You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Orílẹ̀èdè dá eyín kanṣoṣo tó kù lára òkú akínkánjú Lumumba padà fún mọ̀lẹ́bí rẹ̀
Awọn alaṣẹ Belgium ti da horo eyin kanṣoṣo to ku lara oku akinkanju ajijagbara fun ominira orilẹede Congo, Patrice Lumumba pada fun ẹbi rẹ nibi ayẹyẹ ti wọn ṣe nitori eyi ni Brussels. Eyi ni ẹya ara rẹ kanṣoṣo ti o ṣẹku to ṣi wa lorilẹ aye lati igba ti wọn ti pa a ti wọn si fi kẹmika "acid" yọ gbogbo ẹya ara rẹ lọdun 1961.
Taa ni Lumumba alagbara yii ati pe bawo lo ṣe ku?
Pipa ni wọn pa Patrice Lumumba ni o le ni ọgọta ọdun sẹyin nigba to jẹ olori ijọba awarawa akọkọ fun orilẹede Congo.
Iṣọwọọ bi wọn si ṣe ṣe oku rẹ ṣafihan pe wọn sọrọ iru ijọba amunisin to jẹ nigba aye rẹ ni. Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti ileeṣẹ iroyin DW ṣe pẹlu ọmọbinrin Patrice
Lumumba to ti di oloṣelu bayii ati ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin, o ni mọlẹbi awọn ti n duro tipẹ ki wọn da ẹya ara to ṣẹku lara oku baba awọn pada lati Belgium - eyin kanṣoṣo.
O ni "gẹgẹ bi ẹbi, a ni lati tẹsiwaju igbe aye wa, ọna kanṣoṣo taa si le gba ṣe eyi ni taa ba ti sin àkókùù ara baba wa lalaafia".
Ẹwẹ, o ni ọna ti awọn alaṣẹ fẹ gba daa pada lọwọ bakan bakan ninu ati pe iṣẹlu ajalu arun Covid-19 naa ṣe idiwọ fun didaa pada.
Amọ gẹgẹ bi itan, saa ijọba Lumumba ko tilẹ to ọdun kan lẹyin ti alatako rẹ, aarẹ Congo, Joseph Kasa-Vubu gbiyanju lati ṣii nipo. Laarin idarudapọ yii ni iditẹgbajọba kan ti waye eyi ti Joseph Mobutu dari to si gbajọba lọwọ Olootu naa.
Ibẹru eyi gaan lo faa ti wọn fi ṣekupa Lumumba ni ọdun 1961. Iroyin ni awọn ologun to jẹ ti awọn eeyan to yapa kuro lara ipinlẹ Katanga ni Congo lo pa a ti awọn alaṣẹ Belgium si mọ sii.
Kete ti wọn pa a, iroyin ni Ọlọpaa Belgium kan ti orukọ rẹ n jẹ Gerard Soete ati aburo gba akoso biba ara Lumumba jẹ lati lee bo aṣiri ohun to fa iku rẹ.
Ọjọ pe, ọjọ ti kò lonii lati da eyin Lumumba pada!
Ogunjọ oṣu Kẹfa iyẹn oni ni ọjọ naa ko bayii, eto akanṣe ayẹyẹ si ti wa nikalẹ lati da eyin Lumumba pada lonii. Pataki eyin yii gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ ni pe o duro fun asiko idamu ninu itan ati Belgium ati DR Congo - asiko to pe Belgium ṣi n gbiyanju lati ṣara jọ ninu ohun ti wọn la kọja. Ṣe ni wọn ge ara rẹ wẹlẹ wẹlẹ ti wọn si daa sinu paipu ti kẹmika "acid ku nu rẹ lati yọ ọ. Eyi ni ọlọpaa naa, Gerard pada jẹwọ pe o ṣẹlẹ.