You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléeṣẹ́ epo Shell kọtí ọ̀gbọin sí ìkìlọ àwọn tí epo ń ba agbègbè wọn jẹ́
- Author, Simi Jolaoso
- Role, BBC News, Ogoniland
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Iwadii BBC kan ti tuṣu desalẹ ikoko lori ẹsun ti awọn eeyan Ogoni kan fi n kan ileeṣẹ elepo rọbi nla nni, Shell, pe ileeṣẹ naa ko bojuto bo ṣe yẹ ki wọn ṣe atunṣe awọn agbegbe ti epo n ya si to si n ba nnkan jẹ ni Guusu Naijiria.
Awọn to n fẹsun kan Shell sọ pe awọn eeyan kan jokoo sidii owo ti wọn ya sọtọ fun atunṣe awọn agbegbe yii, wọn n nawo naa lai ṣe atunṣe si iya to n jẹ awọn ti epo n ṣe akoba fun.
Olu ileeṣẹ epo Shell to wa ni London, pẹlu ijọba Naijiria ti maa n sọ ọ leralara, pe iṣẹ n lọ daadaa lori atunṣe awọn agbegbe ti epo rọbi n ya si nilẹ Ogoni, eyi ti wọn lo bẹrẹ lọdun mẹjọ sẹyin.
Ṣugbọn iwadii BBC ti fi han pe ọpọ eeyan lo ti kilọ fun awọn alaṣẹ yii, pe awọn kan n kowo eto yii jẹ, iyẹn owo to to biliọnu kan dọla $1bn (£805m).
Onwoye kan ṣapejuwe eto atunṣe yii bii jibiti, eyi to ti fi ọpọ owo ṣofo, to si ti da awọn eeyan ilẹ Ogoni sinu iṣoro epo to n ba nnkan jẹ fun wọn.
Ninu alaye Shell fun BBC, ileeṣẹ naa sọ pe: " O ṣoro lati ṣiṣẹ lagbegbe Niger Delta, nitori wahala awọn to n jale epo.
"Nigba ti epo ba ja sibo mi-in lati ileeṣẹ wa, a maa tun gbogbo ibẹ ṣe, a dẹ maa wa ọna ti ko fi ni i ṣẹlẹ mọ. A o tiẹ ki n wo ti ohun to fa a, to ba ṣaa ti ṣẹlẹ pe epo n ṣan lọ sibi ti ko yẹ, a maa ṣatunṣe, a dẹ tun maa n fun awọn eeyan ati agbegbe to ba ṣẹlẹ si lowo."
Ẹsun ti wọn fi n kan ileeṣẹ Shell yii n waye lasiko ti igbẹjọ lori rẹ yoo bẹrẹ pada l'Ọjọbọ, nile ẹjọ giga ilu London, nibi ti awọn lọọya to n ṣoju ilẹ Ogoni meji yoo wa. Eeyan to to ẹgbẹrun lọna aadota lo n gbe lawọn ile Ogoni.
Ohun ti awọn Ogoni n sọ ni pe Shell gbọdọ ṣetan lati tanran iṣoro epo to ba igbesi aye awọn jẹ laaarin ọdun 1988 si 2020, eyi ti wọn ni ileeṣẹ epo naa lo fa a.
Awọn ilu Ogoni sọ pe epo to n ti ileeṣẹ Shell ya wa sọdọ awọn ti ba omi awọn jẹ, wọn ni awọn ko le dako mọ, bẹẹ ni awọn ko le pa ẹja ninu odo. Wọn fẹsun kan Shell pe wọn ti sọ aye awọn di okolombo.
Ẹwẹ, ileeṣẹ Shell to ti n wa bi yoo ṣe ta awọn dukia re to wa ni Naijiria ti ni awọn ṣetan lati ṣalaye ẹnu awọn lori ẹsun awọn Ogoni.
Shell loun ko ṣe aṣemaṣe to le ko ba igbesi aye awọn Ogoni, kaka bẹẹ, wọn ni awọn ọdalẹ to lọọ n ji ọpa epo bẹ, pẹlu awọn to n ṣe ibudo ifọpo ayederu lo da wahala silẹ.
Ẹka iroyinBBC ti ṣabẹwo si awọn agbegbe tọrọ yii kan ni Niger Delta, nibi ti ileeṣẹ epo Shell to tobi ju to si jẹ ti aladaani ni Naijiria ti ṣawari epo rọbi lọdun mejidinlaaadọrin (68) sẹyin.
Gẹgẹ bi ajọ Iṣọkan agbaye, 'UN' ṣe wi, o kere tan, agba epo miliọnu mẹtala (13 million barrels), tabi toonu kan aabọ (1.5 million tonnes) epo rọbi lo ti danu kaakiri Niger Delta lati ọdun 1958, yoo si to igba ẹgbẹrun meje ti epo ti n ya, to n ba nnkan jẹ ni ẹkun naa bi UN ṣe sọ.
Yiya epo yii ti ko idaamu ba ọpọ mọlẹbi, ọpọ ni ọna atijẹ wọn si ti di iṣoro.
'Ọmọ mẹ́jọ ni mo ti pàdánù níbi omi burúkú tí à ń mu'
Obinrin kan, Paulina Agbekpekpe toun naa n gbe lagbegbe Bodo, nilẹ Ogoni kan naa, so fun BBC pe ilẹ to n ṣan fun wara ati oyin ni ilu awọn tẹlẹ.
O ni ẹja po lodo, igi oko n ṣe daadaa pẹlu awọn eso loriṣiiriṣii ṣaaju yiya epo lati nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin.
Omi mimu ko nira tẹlẹ gẹgẹ bo ṣe wi, ko too di pe Shell de.
