You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún pokùnso nítorí pé kò páàsì ìdánwò nílùú Offa
Ọmọdekurin ẹni ọdun mẹtadinlogu, ti orúkọ rẹ jẹ Adegoke Adeyẹmi ti o jẹ ọmọ ileewe girama Ọffa ni o gbẹmì ara rẹ lẹyin ti o fidi rẹmi ninu idanwo.
Adegoke ni iroyin ọkan rẹ ba jẹ lẹyin ti ko ni anfani lati tẹsiwaju kuro ninu kilaasi to wa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, ẹni to fìdí iṣẹlẹ naa mule, sọ fun BBC News Yoruba pe lọjọbọ ana ni awọn gba gba ipe pajawiri pe wọn ri oku ọdọkunrin kan to n rọ dẹdẹ lagbegbe Ileetura Ariya Garden, niluu Ọffa.
Ajayi ni kía ni awọn ọlọpaa de sibi iṣẹlẹ naa ni wọn ri oku Adegoke Adeyẹmi ni bi ti o ti pokunso.
"Adegoke ni ó ṣe idanwo SS1, lati bọ si SS2, ṣugbọn o fidi rẹmi, wọn si ni yoo tun SS1 ka, eyi lo ṣokunfa to fi lọ pokunso, to si seku pa ara rẹ lojiji."
Ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ti gbe oku ọmọ naa lọ si ileewosan Jẹnẹra tilu Ọffa, fun ayẹwo ti awọn si ti bẹrẹ iwadiilori iṣẹlẹ naa.