You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn agbófinró ya bo ibùba ajínigbé,dóòlà ogún èèyan ní Kwara
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, pẹlu ajọṣepọ awọn fijilante ati ọlọde ibilẹ, ti gba ogun eeyan ti awọn ajinigbe kan gbe wọgbọ lọ pada bayii lẹyin ti wọn ya bo wọn ni ibuba wọn.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ASP Ejire Toun Adeyemi, ṣalaye fun BBC pe nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii ni iṣẹlẹ naa waye.
O ni ọkọ ero mẹta ni awọn ajinigbe naa da lọna, nigba ti wọn n rin irinajo laarin Opopona Osi si Obo-Ayegunlẹ, ni ijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ ni awọn to wa nitosi ti fi to ọlọpaa leti bi Adetoun ṣe wi, ẹsẹkẹsẹ naa ni wọn si ti bẹrẹ igbesẹ didoola wọn.
Gẹgẹ bi ASP Ejire Adeyemi ṣe ṣalaye, o ni igbo ti awọn ajinigbe náà ko awọn ero ọkọ si lawọn ti yabo wọn.
O fikun ọrọ rẹ pe, ikọ ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, pẹlu awọn vigilante atawọn Ọdẹ ibilẹ ni awọn jijọ sisẹ náà papọ.
O tẹsiwaju pe eeyan mẹta lara awọn èèyàn ti wọn jigbe naa lo farapa, ti wọn si n gba itọju lọwọ báyìí.
''Ìwádìí ṣì ń tẹ̀ síwájú''
Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ijinigbe ọhun gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Kwara ṣe sọ.
O ni awọn yoo ri kulẹkulẹ iṣẹlẹ naa lati mọ awọn ajinigbe ọhun.
Bakan naa ni ọkan lara mọnlẹbi awọn ti wọn ji gbe to ba BBC sọrọ, Arabirin Ajayi Bọsẹ, sọ pe awọn ajinigbe naa pe awọn fun owo idoola, ṣugbọn awọn ko ti i sanwo naa.
Olori awọn ọdẹ ni Obbo Ayegunlẹ to ba BBC sọrọ, ṣalaye pe awọn ọdẹ ati fijilante agbeagbe naa ni wọn doola awọn eeyan yii, ki awọn ọlọpaa too darapọ mọ wọn ninu igbo.