You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èèyàn tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ẹ̀kún omi Niger ti di 230, 400 di àwátì
Alekun ti ba iye eeyan to ti padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ ẹkun omi to waye nipinlẹ Niger, eeyan 230 lo ti padanu ẹmi wọn sọwọ iṣẹlẹ naa bayii, ti 400 si dawati.
Igbakeji alaga ijọba ibilẹ Mokwa, Musa Kimboku lo kede eyi fun BBC, to si jẹ ko di mimọ pe igbiyanju n lọ lọwọ bayii lati ṣawari awọn eeyan ti wọn ko ri mọ.
Iṣẹlẹ omiyale yii ni igbagbọ wa pe ohun lo buru ju lorilẹede Naijiria.
Ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA, ni ẹkun omi ti sọ eeyan to le ni ẹgbẹrun mẹta di ẹni ti ko ni ile lori mọ, ti ọpọ ile si ti di ohun igbagbe.
Awọn eeyan ti iṣẹlẹ yii naa ṣe akoba fun ṣo fun BBC pe aṣalẹ ni ẹkun omi naa bẹrẹ, to si jẹ pe ọpọ eeyan to n sun lọwọ lasiko naa ti omi n gbe wọn lọ.
Aarẹ Bola Tinubu ti palaṣẹ fun Ajọ NEMA lati pese ile gbe fun awọn eeyan ti iṣẹlẹ ṣe akoba fun.
Iṣẹlẹ ọhun lo waye ni oṣẹ to kọja, to si gba ẹmi lọwọ ọpọ eeyan.
Ohun ti a ri gbọ ni pe ojo arọrọda lo ṣokunfa ẹkun omi naa.
"Iṣẹlẹ to buru ni, o le pupọ. A ri oku awọn eeyan ni ilẹ kiri."
Igbakeji gomina ipinlẹ Niger, Yakubu Garba sọ fun BBC lẹyin to ṣe abẹwo sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
"Ijamba nla ni iṣẹlẹ yii fun agbegbe Tifin Maza ati Hausawa ," Igbakeji gomina ṣalaye
O le ni eeyan 200 to ki ku bayii
Nigba to n ba BBC sọrọ, Igbakeji Gomina ipinlẹ Niger ni ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi sọwọ ẹkun omi to waye naa.
"Mo fi oju ara mi ri oku mọkanlelogun ni Raba, afara to so ilu Mokwa ja lulẹ. Ọpọ ile lo dawo," igbaekeji gomina sọ.
Garba ni yato si pe oku sun, ọpọ eeyan mii lo tun di awati.
"Awọn eeyan to sọnu, ti a ko ti ri oku wọn ni wọn le ni 400, a ko mọ ibi ti wọn wa ṣugbọn igbiyanju lati ri wọn si n tẹsiwaju.
"A lọ si awọn ile iwosan, a ri ọpọ eeyan to farapa yanayana ti wọn gba itọju.
'A ko ri irufẹ iṣẹlẹ ẹkun omi yii rii'
Olori ilu Mokwa, Muhammad Aliyu Shaba, ni oun ko ti ri iru ẹkun omi bayii lati igba ti wọn ti bi ṣaye.
"A ji, a ko si ri nnkan yatọ si omi to ti mu ile wa."
O ni gbogbo ọna to wọ ilu naa ni omi ti bajẹ, ti ko si si ọna abayọ.
Olugbe agbegbe naa to tun ba wa sọrọ, Abubakar Isa, ni iṣẹlẹ ẹkun omi ju agbara wọn lọ.
"Iṣẹlẹ gba a re, o ju agbara wa lọ, ko si nnkankan ti a le ṣe," o sọ.
O ni oun ko ti ri irufẹ ẹkun omi bayii ri ni igbesi aye oun.
"Lo jiji ni a ri omi to n wọ ile wa, ọpọ eeyan ku, wọn padanu nnkan oko wọn.
Ṣaaju ni awọn alaṣẹ ti ṣe ikilọ pe o ṣeeṣe ki ẹkun omi waye ni awọn ipinlẹ kan ninu ipinlẹ mẹrindinlogoji ti a ni lorilẹede Naijiria