Ààrẹ Macron pàdánù ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin sọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ alátakò

Ní bí kò ì tíì ṣe pé oṣù méjì tí Ààrẹ orílẹ̀ èdè France, Emmanuel Macron jáwé olúborí láti túkọ̀ orílẹ̀ èdè France lẹ́ẹ̀kan si, Macron ti pàdánù àkóso ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ orílẹ̀ èdè náà.

Níbi ètò ìdìbò tó wáyé ní ọjọ́ Ajé, ogúnjọ́, oṣù Kẹfà ni Macron pàdánú púpọ̀ nínú àwọn aṣòfin ilé sọ́wọ́ ẹgbẹ́ alátakò.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Macron rọ àwọn olùdìbò láti dìbò fún ẹgbẹ́ kan gbòógì nítorí àti ní ọmọ ẹgbẹ́ tó pọ̀ jùlọ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ wọn ló pàdánù ìbò wọn.

Alakoso àgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn, Elisabeth Borne ní àwọn kò ròó wípé àwọn le fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò náà tó báyìí.

Borne ní kò ì tíì wáyé rí pé àwọn alátakò ní ó pọ̀ jùlọ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní orílẹ̀ èdè France.

Pẹ̀lú bí Macron ṣe ti pàdánù ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin báyìí, ó ṣeéṣe kí àwọn ètò tó gbé dání láti fi mú àyípadà bá orílẹ̀ èdè náà má rí àmúṣẹ́.

Lára àwọn èròńgbà Macron láti mú ìgbé ayé rọrùn fún àwọn ènìyàn ni sísún ọjọ́ orí ìfẹ̀yìntì láti ọdún méjìléọgọ́ta sí márùndínláàdọ́rin àmọ́ èyí kò tẹ́ ẹgbẹ́ alátakò lọ́rùn.

Macron yóò ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ alátakò

Lónìí, ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kẹfà ni ìrètí wà wí pé yóò ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ alátakò lẹ́yìn tí òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pàdánù ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ sọ́wọ́ àwọn alátakò.

Ó pọn dandan fún Macron báyìí láti wá àtìlẹyìn àwọn alátakò kí ìjọba rẹ̀ le kẹ́sẹ járí.

Ṣùgbọ́n ó jọ́ wí pé Marine Le Pen àti Jean-Luc Mélenchon kò ṣetán láti sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Macron.

Ms Le Pen ti gbà kópa nínú ìpàdé ní tirẹ̀ àmọ́ Mélenchon ní òun kò ní kópa níbi ìjíròrò náà.

Bákan náà ni adarí ẹgbẹ́ àwọn Republican, Christian Jacob náà ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé òun yóò kópa nínú ìpàdé tí Macron pè.

Gbogbo ọ̀nà tí ìjọba yóò fi ṣe àṣeyọrí tí ètò òṣèlú kò ní dojúrú ní France ni Macron ń sáré báyìí.

Ètò ìdìbò tó wáyé ní àná ni ọ̀pọ̀ kò kópa láti dìbò.

Lára àwọn ohun tí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè náà ń bèèrè fún ni mímú àdínkù bá bí gbogbo nǹkan ṣe gbówó lórí pàápàá oúnjẹ.