Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá mú àwọn afurasí ajínigbé 17 tó jí òṣìṣẹ́ Alao Akala gbé ní Oyo

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ní ọwọ́ òun ti tẹ àwọn afurasí agbébọn tó jí Christopher Bakare, ẹni tó ń ṣe àmójútó oko gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ náà, Adebayo Alao Akala.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi ọ̀rọ̀ náà léde.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo, Adewale Osifeso nínú àtẹ̀jáde tó fi síta ní àwọn tí àwọn nawọ́ gán náà jẹ́ afurasí ajínigbé tó ti ń da ìpínlẹ̀ náà láàmú lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.

Ní ẹnu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé ń wọ́pọ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo.

Ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje ni àwọn ajínigbé jí Bakare gbé ní inú oko náà ní Jabata, ìjọba ìbílẹ̀ Surulere.

Bákan náà ni wọ́n tún ji Dókítà kan, Abdulrasheed Oladoye, tó ni ilé ìwòsàn aládani kan, gbé ní ọjọ́ kejìlélógún ní agbègbè náà.

Osifeso ṣàlàyé pé àwọn afurasí mẹ́jọ ni àwọn ti nawọ́ gán báyìí lórí ìjínigbé Bakare àti Dókítà náà.

Àwọn tó ní àwọn ti fi òfin gbé ni Anjola Abubakar, Sani Abacha Abdullahi, Sani Abacha Jafaru, Sale Mohammadu, Isah Seriki Muhammed, Aliu Jafaru, Umar Abubakar àti Mustapha Baruguma.

Ó tún sọ síwájú pé àwọn mẹ́sàn-án mìíràn tún ti wà ní àhámọ́ àwọn fún ẹ̀sùn ijínigbé ní ìjọba ìbílẹ̀ Iwajowa.

Wọ́n tún nawọ́ gán àwọn mẹ́sàn-án mìíràn ní Iwajowa

Osifeso fi kun pé àwọn wọ̀nyí ló wà nídìí ìjínigbé tó ń wáyé ní ìlú Iganna, Iwere-ile àti Ijio.

Orúkọ wọn ni Umar Jale Usman, Abdullahi Mohammed Sani, Jamiu Jubril, Kayode Kolade, Leggi Usman, Jamiu Iroko, Sule Bello, Umar Shuaibu, àti Kali Weti.

“Lára àwọn ohun tí a bá lọ́wọ́ wọn ni ìbọn, ọta, bàtà, ẹgbẹ̀rún méjìlá owó, fìlà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó ni gbogbo àwọn afurasí náà ló ti jẹ́wọ́ wí pé àwọn lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn.

Ó fi kun pé ìwádìí ṣì ń tẹ̀síwájú lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Osifeso nínú àtẹ̀jáde náà rọ àwọn ará ìlú láti ma ran ìjọba lọ́wọ́ nípa fífi àwọn ìròyìn tó le ran ọlọ́pàá lọ́wọ́ láti lé dà ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá tó wọn létí.