Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ níbi ètò orin kíkọ, èèyàn mẹ́sàn-án jáde láyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Mínísítà fétò ìlera ní orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo ti ní kò dín ní èèyàn mẹ́sàn-án tí wọ́n ti pàdánù ẹ̀mí wọn, tí ọ̀pọ̀ àwọn míì sì farapa ní ètò orin kíkọ kan tó wáyé ní orílẹ̀ èdè náà.

Akọrin ẹ̀mí àti pásítọ̀ Mike Kalambay ló ṣe àgbékalẹ̀ ètò orin náà ní pápá ìṣeré Martyrs tó wà ní Kinshasa, olú ìlú orílẹ̀ èdè DR Congo.

Pápá ìṣeré náà kò gbà ju èèyàn 80,000 àmọ́ àwọn àwòrán tó gbòde ṣàfihàn pé èrò tó wà ní ètò náà pọ̀ ju ọgbà náà lọ.

Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ní ọmọ kékeré, ọmọ ọdún mẹ́wàá wà lára àwọn èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn.

Gómìnà Kinshasa, Daniel Bumba nínú àtẹ̀j;ade kan tó fi síta dẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ru èrò tó pọ̀jù níbi ètò ọ̀hún.

Mínísítà fétò ìdájọ́ DR Congo ti pàṣẹ pé kí wọ́n ṣètò ìwádìí láti fìdí ohún tó wáyé gangan múlẹ̀ àti pé kí wọ́n fọ̀rọ̀ wá gbogbo àwọn ọlọ́pàá tó wà níbi ètò náà lẹ́nu wò.

Bákan náà ló ní kí wọ́n ṣe ìwádìí iléeṣẹ́ orin ẹ̀mí Maajabu Gospel tó ṣàgbékalẹ̀ ètò náà.

Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ tó ṣàgbékalẹ̀ ètò orin ọ̀hún fi síta ní ìpapòdà àwọn èèyàn náà jẹ́ ohun tó ba àwọn nínú jẹ́ gidi àti pé àwọn oníwàhálà ló fa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Wọ́n ní ọlọ́pàá ẹgbẹ̀rún méjì lọ wà níbi ètò náà tí wọ́n sì gbìyànjú láti paná wàhálà náà.

Bákan náà ni wọ́n ní èrò tó wà níbi ètò náà kò ju ẹgbẹ̀rún ọgbọ̀n lọ ní èyí tó kéré jọjọ sí èrò ẹgbẹ̀rún ọgọ́rin tí pápá ìṣeré náà le gbà.

Pápá ìṣeré náà, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn pápá ìṣeré tó tóbi jùlọ nílẹ̀ Áfíríkà ni ìjọba tí tì pa báyìí láì ní gbèdéke ọjọ́.

Ọ̀pọ̀ àwọn ayẹyẹ ni wọ́n máa ń ṣe níbẹ̀ bíi ìdíje bọ́ọ̀lù, ètò orin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kódà ibẹ̀ ni wọ́n ti ṣètò ìbúrawọlẹ̀ fún ààrẹ Félix Tshisekedi.

Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, àwọn aláṣẹ ìlú Kinshasa ti rọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti túnbọ̀ pọkún ààbò àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe àmójútó rẹ̀ pé àwọn tó bá fẹ́ ṣe ayẹyẹ ń tẹ̀lé ìlànà àti òfin tó bá yẹ láti pèsè ààbò fún ayẹyẹ wọn.

Ìgbá àkọ́kọ́ ka nìyí tí ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ń wáyé níbi ètò ayẹyẹ ńlá ní DR Congo.

Lọ́dún 2022, èèyàn mọ́kànlá ló pàdánù ẹ̀mí wọn ní pápá ìṣeré yìí bákan náà níbi ètò orin kan tí olórin Fally Ipupa ṣe.