A ti mọ iléeṣẹ́ tó ni àdó olóró tó bú gbàmù nílùú Ibadan – Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọ pe ijọba oun ti mọ orukọ ileeṣẹ to ni ado oloro to bu gbamu niluu Ibadan lalẹ ọjọ Iṣẹgun.

Bo tilẹ jẹ pe Makinde ko darukọ ileeṣẹ naa, o ni iṣẹ ti n lọwọ lati tuṣu de isale ikoko iṣẹlẹ ọhun.

Makinde lo sọ ọrọ naa lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lori ibugbamu naa niluu Ibadan.

O fi kun pe apapọ awọn eeyan to jade laye nibi iṣẹlẹ ọhun ti pe mẹta bayii.

Ṣaaju ni eeyan meji ti kọkọ ku lẹyin ibutgbamu naa ki ẹnikan to tun jade laye.

Yatọ si awọn to ku, nnkan bi ọkọ marun un to bajẹ nibẹ to fi mọ ọpọlọpọ ile.

Awọn to farapa nibi iṣẹlẹ naa jẹ mẹtadinlọrin.

Makinde ti paṣẹ fun ile iwosan UCH ko maa ṣetọju awọn to farapa lọfẹẹ, ti ijọba ipinlẹ naa yoo si san owo itọju wọn.

O tun rọ awọn eeyan agbegbe naa lati dẹkun ati maa lọ sinu ile wọn lasiko yii nitori ijọba ti pese ile ti wọn yoo maa gbe fun akoko igba diẹ.

Àtọwọ́dá àdó olóró IED ló fa ìbúgbàmù tó wáyé ní ìlú Ibadan - NEMA

Ado oloro atọwọda IED lo ṣokunfa ibugbamu to waye ni ilu Ibadan lọjọ Iṣẹgun.

Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA lo sọ eyi di mimọ.

Ninu atẹjade to fi sita loju opo X rẹ, ajọ NEMA ṣalaye pe ibugbamu ado oloro atọwọda IED naa ba nnkan bii ogun ile lagbegbe naa jẹ.

O ni ni kete ti ajọ naa gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun lo ti ko awọn oṣiṣẹ rẹ ranṣẹ si agbegbe naa lati bẹrẹ igbesẹ ati doola awọn ẹmi nibẹ.

“Nigba ti a de ibi ti ibugbamu naa ti waye, a rii pe awọn ado oloro atọwọda IED eyi to kan ile bii ogun. A ko lee fi idi iye awọn to baa lọ ni pato mulẹ. Eto idoola ẹmi ṣi n tẹ siwaju.”

O ni lara awọn ileeṣẹ ati ajọ ijọba to kọkọ debẹ lati mojuto abo ati idoola ẹmi ni ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ ọmọogun, ileeṣẹ panapana, ajọ NSCDC, ajọ SEMA, Red Cross, ileeṣẹ ọrọ ayika nipinlẹ Ọyọ, ati Amọtẹkun.

Ki ni Àtọwọ́dá àdó olóró IED?

Atọwọda ado oloro IED jẹ agbelẹrọ̀ ado oloro tabi ohun abugbamu to le ba ọpọlọpọ nnkan jẹ, tabi sọ oke di ilẹ ni iṣẹ ju aaya.

Lara awọn to maa n lo atọwọda ado oloro yii ni awọn ọdaran, awọn ọbayejẹ, agbebọn, eṣinṣin-o-kọku atawọn awakusa nigba miran.

Lara awọn eroja ti wọn maa fi n ṣe e ni ajilẹ, ẹtu ibọn ati eroja Hydrogen peroxide.

Awọn akọṣẹmọṣẹ fi idi rẹ mulẹ pe bi akojọpọ ado oloro atọwọda yii ba ṣe pọ to ni ọwọja rẹ ṣe maa n rinlẹ si.

Bakan naa ni wọn ni bi ibi ti o ba wa ba ṣe ri naa tun kun ara ohun to maa n sọ bi ọṣẹ rẹ yoo ṣe lagbara to.