You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ jọ̀wọ́ ẹ dáwọ́ ogun dúró, kí kóówá sinmi ọdún– Aarẹ Russia ké sí Ukraine
Aarẹ orilẹede Russia, Vladimir Putin ti kesi adari ikọ ologun rẹ pe ki wọn dawọ ija duro fun wakati mẹrindinlogoji.
Aarẹ Vladimir Putin ni eyi yoo gba wọn laaye lati ṣe ayẹyẹ ọdun Keresimesi ti ijọ Othodox, eleyii ti wọn pe ni Othodox Christmas.
Putin wa kesi aarẹ orilẹede Ukraine lati dawọ ogun duro fun asiko yii.
Ọjọ Keje, Osu Kini ni ile ijọsin Eastern Orthodox ma n ṣe ayẹyẹ ọdun keresimesi ni ọdọọdun
Amọ aarẹ orilẹede Ukraine, Volodymyr Zelensky ni ko si ohun to jọ didawọ ogun duro ni agbegbe kankan.
Zelensky ni Putin n gbe igbeṣẹ naa lọna ati dẹkun igbeṣẹ ikọ ọmọgun Ukraine lati jawe olubori ni ila oorun orilẹede naa.
Wọn fikun un pe kii ṣe pe Putin fẹ dawọ ogun duro, amọ oun gbe igbeṣẹ naa nitori adari ijọ Orthodox church ni orilẹede Russia rawọ ẹbẹ si aarẹ naa.
Adari ijọ Orthodox, Patriarch Kiril ni iroyin ni pe o pe fun alaafia lasiko ọdun kere si naa ki awọn eniyan le ṣe ọdun ayọ, ki wọn si lọ si ṣọọṣi.
Ọjọ Keje, Osu Kini, ọdọọdun ni ile ijọsin Eastern Orthodox ma n ṣe ayẹyẹ ọdun keresimesi ni ọdọọdun.
Amọ Zelensky ni Russia n parọ ni ti wọn ko si fẹ ki Ukraine gba agbegbe Donbas pada lọwọ wọ.
Zelensky ni ọpọlọpọ igba ni awọn ti pe fun alaafia ti orilẹede Russia si kọ lati gba alaafia laaye.