You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléẹjọ́ dá aṣòfin tó ń ṣójú ẹkùn Ìjẹ̀bú North II padà sípò lẹ́yìn tí wọ́n fòfin dèé
Họnọrebu Oludare Oluwatimilẹyin Kadiri ni ilé ejo gíga ijoba apapo tí ó fìdí kalẹ sì Abẹ́òkúta tí ni kí òun padà sí ilé ìgbìmò asofin ipilẹ ogún láti máa tesiwaju nínú ṣíṣoju àwọn ẹkùn.
O ni ifaseyin ń lá ti dé bá àwọn ènìyàn agbegbe ọhun láti ìgbà tí wọ́n ti fi òfin de òun nílé ìgbìmò asofin ipilẹ ogún.
Ó fi ẹ̀sùn kan olórí ilé igbimo asofin ipilẹ ogún, Olakunle Oluomo wipe ó ń lo ilé ìṣe olopaa láti dùn kókó mọ òun.
Kadiri ni àwọn èto tí ó tó sì àwọn ènìyàn ẹkùn tí òun ń ṣojú ni wọ́n fi dùn wọn látàrí bí olórí ilé igbimo asofin ipilẹ ogún, Olakunle Oluomo ṣe gbedi lè àwọn owó tí ó tó sì ẹkùn náà.
Saaju ni abẹnugan ile igbimọ aṣofin, Olakunke Oluomo ti fofin de Dare Kadiri ati Solomon Osho.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe oun lo wa ni idi bi ajọ EFCC ṣe bẹrẹ si ni tọpinpin abẹnugan ile aṣofin naa lori ẹsun pe o ji iye owo to le ni biliọnu meji naira.