"Ni bayii, ọpọ awọn ọmọ wa lo ti ko arun latara omi buruku ti wọn n mu, ọpọlọpọ lo ti ku. Ọmọ mẹjọ ni mo ti padanu, ara ọkọ mi gan-an ko ya bayii.
"Wọn ti gba ọna atijẹ wa, ìyà lo ku ti awa eeyan Bodo n jẹ bayii, oju wa n ri to."
Bẹẹ ni Paulina wi.
Obinrin mi-in, Grace Audi, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37), n gbe lagbegbe Ogale, nilẹ Ogoni pẹlu ọkọ ati ọmọ ọdun meji ti wọn bi.
Grace ati ẹbi rẹ pẹlu awon alabagbe rẹ ki i ri omi lo, kanga kan ti epo ti bajẹ ni wọn ni. Eyi lo fa a ti wọn fi n fowo ra omi to mọ lati fi dana, fọṣọ, wẹ.
Lojumọ lori omi bi wọn ṣe wi, ẹgbẹrun mẹrin aabọ (4,500) ni wọn n na, owo ti wọn si n ri lojumọ ko to nnkan, ko to dọla mẹjọ oyinbo $8.
O kere tan bi a ṣe gbọ, o ti to igba ogoji ti epo ti ya si agbegbe yii lati ileeṣẹ epo Shell Gẹgẹ bi Leigh Day ti i ṣe agbẹjọrọ agbegbe yii ati awọn to sun mọ ọn ṣe sọ.
Kí ni BBC rí?
BBC ti ri awọn iwe abẹnu kan to n tọka pe ikilọ ti lọ sọdọ awọn aṣoju Shell ati ijọba Naijiria, pe awọn kan n ko owo to wa fun atunṣe agbegbe yii jẹ.
Ẹnikan to mọ nipa eto naa ba BBC sọrọ lai darukọ rẹ, ki wọn ma baa fiya jẹ ẹ . O ni:
"Awa funra wa mọ pe a n lu wọn ni jibiti ni. Ọpọ ohun ti a n ṣe la kan fi n gba awọn Ogoni loju." Bẹẹ ni ẹni to ta wa lolobo naa sọ.
O fi kun alaye rẹ pe:
"Arumọjẹ lasan ti wọn gbe kalẹ kawọn oloṣelu atawọn to wa nipo agbara maa fi jẹun ni."
Lara awọn ẹsun to wa nilẹ ti wọn fi n kan Shell ni: Gbigbe iṣẹ atunṣe fun awọn ileeṣẹ ti ko tiẹ mọ nipa ẹ.
* Mimu esi ayẹwo awuruju jade: Igba mi-in, wọn aa ni kinni kan ko ṣe omi ti epo ti wa lara rẹ, tabi ilẹ oko ti epo ti bajẹ.
*Bi wọn ba na ẹgbẹrun kan, bii ki wọn sọ pe mẹwaa lawọn na.
*Won ki i gba ki awọn alayẹwo lati ita wo ohun ti wọn n ṣe.
Ninu akọsilẹ ipade kan ti wọn ṣe ni 2023, eyi ti awọn aṣoju Shell naa wa nibẹ, wọn ri i pe awon agbaṣẹṣe ti ko kunju osuwọn ni wọn gbeṣẹ fun, wọn si pa wọn laṣẹ lati ma ṣe jẹ ki wọn ba nnkan jẹ ju bẹẹ lọ. Awọn UNEP ati naa wa nibi ipade ọhun.
Bakan naa, ninu aṣiri abajade kan to tu si BBC lọwọ lọdun 2023 kan naa, o fi han pe aiṣe deede wa ninu awọn abọ ti wọn jẹ pada lori iṣẹ atunṣe ilẹ Ogoni yii.
Ni 2022, Ajọ Iṣọkan Agbaye ( UN), kọwe si Naijiria, pe bi nnkan ko ba yipada, aiṣe deede ti a n wi yii yoo maa tẹsiwaju ni.
BBC kan si Hyprep ati ijọba Naijiria lati fesi si awọn ẹsun yii, ṣugbọn a ko ri esi kankan gba latọdọ wọn.
Ṣugbọn iwadii wa fidi ẹ mulẹ, pe ileeṣẹ Shell naa mọ nipa iṣoro yii.
Ìbẹ̀rù gba ọkàn àwọn èèyàn Ogoni
Ibẹru to wa lọkan awọn eeyan ilẹ Ogoni bayii ni pe o ṣee ṣe ki Shell sa lọ lai tan ọran ti wọn ni wọn da.
Wọn si tun n ro o pe o ṣẹẹ ṣe ki ileeṣẹ yii ṣi maa fi ilẹ Ogoni pawo lọjọ iwaju.
Awọn nnkan alumọọni bii epo rọbi ati afẹfẹ idana ti wọn n gbe jade ni Naijiria to ida 90%, ẹkun Niger Delta yii ni wọn si ti n ri pupọ rẹ.
Awọn olugbe ibẹ sọ fun BBC pe latigba ti wọn ti ṣawari awọn nnkan ọrọ̀ yii ni awọn ileeṣẹ nla-nla, awọn oloṣelu ati awọn ole to n ji epo wa ti sọ awọn di nnkan ipawo si apo wọn.
Patience Ogboe, araalu kan to di ẹbi ai ri nnkan oko mọ ru epo to n ya yii, sọ pe tẹlẹtẹlẹ, oun n ri nnkan oko jẹ, oun tun n ta lọja ti owo n wọle.
Ṣugbọn ni bayii,Patience loun ko ri jẹ debi ti oun yoo ri ta, bẹẹ ni obinrin ẹni ọdun mejilelogoji naa ṣalaye fun BBC.