You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléẹjọ́ ICC pàṣẹ pé kí wọ́n fi Ààrẹ Russia sí àhámọ́
Ile ẹjọ agbaye to n gbọ ẹsun iwa ọdaran, ICC ti palasẹ pe ki wọn fi Aarẹ Russia, Vladimir Putin si ahamọ
Ileẹjọ fi ẹsun kan Putin pe oun lo sokunfa bi ogun se waye ati bi wọn se fi tipa tipa ko awọn ọmọ kekere ni ọna to lodi si ofin lati orilẹede Ukraine lọ orilẹede Russia.
ICC ni Putin ṣe si ofin ọhun ni orilẹede Ukraine lati ọjọ kẹrinlelogun ọdun 2022 nigba ti Russia ṣe ikọlu nla si Ukraine.
Moscow ti ni awọn ko lọwọ ninu ikọlu lasiko ti wọn fi ẹsun naa kan wọn.
Ileẹjọ ti wa fi ẹsun kan Aarẹ Putin pe o lọwọ ninu bi wọn fi ọna to lodi si ofin ko awọn ọmọde kuro lorilẹede Ukraine, ti ileẹjọ si ni gbogbo ọna lati ni igbagbọ pe Putin jẹ bi ẹsun naa.
ICC tẹsiwaju pe Olori ilẹ Russia kuna lati lo ẹtọ rẹ fi da awọn orilẹede yooku to n kuro ọmọ duro.
Bakan naa ni ICC kede pe awọn n wa Kọmisọna fun ẹtọ ọmọde lorilẹede Russia, Maria Alekseyevna Lvove Bolova.
Pẹlu bi wọn ṣe ikede pe ki wọn fi ofin gbe Putin ati kọmisọna rẹ, ileẹjọ ICC ko ni ẹtọ lati fo ofin gbe ẹnikẹni si atimọle sugbọn wọn le gbe idajọ kalẹ lori awọn orilẹede to tọwọ bọ iwe ahehun lati da ileẹjọ naa silẹ
Orilẹede Russia ko tọwọ iwe adehun naa, fun idi iye o sese ki idajọ naa ma ni isẹ nilẹ