Bọ́ọ̀sì akérò sọ ìjánu rẹ̀ nù, ó yà pa obìnrin tó fẹ́ wọkọ̀ níbùdókọ̀

Oríṣun àwòrán, LASTMA
Èrò kan to n duro de mọto ti yoo wọ nikorita Demurin, Ketu nipinlẹ Eko, padanu ẹmi rẹ ni nnkan bii aago meje aarọ ku iṣẹju mẹẹẹdogun.
Alaye ti Adari ẹka ilanilọyẹ nileeṣẹ LASTMA to n ri si igbokegbodo ọkọ l’Ekoo, Adebayọ Taofiq, ṣe ni pe bọọsi akero kan lo padanu ijanu rẹ nibi to ti n sare asapajude.
Adebayọ sọ pe yatọ si ẹni ti mọto pa nibi to duro si naa ,obinrin kan naa tun ni ijamba ninu mọto mi-in ti bọọsi akẹro naa kọlu.
‘NSW 216 XA’ ni nọmba ọkọ akẹro to padanu ijanu rẹ yii. Ata atawọn nnkan ọbẹ mi-in lo si di sinuu mọto naa bamubamu.
Eré àsájù ló jẹ́ kí mọ́tò ọ̀hún pàdánù ìjánu rẹ̀- LASTMA
Nigba to n ṣalaye idi ti ijamba to paayan laaarọ kutu naa ṣe waye, aṣoju LASTMA sọ pe ere asaju lo fa a.
’’Yatọ si ẹni to pa, o tun kọlu ọkọ akero mi-in to duro jẹjẹ rẹ.
Obinrin kan to wa ninu mọto to kọlu ko le da jade ninu ọkọ naa.
Awọn oṣiṣẹ LASTMA lo gbe e jade ti wọn si sare gbe e lọ sileewosan.’’
Wọn ti mu awakọ to paayan naa lẹsẹkẹsẹ gẹgẹ bo ṣe wi.
Ọga agba fun LASTMA, Ọlalekan Bakare-Oki, rọ awọn ero to ba fẹẹ wọ mọto lati maa duro nibudokọ tijọba pese.
Bakan naa lo rọ awọn onimọto pe ki wọn yee sare asapajude.
Ki wọn si ri i pe ijanu ọkọ wọn atawọn ẹya ọkọ yooku wa laaye ire.













