You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lẹ́yìn ìdúnkookò Makinde sáwọn òṣìṣẹ́ ṣóńṣó méjì pàdé, irin kan tẹ̀ fún ọ̀kan
Se ni ọgba ileesẹ ijọba ipinlẹ Oyo to wa ni Secretariat gbalejo awọn osisẹ lẹẹkan si nitẹsiwaju awọn iyansẹlodi ati iwọde wọn to n lọ lọwọ.
Igbesẹ naa si ni awọn osisẹ yii se lati gbena woju ẹkun gomina Seyi MAkinde to fohun lile ba wọn sọrọ lọjọ Satide to kọja.
Bẹẹ ba gbagbe, gomina Seyi Makinde lo bawọn araalu sọrọ lopin ọsẹ lori iyansẹlodi tawọn osisẹ gunle ati iwọde ti wọn n se ni gbagede ọgba Secretariat nilu Ibadan.
Ninu ọrọ rẹ si ni gomina Makinde ti fọhun akin, to si ke sawọn agbofinro lati kọju oro sawọn osisẹ to n di awọn osisẹ yoku to fẹ sisẹ lọwọ lati wọle sọgba osisẹ naa.
Amọ se ni awọn asaaju osisẹ yinmu si awọn ọrọ gomina naa, ti wọn si fi ipade sọjọ aje pe awọn yoo pade niwaju ọgba Secretariat lodi si asẹ ti gomina pa.
Wọn wa leri leka pe lọjọ Aje naa ni awọn araalu yoo mọ boya ikun lo ni oko ni tabi pakute.
Makinde kẹyin si ihalẹ rẹ lati lo iwa ipa, o bẹ awọn osisẹ lati fopin si iyansẹlodi
Amọ se lo n ya ọpọ eeyan lẹnu pe ọwọ tutu ni gomina Makinde fi pada mu ọrọ awọn osisẹ naa loni ọjọ Aje nigba ti ọn pada peju siwaju ọgbọ Secretariat naa.
Ọrọ Yoruba si ni Makinde tẹle lori isẹlẹ naa eyi to ni "ti a ba fi ọwọ ọ̀tun ba ọmọ wi, se la maa n fi ti osi fa a mọra."
Dipo ki ijọba kọju oro sawọn osisẹ naa, se ni gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde jade sita lati se ipade pẹlu awọn osisẹ to n se iwọde naa.
Makinde wa n rawọ ẹbẹ si awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa lati fi opin si iyanṣẹlodi ti wọn gunle lati bii ọsẹ kan sẹyin.
Ninu ọrọ ti o ba wọn sọ lọjọ Aje ni gbagede ọfisi Gomina to n bẹ ni agbegbe Agodi n'ilu Ibadan, Makinde ni odidi ọsẹ kan ti wọn fi yan isẹ lodi ti ṣe akoba fun eto ọrọ aje ipinlẹ Ọyọ.
Gbogbo ohun tawọn osisẹ n beere fun ni maa se fun wọn - Makinde
O fikun pe se lo yẹ ki wọn da ero wọn lori iyansẹlodi naa yẹwo nitori owo naa ni ijọba yoo fi gbọ bukata awọn nnkan ti wọn n beere fun.
O fi kun ọrọ rẹ wi pe gbogbo ipa ni oun yoo sa lati di ogiri to lanu laarin ijọba ati awọn oṣiṣẹ.
Lẹyin ọrọ ti Makinde ba awọn oṣiṣẹ sọ, ni o wọ iyẹwu lọ fun ijiroro pẹlu awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ.
Makinde ni laarin ọṣẹ kan ti wọn gunle iyanṣelodi naa ni igbeṣẹ ọhun ti fa ifaṣẹyin fun ọrọ aje ipinlẹ Ọyo.
‘’Gomina Makinde ni oun yoo da ayọkuro owo osu wọn pada.
Bakan naa ni gomina ni lati opin osu yii ni awọn oṣiṣẹ fẹyinti yoo bẹrẹ si ni gba owo ajẹmọnu wọn, iyen gratuities.
Gomina naa fikun un pe ni ohun gbogbo ti awọn oṣiṣẹ fẹ ni ohun yoo ṣe fun wọn, ti awọn yoo si jiroro lori rẹ lasiko ipade wọn.
Gomina ti ni oun yoo mu ileri ṣẹ fun awọn oṣiṣẹ - Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Nigba ti wọn n ba ikọ iroyin BBC Yoruba sọrọ, alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ labẹ aburada NLC n'ipinlẹ Ọyọ, Kayode Martins ṣe alaye pe eti awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ko ni di si abajade ipade pẹlu Gomina.
Lara nnkan ti awọn oṣiṣẹ naa n pe fun ni idapada ayọkuro owo oṣu, ipese ohun amayedẹrun, atungbeyẹwo owo oṣiṣẹfẹyinti ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ti le ni ọṣẹ kan bayii ti awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ Ọyọ ti gunle iyanṣelodi lori ẹsun pe ijọba kọ lati san awọn owo ajẹmọnu wọn.
Bakan naa lo ṣeleri fun wọn pe oun ti wọn n fẹ yoo tẹ wọn lọwọ, to si ra ọwọ ẹbẹ si wọn lati pada si ẹnu iṣẹ.