Ìdí tí mo fí fẹ́ akọ̀wé ìjọba àpapọ̀, George Akume lẹ́yìn tí mo fi Ooni Ile Ife sílẹ̀ – Zaynab, Olorì Ooni Ogunwusi tẹ́lẹ̀ ṣàlàyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Olori Ọọni ile Ifẹ , Ọba Adeyẹye Ogunwusi nigba kan ri, Zanab Otiti to ti wa di Zaynab Ngohemba bayii ti ṣalaye nipa igbeyawo rẹ tuntun pẹlu akọwe ijọba apapọ orilẹede NAijiria, Sẹnetọ George Akume, eleyi to tọka si gẹgẹbi ajọṣepọ to ni ifọkanbalẹ ninu ati ipinnu lati ṣiṣẹ sin araalu.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, David Adeoye fi sita lori awọ ileeṣẹ iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria, Zaynab ṣalaye pe ko fi bẹẹ si iyatọ kankan lori ọna ti oun n tọ bikoṣe itẹsiwaju laarin awọn eeyan meji ti wọn ti n ṣiṣẹ sin araalu ṣaaju.

O ni lara awọn amuyẹ to mu ki ajọṣepọ awọn naa o duro deede ni ẹmi irẹlẹ, aanu ati ifaraẹnijin.

Atẹjade naa tun tẹsiwaju lati sọ pe ifẹ ọmọlakeji ati iduroṣinṣin to jẹ ọkan lara ohun ti awọn eeyan orilẹede yii n poungbẹ fun lasiko yii jẹ ohun kan to jẹyọ ninu igbe aye awọn tọkọtiyawo tuntun naa.

Zaynab ti ọpọ mọ si Olori Wuraọla fẹ Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi fun oṣu mẹtadinlogun laarin oṣu kẹta ọdun 2016 si ọdun 2017.