You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'A ti sọ fún ìjọba Italy láti pèsè iṣẹ́ fún ìyàwó Alika tí wọ́n lù pa'
Ijọba orilẹede Naijiria ni awọn ti sọ fun ijọba orilẹede Italy lati pese iṣẹ fun iyawo arakunrin ti ọmọ orilẹede Italy lu pa laipẹ yii.
Ninu atẹjade ti alaga ajọ to n risi ọrọ awọn ọmọ Naijiria ni oke okun, Abike Dabiri-Erewa fi lede loju opo Instagram re ni wọn ti fi igbesẹ wọn lede.
Dabiri- Erewa ninu atẹjade to fi lede loju opo Instagram lo ti ni awọn ti bẹrẹ iduna dura pẹlu ijọba Italy lori iṣẹlẹ iku Arakunrin Alika naa
Iku Alika ko ni jasi asan
Arakunrin Alika to jẹ ọmọ Naijiria naa n ta ọja o sị jẹ abarapa, ti ọmọ orilẹede Italy naa fi igi to fi n rin naa lu u titi de oju iku.
Bakan naa lo ni wọn ti fi panpẹ ọba mu arakunrin to ṣekupa Alika naa, ti yoo si foju wina ofin.
‘’A ti sọ fun ijọba Italy wi pe ki wọn ripe opo Alika ni iṣẹ gidi lọwọ lati le toju ẹbi ati ara ti ọkọ rẹ fi silẹ lọ.
‘’Nitori pe arakunrin naa lo n toju ẹbi ati ara rẹ tẹlẹ, ki wọn to ṣekupa a.’’
‘’Mo tun fi asiko yii dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria kaakiri agbaye ati ni Italy fun adurọti wọn ati dida owo jọ fun arabinrin naa lati igba ti ọkọ rẹ ti ṣe alaisi mọ.’’
Ọwọ ti tẹ afurasi to Pa ọmọ Naijiria meji ni Canada
Ninu ọrọ ti Abike Dabiri-Erewa fi lede naa lo ti ni awọn ti kan si ijọba orilẹede Canada lori ọmọ Naijiria meji ti wọn ṣekupa lorilẹede naa.
Awọn mejeeji, Amos Arowoshegbe ati Chibueze Momoh ni wọn yinbọn pa ni ile ijo nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ aṣọle.
O ni ọwọ ijọba ilẹ Canada titẹ awọn to ṣekupa wọn naa, ti iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹle naa
Iyawo oloogbe ọmọ Naijiria ti ọmọ orilẹede Italy kan lu titi doju iku ti fọhun sita gẹgẹ bo ṣe n ṣọfọ iku ọkọ rẹ lọwọ.
Nínú fídíò kan ni ìyàwó Alika Ogorchukwu, Charity Oriachi ti ń bèrè fún ìdájọ òdodo lórí bí ọkùnrin náà ṣe rán ọkọ rẹ̀ sọ́run láì tó ọjọ́.
Charity ní ọgbẹ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ ti dá sí òun lọ́kàn lẹ́nu ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé kò kéré rárá.
Ó ní gbogbo ohun tí òun fẹ́ báyìí kò kọjá wí pé kí ẹni tó pa òun lọ́kọ náà gbọ́dọ̀ fojú winá òfin.
Ọmọ méjì àti ìyàwó ní olóògbé náà fi sílẹ̀ sáyé.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní orílẹ̀ èdè Italy ti ṣàfihàn arákùnrin tó pa ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà naa, Alika Ogorchukwu ní orílẹ̀ èdè Italy.
Fillipo Ferlazzo ni wọ́n pe orúkọ ọkùnrin ọhun.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní afurasí náà lu olóògbé, Alika Ogorchukwu dójú ikú nítorí pé olóògbé tọrọ owó lọ́wọ́ rẹ̀.
Wọ́n ṣàlàyé wí pé ẹ̀rọ ayàwòrán tó wà ní ojú òpópónà ṣàfihàn bí Ogorchukwu ṣe ń tọrọ owó lọ́wọ́ Fillipo àti ìkejì rẹ̀ ló fa èdè- àìyedè láàárín wọn.
Bákan náà ni wọ́n ní àwọn ti nawọ́ gán Fillipo tó sì ti wà ní àhámọ́ àwọn fẹ́sùn ìpànìyàn àti jíjí fóònù olóògbé náà.
Fillipo, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́pàá ṣe sọ, ti wà ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Montacuto ní Ancona.
Àfi kí ẹ tètè fojú ẹni tó pa Ogorchukwu hàn o, bí bẹ́ẹ̀ kọ...Ìjọba Nàìjíríà ránṣẹ́ n ò ní gbà lóríko ṣíṣekú pa ọmọ Nàìjíríà kan ní Italy
Ijọba Nàìjíríà ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Italy níbi èdè-àìyedè ti ṣokùnfà ikú ọmọ Nàìjíríà kan, Alika Ogorchukwu.
Ijọba orilẹede Naijiria fi aidunu rẹ han ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Naijiria fi sita lọsan ọjọ Aiku, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu keje, ọdun 2022.
