbe igbesẹ kankan lori agbekalẹ igbimọ oluwadii naa, bi wọn ko ba yanju aṣẹ ti ile ẹjọ giga ti pa ṣaaju nipa igbesẹ naa.
Amọ o ni nibayii ti gbendeke lori aṣẹ ti ile ẹjọ giga gbe kalẹ ti wa kọja, ile aṣofin ni asiko ti to, bẹẹ si ni aaye wa ki adajọ agba ṣe agbekalẹ igbimọ iwadii yi.
Igbesẹ ti ile aṣofin fẹ gunle bayii n waye lẹyin bi ọsẹ kan ti ile kede pe awọn ti kawọ rọ lori iyọni nipo igbakeji Gomina lẹyin ti awọn olori ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress APC da si ọrọ naa.
O dabi pe gbogbo igbiyanju igbimọ apẹtusaawọ ti ẹgbẹ APC gbe kalẹ lori aawọ nipinlẹ Ondo ti ja si pabo
Olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo ti ṣaaju ṣe ipade kan pẹlu alaga ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn eekan ẹgbẹ mi to si kede nibẹ pe awọn ti dawọ igbesẹ iyọni nipo Aiyedatiwa duro.
Lẹyin igba naa ni ile kesi igbakeji Gomina lati yọwọ ninu ẹjọ gbogbo to pe ile aṣofin ati Gomina Rotimi Akeredolu.
Ibi ọrọ wa gba yọ bayii dabi ẹni pe gbogbo igbiyanju igbimọ ipẹtusaawọ ti ẹgbẹ APC gbe kalẹ ti ja si pabo.
Gomina ipinlẹ Katsina tẹlẹ ri Aminu Bello Masari ni o lewaju igbimọ yi.
Ẹwẹ agbẹjọro igbakeji Gomina, Ebun-Olu Adegboruwa (SAN), ninu atẹjade kan ti sọ pe, ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo ti gba ile asofin ati Aiyedatiwa nimọran lati lọ yanju ọrọ naa ni tubi n nubi.