Mr Macaroni fẹ́ gbé òṣèré tíátà, Lege Miami lọ sílé ẹjọ́, ó ń bèèrè N50m owó ìtanràn

Eekan alawada nni, Adebowale Adedayo, ti gbogbo eeyan mọ si Mr Macaroni, ti kọ iwe ipẹjọ si eekan oṣere tiata, Adams Kẹhinde, ti ọpọ mọ si Lege Miami lati san aadọta miliọnu naira fun ẹsun ibanilorukọjẹ to fi kan an.

Macaroni, lati ipasẹ awọn agbẹjọro rẹ lati ileeṣẹ Falana and Falana ṣalaye ninu iwe ipẹjọ naa, nipa awọn ẹsun ti wọn fi kan Lege Miami.

Awọn ẹsun naa si lo nii se pẹlu awọn ọrọ to sọ atawọn ẹsun to fi kan ouMr Macaroni eyi ti alawada naa lo ṣe ọpọ ipalara fun oun.

Lege Miami ati Mr Macaroni lo ti n fẹ oju toto mọ ara wọn lori ayelujara lori igun oṣelu ọtọtọ ti ikọọkan wọn to si bi o tilẹ jẹ pe ọrẹ ni awọn mejeeji.

Lege lo n gbe si ẹyin Asiwaju Bola Tinubu ti ilu ṣẹṣẹ yan si ipo aarẹ ati ẹgbẹ oselu APC.

Mr Macaroni ni tirẹ, n gbe sẹyin Peter Obi, to dije fun ipo aarẹ ṣugbọn to fidi rẹmi ati ẹgbẹ oṣelu Labour Party.

Ki lo wa ninu iwe ipẹjọ ti Mr. Macaroni fi ranṣẹ si Lẹgẹ Miami?

Ileeṣẹ amofin Falana and Falana lo kọ iwe ipẹjọ naa si Lege Miami, ti won sì sọrọ pe awọn ọrọ ati akọsilẹ kan to n sọ tabi kọ nipa Mr Macaroni, to jẹ onibara awọn ku diẹ kaato.

Wọn ni awọn ẹsun naa lo n ta abuku ba orukọ ati iyì Macaroni lawujọ, paapaa julọ, pe “Macaroni n gba owo lọwọ awọn kan lati ṣi awọn eeyan lọna.”

Bakan naa ni wọn tun sọ pe, Lege n sọ pe Mr Macaroni ko fẹran alafia ati wi pe o pe ero le onibara awọn lori lori ayelujara, to si ni ko lọ si gbangba ode wa fi atilẹyin han fun oludije tirẹ.

Awon ẹsun miran ti awọn amofin Macaroni tun fi kan Lege Miami ni pe:

  • O sọ lori ayelujara pe Mr Macaroni n lo ayederu ọjọ ibi
  • Lẹgẹ Miami ni pe ẹlẹtan ni Macaroni ati pe iwa jibiti pọ ni ọwọ rẹ
  • Lẹgẹ Miami tun fi ẹsun kan Macaroni pe o gba owo lọwọ awọn oloselu
  • Ati pe pẹlu eyi kii ṣe ẹni ti eeyan lee fi inu tan.

Awọn agbẹjọro Mr Macaroni wa n beere fun atẹjade loju opo ayelujara rẹ lati fi tọrọ aforijin lọwọ onibara wọn.

Bakan naa ni wọn tun ni ki Lege Miami funra ara rẹ sọ faye pe oun ko sọ ọrọ naa mọ.

Lẹyin eyi ni wọn tun beere fun owo itanran ibanilorukọjẹ aadọta miliọnu naira laarin ọjọ mẹta bibẹẹkọ ile ẹjọ ya.

"Ọrẹ ni emi ati Macaroni, Baba Falana, ẹ maa da sí ọrọ wa"

Saaju lẹyin ibo aarẹ, ni Lege Miami bọ si oju opo ayelujara Instagram rẹ, nibi to ti fi ọrọ ranṣẹ si Macaroni.

Ninu fidio naa si lo ti fi ẹsun kan Macaroni pe gbogbo igba lo maa n pariwo pe ki awọn ọdọ kọ ẹyin si Oludije ẹgbẹ oselu APC ti oun n tẹle.

Bakan naa lo ni Macaroni ko yẹ ko ṣi maa pe ara rẹ ni ọdọ tori o ti gbo, ti ọjọ ori rẹ si ju oun lọ.

O wa ke gbajare sí awọn ọdọ ninu fidio to fi soju opo ayelujara naa pe, ki won lọ ba Macaroni nitori pe igba ti ọrọ burẹkẹ tan lo ṣẹṣẹ wa n pariwo alaafia.

Amọ ṣa, lẹyin ti lẹta ipẹjọ naa de igboro aye, ni Lẹgẹ Miami pẹlu pada si ori ayelujara, lati kede pe ọrẹ ni oun ati Mr Macaroni, nitori naa, ki Amofin Falana mase daamu ara rẹ.

Lẹgẹ ni oun ati Macaroni yoo pari ọrọ naa ni itubi n nubi, ko si si owo kankan ti oun yoo san nitori pe ọrẹ lawọn mejeeji.