Atẹjade naa ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere, arabinrin Francisca Omayuli fọwọ si ṣalaye pe ijọba Naijiria ti kọ si akẹgbẹ rẹ lorilẹede Italy lati tete fi arakunrin to ṣe iṣẹ laabi naa jofin lẹyẹ o ṣọka.
Bakan naa ni wọn tun ke si ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria lorilẹede Italy lati muu lọkunkundun pe wọn ko jẹ ki awọn ileeṣẹ ati ajọ gbogbo ti ọrọ kan pẹlu idajọ ododo fun oloogbe Ogorchukwu o sinmi titi ti igbesẹ gbogbo yoo fi waye.
“Ijọba orilẹede Naijiria bu ẹnu atẹ lu bi arakunrin ọmọ Italy kan ṣe ṣekupa ọmọ Naijiria, Alika Ogorchukwu ni Civitanova, lẹkun Marche lorilẹede Italy ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu keje ọdun 2022.
“Ijọba apapọ Naijiria bu ẹnu atẹ lu iwa ṣiṣekupa ọgbẹni Ogorchukwu lainidi, o si n ke si ijọba orilẹede Italy lati rii daju pe wọn tete fi ẹni to ṣiṣẹ laabi naa jofin ni kiakia ni ibamu pẹlu ofin gbogbo to ba yẹ.”
Ki ni ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria ni Italy sọ?
Aṣojú ọmọ Nàìjíríà ní Italy, Mfawa Omini Abam ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà banilọ́kàn jẹ́ gidi gan ni.
Abam wá ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn sí ìyàwó àti àwọn ọmọ méjì tó fi sílẹ̀ sáyé lọ.
Ó ṣàlàyé pé àwọn ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ìjọba Italy láti wá ìdàjọ́ òdodo lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti láti ri dájú pé àwọn ẹbí rẹ̀ rí ìrànlọ́wọ́ tó péye.
Bákan náà ló rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Italy láti ṣe sùúrù, kí wọ́n má gbèrò láti gbẹ̀san ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún lọ́wọ́ ara wọn.
Ó sọ àrídájú rẹ̀ wí pé ìgbésẹ̀ tó tọ́ ma wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ariwo sọ! Èèyàn kan lù ọmọ Nàìjíríà ẹni ọdún 39 títí dójú ikú ní Italy
Aworan ti kun ori ayelujara eyi ti ileeṣẹ Ọlọpaa ibilẹ ti orilede italy fi sita lẹyin iṣẹlẹ iku ọmọ orilede Naijiria kan ti wọn kọlu ti wọn si lu titit doju iku lọsan gangan ni iha aarin gbungbun.
Eyi ti fa ọpọlọpọ ariwo ati irunu nilu ati lori ayelujara bakan naa si ni eeyan kan tun ya fọnran iṣẹlẹ naa bi wọn ṣe luu pa.
Iṣẹlẹ naa waye aarin igboro ilu Civitanova Marche lọjọ Ẹti ọsẹ to kogba wọle yii nibi ti wọn ni arakunrin ọhun ti maa n ta ọja.
Fọnran fidio to jade naa ti iroyin s pe ara awọn oluworan lo yaa ṣafihan bi ẹnikẹni ko ṣe gbiyanju lati sa si didoola ẹmi arakunrin ọmọ Naijiria ọhun to si fihan bi arakunrin alawọfunfun ẹni ọdun mejilelọgbọn ṣe ki arakunrin ọmọ Naijiria ẹni ọdun mọkandinlogoji mọlẹ.
Fidio yii jẹ iyalẹnu fun awọn araalu ti pọlọpọ si n sọ ero wọn nipa iwa ti eeyan kọọkan to n woran iṣẹlẹ naa hu.
Amọṣa, gbogbo ohun to yi iṣẹlẹ naa ka ko tii hande.
Ariwo ipe fun idajọ ododo
Awọn alaṣẹ ti fi orukọ oloogbe naa sita bayii gẹgẹ bii Alika Ogorchukwu to ni iyawo, Charity Oriachi ti wọn si ni ọmọ meji.
Iyawo rẹ, Charity n wa ẹkun mu ni ti ko lee dakẹ gẹgẹ bo ṣe n ba awọn oniroyin sọrọ nipa bi wọn ṣe fi oku ọkọ rẹ han an to wa nilẹẹlẹ.
Lọjọ Satide, ṣe ni ọgọọrọ awọn eeyan tu si ita ni agbegbe ibi ti awọn ọmọ Naijiria n gbe ni Civitanova Marche lati ja fun idajọ ododo.
Bakan naa, awọn oloṣelu lorilẹede Italy ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa.
Enrico Letta to jẹ adari ẹgbẹ oṣelu ti igun ti wọn n pe ni “left-wing Democratiac Party, ni ohun to ṣẹlẹ yii “kọ ni lominu gidi”.
O kọ atẹjade kan si oju opo Twitter rẹ pe “ko si omi ti ẹni to ṣe iṣẹlẹ naa fi le wẹ ara rẹ mọ”.
Lafikun, adari ẹgbẹ oṣelu igun ti wọn n pe ni right-wing, Matteo Salvini naa fi ibinu rẹ han lori iku mọ Naijiria naa to si ni “awọn oṣiṣẹ alaabo ko ni awọ kankan ki wn si pada si ṣiẹ ohun to tọ”.