Tinubu mórílé France lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ China yọ̀nda ọ̀kan lára báàlù iléeṣé ààrẹ mẹ́ta tó gbẹ́sẹ̀ lé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu yoo rinrin ajo lọ si orilẹede France lonii ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹjọ.

Oludamọran aarẹ lori eto iroyin ati ilukoro, Ajuri Ngelale ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe irinajo lẹnu iṣẹ ni abẹwo ranpẹ ti aarẹ yoo ṣe si orilẹede France.

Ajuri ṣalaye ninu atẹjade naa pe Tinubu yoo dari wale laipẹ lẹyin abẹwo rẹ si ilu Paris.

Oludamọran aarẹ ko sọ ẹkunrẹrẹ idi ti Aarẹ Tinubu fi gunle irinajo si France naa.

Ileeṣẹ aarẹ ko sọ ẹkunrẹrẹ idi abẹwo Tinubu si orilẹede France

Ajuri fi atẹjade naa sita nipa irinajo Tinubu lọ si orilẹede France lẹyin ti ileeṣẹ China, Zhongshan Fucheng Industrial Investment Co. Limited, to gbe orilẹede Naijiria lọ sile ẹjọ lori aitẹle adehun fi ọkan lara baalu mẹta ileeṣẹ aarẹ Naijiria to gbẹsẹ le silẹ.

Laipẹ yii ni iroyin kan jade eyi to sọ pe ileeṣẹ China ti gbẹsẹ le baalu ileeṣẹ aarẹ Naijiria, Dassault Falcon 7X, Boeing 737-7N6/BBJ ati A330-243 ti wọn wa ni papakọ ofurufu Paris-Le Bourget ati Basel-Mulhouse lorilẹede France.

Eyi lo waye latari bi ijọba ipinlẹ Ogun ti fagile adehun to kọwọ bọ pẹlu ileeṣẹ China naa lọdun 2016.

Amọ, atẹjade kan ti a gbọ wi pe agbẹnusọ ileeṣẹ China naa fi sita ṣalaye pe ileeṣẹ naa fi ọkan lara awọn baalu ọhun silẹ lẹyin ti ileeṣẹ aarẹ sọ fun wọn pe Tinubu fẹ lo ọkan ninu awọn baalu naa lati rinrin ajo lọ si France fun ipade kan pẹlu Aarẹ Emmanuel Macron orilẹede France.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa ni a gbọ pe o ṣalaye wi pe ileeṣẹ Zhongshan ti gbẹsẹ kuro lori ọkan lara awọn baalu ọhun ki Aarẹ Tinubu le lanfaani lati lo o fun abẹwo rẹ si France.

Igbakeji ree ti Tinubu yoo gunle irinajo silẹ okeere laarin ọsẹ kan lẹyin to ti ṣe abẹwo ọlọkọ mẹta si orilẹede Equatorial Guinea lọsẹ to kọja.