You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àmọ̀tẹ́kùn mú afurasi ajínigbé 19 l'Ondo
Awọn ọmọ ikọ amọtẹkun nipinlẹ Ondo lo ti fi panpẹ ọba mu awọn afurasi mẹrindinlogoji nipinlẹ naa.
Mọkandinlogun ninu awọn ti wọn mu naa ni wọn furasi pe ajinigbe ni wọn ti awọn ikọ naa si mu wọn nitosi oriko ti wọn ti maa n jinigbe julọ lagbegbe ijọba ibilẹ Owo.
Awọn mọkandinlogun naa ni wọn mu pẹlu oriṣiriṣi ohun ija oloro bi ibọn, ida, ada, ọbẹ atawọn eroja ogun ibilẹ bii ounde, ifunpa ati oruka lonirannran.
Adari ikọ amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Akogun Adetunji Adeleye, lakoko to n fi oju awọn afurasi naa lede wi pe awọn n gbiyanju lati pinwọ ijinigbe nipinlẹ naa.
Adeleye wi pe “igbiyanju awọn ajinigbe ni a tuka lẹẹmẹrin ọtọọtọ laarin oṣu kan sẹyin leyi to faa ti ko fi si ijinigbe kankan nipinlẹ yii lati igba naa.
“Eyi lo waye latari ifimufinlẹ to lagbara ati bi ikọ yii ṣe ji giri lati ṣiṣẹ lori olobo ti wọn ta wa.
“Akoko yii ni ọwọ wa tẹ awọn afurasi ajinigbe mọkandinlogun ti ẹ n wo yii nitosi oriko kan ti ijinigbe ti maa n waye pupọ lapa ariwa ipinlẹ yii.”
Adari ikọ amọtẹkun naa to tun jẹ olubadamọran pataki fun gomina lori eto abo waa rọ awọn araalu lati maa fi ohun ti oju wọn ba ri to awọn agbofinro leti.
O wi pe “a rọ awọn araalu, paapaa julọ, awọn Olu ati baalẹ lawọn ileto wa, ki wọn maa fi to ajọ amọtẹkun abi awọn ẹṣọ alaabo to ku leti ti wọn ba ri awọn alejo to ko ara wọn wọlu lojiji.
“Lati rii pe awọn ọdaran yii ko gba igboro mọ wa lọwọ latari bi a ṣe n doju ija kọ wọn lẹyin odi ilu ati ninu igbo ọba ti wọn maa n sa pamọ si, a ti ṣe agbekalẹ oriko awọn ọmọ ikọ yii sawọn aaye to lapẹrẹ kaakiri ipinlẹ yii.
“A si n reti ki awọn araalu o fi ọwọ sowọpọ pẹlu wọn lati lee fọ ipinlẹ yii mọ lọwọ awọn ọdaran.”
Adeleye fi kun pe awọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn alaṣẹ lati lee fopin si irinkerindo awọn to n ṣalẹ laarin ilu nitori pe ọpọ wọn lo fi eyii boju lati hu iwa ọdaran.