Ìjọba Eko ṣí ojú òpó láti ṣèrànwọ́ fáwọn ẹbí tí èèyàn wọn há sábẹ́ ilé ìtajà tó jó lọ́jà Balogun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, Lagos State Emergency Management Agency, LASEMA ti kéde pé àwọn ti ṣí ojú òpó láti ṣe ìrànwọ́ fáwọn èèyàn tí wọ́n ṣì ń wá àwọn èèyàn wọn níbi ìjàmbá iná tó wáyé nílé ìtajà Great Nigeria Insurance House, Balogun, Eko.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé látàrí báwọn ẹbí kan ṣe ń kọminú pé ó ṣeéṣe káwọn èèyàn àwọn ṣì há sábẹ́ ilé ìtajà náà tó jóná ní alẹ́ ọjọ́ ọdún Kérésìmesì ku ọ̀la.

Akọ̀wé àgbà àjọ LASEMA, Femi Oke-Osanyintolu nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sáwọn ẹbí àwọn èèyàn tí wọ́n pàdánù èèyàn wọn, tó sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wọn ẹ̀mí láti gba àdánù wọn.

Ó ṣàlàyé pé ojú òpó tí wọ́n ṣí náà wà fún àwọn èèyàn láti wá ṣe àkọ́lẹ̀ nípa àwọn èèyàn wọn tí wọ́n bá ń wá, tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé wọ́n ṣì wà nínú abẹ́ ilé ọ̀hún.

Ó sọ pé àjọ náà máa ṣe ìwádìí ohun tí wọ́n bá sọ fún àwọn nípa àwọn èèyàn náà, tí àwọn sì máa lò ó láti fi ṣe àkójọ gbogbo orúkọ àwọn tí wọ́n ń wá níbi ìjàmbá iná náà.

"Èyí máa ṣe ìrànwọ́ fún láti tètè ṣàwárí àti ìdánimọ̀ àwọn tó há sábẹ́ ilé náà."

Ó fi kun pé àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì yóò túnbọ̀ tẹ̀síwájú láti tú gbogbo abẹ́ ilé náà láti ṣàwárí rẹ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni tó há sábẹ́ ilé náà.

Láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé iṣẹ́ náà ló ṣe yẹ, LASEMA sọ pé àwọn ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn iléeṣẹ́ míì, tó fi mọ́ àwọn iléeṣẹ́ ètò ìlera, àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti lè jẹ́ kí iṣẹ́ náà ní àṣeyọrí.

Oke-Osanyintolu fi kun pé àwọn ní ìfarajìn láti túnbọ̀ máa dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá, tí àwọn yóò sì máa fi bí ìgbésẹ̀ náà bá ṣe ń lọ tó àwọn aráàlú létí.

Bákan náà ló rọ àwọn aráàlú láti ṣe sùúrù, kí wọ́n fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ iṣẹ́ pàjáwìrì, kí wọ́n ba à lè ṣiṣẹ́ wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

Ìjàmbá iná jó ilé ìtajà lọ́jà Balogun l'Eko lọ́dún Kérésì ku ọ̀la, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣófò

Níṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn olùtajà tí wọ́n ní ṣọ́ọ̀bù ni ilé ìtajà Great Nigeria Insurance House, tó jẹ́ ilé alájà púpọ̀ tó wà ní òpópónà Martins, Lagos Island, ìpínlẹ̀ Eko ń káwọn mọ́rí ní ọjọ́ ọdún Kérésìmesì ku ọ̀la bí ilé ìtajà náà ṣe gbaná lójijì.

Gẹ́gẹ́ bí fídíò tó gba orí ayélujára tí BBC News Yorùbá rí, níṣe ni iná náà gbilẹ̀ tó sì ń jó lala.

Àtẹ̀jáde tí àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko ìyẹn Lagos State Emergency Management Agency, LASEMA ṣe sọ, wọ́n ní àjà kẹrin ni iná náà ti dédé ṣẹ́yọ.

Adarí LASEMA Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde náà pé láti àjà kẹrin ni iná ọ̀hún ti ràn wọ àjà kẹfà, tó sì ń jò wá sílẹ̀.

Nǹkan bíi aago márùn-ún ku ogún ìṣẹ́jú ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ìjàmbá iná náà bẹ̀rẹ̀ táwọn òṣìṣẹ́ panápaná àtàwọn tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì sì gbìyànjú láti pa iná náà.

Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, a kò lè sọ bóyá èèyàn kankan bá ìjàmbá náà lọ àmọ́ ọ̀pọ̀ dúkìá olówó iyebíye ni ó run sínú ìjàmbá iná náà.

Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ṣì wà níbi ilé náà, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti pa iná náà, tí wọn kò sì le sọ ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá iná ọ̀hún.

Àwọn ibi tí ìjàmbá iná náà ti ṣọṣẹ́ ló jẹ́ ibi tí àwọn ọlọ́jà tí wọ́n ń ta aṣọ máa ń kó ọjà pamọ́ sí, tí àwọn iléeṣẹ́ kọ̀ọ̀kan náà sì wà níbẹ̀.