You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ajínigbé márùn-ún tó jí Fulani gbé, tí wọn sì pa á, gbà Idájọ́ ikú l‘Osun
Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun awọn marun-un kan ti wọn ni wọn ji eeyan gbe, ti wọn si pada pa ẹni naa.
Awọn ti kootu ni ki wọn yẹgi fun naa ni Ibrahim Issa, Lateef Bello, Abdul Ramon Soliu, Bello Ibrahim ati Abudu Mumini Jolaanobi Saheed.
Nigba to n darukọ ẹni ti wọn pa naa, agbẹnusọ ijọba, Farẹmi Moses, sọ fun kootu pe Alhaji Ibrahim Adamu, gbajumọ Fulani l’Owode-Ẹdẹ, ipinlẹ Ọṣun, ni.
"Ẹbi Adamu san miliọnu mẹta tawọn ajinigbe ọhun beere, àmọ́ wọn pada pa a sigbekun"
O ṣalaye pe lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin ọdun 2018, awọn olujẹjọ yii ji Oloogbe Adamu gbe nile rẹ.
Mọto rẹ, Totota Corrola ni wọn fi gbe e sa lọ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹbi ọkunrin naa san miliọnu mẹta tawọn ajinigbe ọhun beere, agbefọba sọ pe wọn pada pa a sigbekun wọn.
Lẹyin ti ọwọ ba wọn, wọn foju ba kootu lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa ọdun 2021, wọn lawọn o jẹbi.
Awọn ẹri to foju han ti ọlọpaa to wadii iṣẹlẹ naa, Ganiyu Taofeek gbe kalẹ, pẹlu awọn ẹlẹrii mi-in to tun fidi ẹ mulẹ, mu ki Adajọ Kudirat Akano, paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun awọn olujẹjọ naa.
Ṣaaju ni lọọya wọn, Amofin Bọla Ige, ti sọ fun kootu pe ẹri agbefọba ko fẹsẹ mulẹ, ki Adajọ wo ti awọn onibaara oun ṣe.
Adajọ Akano ninu idajọ rẹ, sọ pe iwa ika to buru jai ni awọn olujẹjọ jẹbi rẹ.
O paṣẹ ki wọn yẹgi fun wọn ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.