Èmi ò kán ọrùn Mohbad, irọ́ layé ń pa mọ́ mi, ìbátan rẹ̀ Darosha fi'gbe ta

Darosha Losobeh, ibatan akọrin takasufe Mohbad to si tun jẹ amugbalẹgbẹ rẹ ti fesi lori ẹsun pe o kan akọrin naa lọrun gẹgẹ bo ṣe jọ ninu fidio ibi tí wọn gbe Mohbad sinu posi.

Lọjọ Kejila oṣu Kẹsan ni akọrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn yi jáde laye ti iku rẹ si mu ki ọpọ ni Naijiria gbara ta.

Ariwo to sọ lẹyin iku rẹ lo ṣokunfa bi awọn agbofinro ṣe mu ọga ileeṣẹ akọrin ti Mohbad n ba kọrin Azeez Fashola to ọpọ mọ si Naira Marley ati Samson Balogun ti inagijẹ rẹ a máà jẹ Sam Larry.

Awọn mejeeji yi ni wọn mu lori ẹsun pe wọn n dunkooko mọ akọrin naa.

Wọn ti pada gba itusilẹ.

Amọ ọrẹ Mohbad kan Primeboy ati nọọsi ti wọn fẹsun kan pe o gun Mohbad labẹrẹ yi wa latimọle ti ọlọpaa sí ni awọn ni oju wa lara wọn ju nípa iku Mohbad.

Nigba to n fesi si ẹsun pe o kan ọrun Mohbad Darosha salaye loju opo rẹ ni Instagram lọjọ Abamẹta yi pe ki awọn to n gbe iroyin ofege yi dakun jáwọ nidi rẹ tori o n ṣe akoba fun ilera ọkan rẹ.

O kọ sibẹ pe " Inu mi bajẹ debi pe mo ni lati jáde wa kọ ọrọ yi ki o baa ma ruju pe mi o kan ololufẹ mi lọrun."

O tesiwaju pe "iṣẹlẹ yí jẹ nkan to bami ninu jẹ julọ pe mo kan ọrun ọmọ iya mi.O dun mi gidigidi "

Nkan to ṣẹlẹ gaan ree

O tẹnu bọ alaye pe nigba t'awọn de Ikorodu wọn sọ pe ko si aaye ti wọn yoo gbe oku si ni mọṣuari ati pe "" a o fẹ gbe oku rẹ si mọṣuari a o si fẹ sin lalẹ ọjọ yi""

O ni idi ree ti oṣiṣẹ mọṣuari kan se gbawa nimọran ka san owo ọkọ agbokusi nibi taa gbe sí titi ti ilẹ yoo fi mọ. Ọkọ yi naa ni yoo gbe lọ sibi ti wọn yoo ti sin oku rẹ.

O ni gbogbo mọlẹbi lo faramọ tori ọkọ agbokusi to gbe wa lati Island wa si Ikorodu ti n fohun sílẹ pe awọn ni lati pada lalẹ naa.

O fikun pe iya Mohbad nikan ni kò sí níbẹ lalẹ ọjọ naa.

Ibatan akọrin yi salaye pe nkan to kan ohun ninu gbogbo ọrọ yi ni pe oun ṣeto posi ati ọkọ agbokusi.

O ni oun ko mọ pe posi ti wọn gbe wa kere fun oku Mohbad.

O wa sọ pe gbogbo mọlẹbi lo ri oku rẹ ninu ọkọ agbokusi k'awọn to lọ sibi ti wọn ti sinku rẹ.

"Ko si ẹnìkankan to sọrọ nipa oku rẹ k'a to gbera lati lọ sin.Wọn o sọ nkankan nipa ori rẹ tabi ará rẹ kankan.Mi o sunmọ ibi ọkọ agbokusi tori ọkan mi ko balẹ.Oju opo ayelujara ni mo ti pada n gburo ọrọ nipa pe ọrun Mohbad kan . O bami ninu jẹ nigba ti mo ri "