You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èèyàn mẹ́tàlá ni wọ́n kọ́kọ́ gbé wá sí UCH, wọ́n tún gbé òkú ẹnìkan wá - Ọ̀gá àgbà UCH
Ọga agba ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun ti fasiti ilu Ibadan tawọn eeyan mọ si UCH, Ọjọgbọn Jesse Abiodun Otegbayo ti ṣalaye pe eeyan mẹtala ni wọn gbe wa sile iwosan naa lati ibi ti ibugbamu ti ṣẹlẹ lagbegbe Bodija niluu Ibadan.
Ọjọgbọn Otegbayo tun sọ pe wọn gbe ẹnikan wa to ti ku, o ni ẹni naa si wa ni ile igbokusi.
Adari ile iwosan UCH ni wọn tun ti gbe awọn eeyan mii wa loni Ọjọru.
''Wọn tun ti gbe awọn mii wa lonii Ọjọru, o si ti di eeyan mẹtala to n gba itọju ni wọọdu pajawiri nigba ti ẹnikan wa ni wọọdu ICU nibi ti wọn ti maa n tọju awọn aisan to lagbara.
Ile bii mẹẹdogun ni ibugbamu naa ṣe ipalara fun ninu ọgba ile iwosan UCH.
Ibugbamu ọhun ṣakoba fun awọn laabu wa kan, bakan naa lo tun ni ipa lori ile ẹkọ nọọsi wa naa.
Koda, omiran fẹẹ sa jade ni ihoho ninu awọn akẹkọọ wa nigba ti ibugbamu naa ṣẹlẹ lalẹ ana.
Awọn gilaasi ferese fọ, awọn ilẹkun fi agbara ṣi kalẹ. ọpọ aja awọn ile mii ninu ọgba UCH lo ja.
Awọn ibikan ti ẹ wa ti orule ile fọ ti a si n ri oju ọrun lati inu ile.
Awọn waya kan naa ja, amọ ko si ile kankan to dawo ni UCH,'' Ọjọgọn Otegbayo lo sọ bẹẹ.
Ọga agba ile iwosan UCH fikun ọrọ rẹ pe Gomina Seyi Makinde sọ pe ki ile iwosan naa ṣe itọju gbogbo awọn ti wọn ba gbe e wa fun itọju lati ibi ibugbamu naa.
O tun fidi rẹ mulẹ pe awọn ko gbowo lọwọ ẹnikẹni tawọn fun ni itọju to fi mọ awọn to gba ẹjẹ gan an, atawọn to ṣiṣẹ abẹ diẹ atawọn ti wọn to egungun wọn.
''Ilé wó lu ìyá mi mọ́lẹ̀ níbi tí ìbúgbàmù ti wáyé ní Ibadan,'' àwọn olùgbé Bodija sọ ìrírí wọn
Yoruba bọ, wọn ni gbọngbọn nii kan ọlọrọ, awọn olugbe agbegbe Bodija nibi ti ibugbamu ti ṣẹlẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ gan an.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba lowurọ Ọjọru, wọn sọ ibi ti wọn wa nigba ti iṣẹlẹ ọhun waye ati ipa to ni lori wọn ati lori ile wọn.
Arabinrin kan ni lati agbegbe Ologun-eru loun ti gbọ ariwo nla ti ilẹ si mi titi.
'Mama mi ṣeṣe ninu ibugbamu naa'
Obinrin naa sọ wi pe lojiji lawọn ọmọ oun sare wọle, niṣe ni ina ibugbamu kọ mọna loju ọrun.
O ni nigba to ya ni oun ati ẹbi oun gbọ pe agbegbe Bodija ni iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.
Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Emmanuel sọ fun BBC Yoruba pe ''ni alẹ ana ni a gbọ ti nkan naa ṣe dun bii bọmbu.
Bayii ni gbogbo eeyan bẹrẹ si ni kọminu pe iru iro wo ni eyi ati pe ki lo n ṣẹlẹ gan an.
Bi o ṣe dun yii mu ẹru ba gbogbo eeyan, ilẹ mi titi.
Ohun ti a gbọ ni pe ẹnikan lo kan nkan bi ado oloro pamọ sinu ile eyi to bu gbamu.
O ṣakoba fun ọpọ ile ati ọkọ, koda ọpọ ẹmi lo sọnu nibi iṣẹlẹ ọhun.
Amọ, a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko ju bayii lọ.''
Ẹlomiran tun sọ pe iya oun ṣeṣe ninu iṣẹlẹ naa tori ile to wa lẹgbẹ ibi ti ibugbamu yii ti waye ni mama oun n gbe.
O ṣalaye pe iya oun ti n gba itọju nile iwosan bayii.
Oriṣiriṣi iroyin lawọn eeyan n gbe kiri lori iṣẹlẹ naa - Ọjọgbọn Ayantayọ
Ọjọgbọn Kehinde Ayantayo ni tilẹ sọ pe oun n kawe lọwọ ninu yara ikawe oun nigba ti ibugbamu ṣẹlẹ.
Gbogbo yara ikawe mi lo mi titi nigba ti ibugbamu ọhun ṣẹlẹ.
Ọjọgbọn Ayantayo ni oriṣiriṣii iroyin lawọn eeyan n gbe kiri lori ibugbamu to sẹlẹ.
O ni bawọn kan ṣe n sọ pe banga ni lawọn mii ni baalu lo ja.
Awọ kan tiẹ tun ro pe bo ya awọn sọjọ lo n ṣe ayẹwo bọnbu wọn.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo sọ loju opo X rẹ pe awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ṣi n ba iṣẹ lọ nibi ti ibufgbamu ọhun ti ṣẹlẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ko sẹni to le raye wọ ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye mọ bayii ki awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi le raye ṣiṣẹ wọn.
Ileeṣẹ ni iwadii yoo ya kiakia lori iṣẹlẹ naa, yoo si jẹ ẹkunrẹrẹ.