You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé-iṣẹ́ ààrẹ fèsì sí ìròyìn tó ní Tinubu ti dá 'subsidy' orí epo padà láti lè paná ìwọ́de tó ń bọ̀
Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria ti fesi si àhesọ ọrọ kan to lu ori itakun ayelujara pa wi pe Aarẹ Bola Tinubu ti da owo iranwọ ori epo bẹntiróòlù ati tariifu owo ina pada lati le da ifẹhonuhan tawọn ọdọ n gbero lati ṣe duro.
Lọjọ Abamẹta ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Keje yii ni atẹjade kan eyi to ṣalaye igbesẹ Tinubu lati da ifẹhonuhan to n bọ duro lu ori itakun ayelujara pa.
Amọ, oludamọran aarẹ lori eto iroyin ati ọgbọn inu, Bayo Onanuga ti sọ pe iroyin ofege ni atẹjade naa.
Koko to wa ninu atẹjade to ni Tinubu ti da 'subsidy' ori epo pada ree
Atẹjade naa eyi ti wọn pe ni ọrọ aarẹ si araalu ṣalaye pe Tinubu loun ṣetan lati gbe awọn igbesẹ nla kan ti yoo mu adinku ba eto inawo ijọba latari bi nnkan o ṣe fararọ lorilẹede Naijiria lọwọ yii.
Atẹjade ọhun sọ pe Tinubu ṣetan lati mu adinku idaji ba owo oṣu at'awọn ajẹmọnu rẹ gẹgẹ bi aarẹ Naijiria.
Bakan naa ni Tinubu tun kepe igbakeji aarẹ, aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja ati gbogbo awọn to dipo nla nla mu lati ṣe bẹẹ pẹlu.
Atẹjade naa tun sọ pe ko ni si ọfiisi aya aarẹ mọ lati tubọ mu adinku ba eto inawo si.
Atẹjade ọhun tun ni ijọba yoo ta awọn ọkọ baalu ileeṣẹ aarẹ ti ko ri lilo daadaa mọ.
Ati pe adinku yoo tun ba iye awọn minisita ti wọn ko fi ni ju mẹrindinlogoji lọ.
Owo iranwọ ori epo ati ina ọba yoo pada lẹsẹ k'ẹsẹ ki ara le rọ araalu.
Gbogbo oṣiṣẹ ijọba yoo bẹrẹ si maa lo awọn nnkan ti wọn n ṣe ni Naijiria to fi mọ ọkọ ti wọn yoo maa gun.
Adinku awọn oludamọran ati amugbalẹgbẹ aarẹ lati le tubọ mu adinku ba eto inawo ijọba.
Atunto gbogbo iṣẹ ti ijọba gbe fawọn agbaṣẹṣe lati din ninu owo ti wọn fẹ fi ṣiṣẹ ku.
Gbigbẹsẹle irinajo silẹ okeere awọn oṣiṣẹ ijọba lori awọn nnkan ti ko ṣe pataki.
Aarẹ ko ni lọ fun itọju ara rẹ mọ loke okun. Aarẹ ati gbogbo awọn to n ba a ṣiṣẹ pọ yoo maa lo ile iwosan to wa ni Naijiria fun itọju ara wọn.
Atẹjade naa sọ pe awọn igbesẹ yii jẹ ibẹrẹ eto ọkan o jọkan ti ijọba Tinubu yoo gbe lati mu aye rọrun fun araalu.
Atẹjade naa tun ni aarẹ rọ awọn ọdọ to fẹ ṣe iwọde wi pe ki wọn jeburẹ, ki wọn si fun ijọba oun laye diẹ si wi pe gbogbo ohun to le lọwọ yii si n bọ wa dẹrọ.
Esi ileeṣẹ aarẹ si ahesọ ọrọ to lu ori ayelujara pa
Nínu ọrọ rẹ, oludamọran aarẹ lori ọrọ iroyin ati ọgbọn inu, Bayo Onanuga ṣalaye pe irọ to jinna si ootọ ni iroyin naa.
Onanuga sọ loju opo ayelujara X pe káwọn ọmọ Naijiria kọ eti ikun si atẹjade ọhun ti wọn pe ni ọrọ aarẹ si araalu.
"Irọ funfun balau ni, iṣẹ ọwọ awọn ti wọn fẹ da rogbodiyan silẹ ni Naijiria ni eleyii.
Ẹ ma dawọn lohun, Aarẹ Tinubu ko tii sọrọ kan kan," Onanuga lo sọ bẹẹ.