Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Ebenezer Obey jáde láyé

Ọfọ ṣẹ̀ nile agba ọjẹ akọrin Juju, Ajihinrere Ebenezer Obey-Fabiyi, pẹlu bi ọkan lara awọn ọmọ rẹ ọkunrin, Olayinka Olalekan ṣe jade laye.

Aṣoju Obey-Fabiyi, to jẹ mọnija rẹ, fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC ni owurọ ọjọ Aje, pe lọjọ Ẹti to kọja ni oloogbe Olayinka ku.

Iroyin sọ pe ẹni ọdun mejidinlaadọta ni oloogbe naa nigba to ku.

Wọn si ti sin oku rẹ ni ọjọ keji, ọjọ Satide Ọgbọnjọ, oṣu Keje, ọdun 2021.

Amọ titi di asiko yii, a ko ti i le sọ iru iku to pa a .

Bakan naa ni ko daju pe baba rẹ gan-an wa lorilẹ-ede Naijiria nigba ti ajalu buruku naa ja lu ile rẹ.

Idi ni pe, ni opin ọsẹ to kọja ni gbajugbaja pasitọ kan to jẹ ọmọ Naijriia nilẹ Gẹẹsi, Tobi Adegboyega, fi fidio kan sita, nibi to ti n ki Oloye Obey Fabiyi kaabọ sile rẹ.