You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé tí èèyàn 121 ṣe tẹ ara wọn pa ní ilé àdúrà mi - Olórí ẹ̀sìn
Lẹyin iṣẹlẹ ti eeyan mọkanlelọgọfa (121) ti tẹ ara wọn pa lọjọ keji, oṣu keje ọdun 2024 yii to waye ni orilẹede India, adari ẹsin to dari eto nibudo adura naa ti sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa rẹ.
Isin awọn Hindu kan ti wọn n pe ni Satsang ni wọn n ṣe lọjọ naa, lagbegbe Hathras, Uttar Pradesh, lorilẹede India.
Olori ẹsin naa tawọn eeyan mọ si Bhole Baba, ṣalaye pe awọn ọlọtẹ ti ko fẹran ohun tawọn n ṣe lo wa nidii iṣẹlẹ ọhun.
Orukọ ọkunrin naa gan-an ni Narayan Sakar Vishwa, ṣugbọn Bhole Baba lawọn eeyan mọ ọn si julọ.
Alaye ti lọọya rẹ, AP Singh, ṣe fun BBC ni pe awọn kan ti ko fẹran ohun to ba ti yatọ si ìṣe ilu ni wọn ditẹ mọ onibaara oun ti wahala fi de.
O ni awọn ṣetan lati ran iwadii tawọn agbofinro n ṣe lọwọ lori iku rẹpẹtẹ ọhun, awọn yoo si fọwọsowọpọ pẹlu ijọba.
Eeyan mẹfa lawọn ọlọpaa sọ pe awọn ti mu bayii ninu igbimọ to tẹ pẹpẹ eto adura naa.
Ariwo ni mo kọ́kọ́ gbọ́, lẹ́yìn náà làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣubú léra wọn lórí - O ṣoju mi kòró
Awọn ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ yii ṣalaye fun BBC pe,’’ko si wahala kankan lati ibẹrẹ eto, afi lojiji tawọn eeyan bẹrẹ si i pariwo, ti wọn si n ṣubu lera wọn lori.
" Ariwo ni mo kọkọ gbọ, ki n too mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn eeyan pupọ ti ṣubu lori ara wọn.
‘’Opọlọpọ eeyan ni wọn ti tẹ mọlẹ, mi o le ran wọn lọwọ tan. Ori lo ko emi naa yọ ti mo fi ye.”
Obinrin kan to pe orukọ rẹ ni Shakunntala, naa ṣalaye fun ẹka iroyin Press Trust ilẹ India, pe nigba ti wọn pari iwaasu nibi eto naa lo di pe awọn eeyan n sa jade.
" Awọn eeyan n ṣubu le ori ara wọn loju ọna, bẹẹ ni wọn ṣe n ku sori ara wọn”
Awọn fọto iṣẹlẹ aburu naa, ti ko ṣee wo fun ẹni ti ko ba lọkan akin, lo ti wa lori ayelujara bayii.
Awọn fidio kan naa ṣafihan ibi ti wọn ti n gbe awọn ti wọn farapa lọ sileewosan, bi wọn ṣe n gbe wọn si mọto, ni wọn n fi ọkada gbe wọn.
Fọnran kan ti BBC ri, ṣafihan ọpọlọpọ oku eeyan ti wọn tẹ sẹnu ọna abawọle ọsibitu kan, ti awọn ẹbi wọn si n sunkun kikoro, ti wọn n pe fun iranlọwọ.
Oṣiṣẹ kan to ṣoju ijọba ti wọn pe orukọ rẹ ni Kumar, sọ pe ero ti pọju nibi eto naa, awọn si ti gbe igbimọ ti yoo tọpinpin ohun to ṣẹlẹ dide.
Ni Hathras, ọpọlọpọ mọlẹbi lo n sunkun nileewosan nitori awọn eeyan wọn ti iṣẹlẹ yii kan, bẹẹ lawọn in ṣi n wa ẹbi tiwọn.
Oku tun pọ nileewosan ti awọn mi-in ko waa gba rara.
Iroyin sọ pe ọkọ agbokuu-gbe-alaarẹ(ambulance) ko to, oku meji si mẹta ni wọn n gbe de, ibanujẹ si kun ọkan awọn eeyan Hathras gidi.
Eyi kọ ni igba akọkọ ti ijamba yoo waye nibi apejọ ẹlẹsin ni India, pẹlu bo ṣe jẹ pe wọn saaba maa n kọ eti ọgbọnin si imọran awọn alaṣẹ nipa aabo.
Ni 2018, o to ọgọta eeyan to ku nigba ti ọkọ kan ja wọ aarin ero to n woran ọdun Dusshera, to si pa wọn.
Kí ló wáyé ní ìbùdó àdúrà tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èrò ṣe tẹ èèyàn 121 pa
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe o kere tan, eeyan mọkanlelọgọfa ni wọn ti jade laye lẹyin ti awọn eeyan tẹ wọn pa nibi eto adura kan ni India.
Awọn alaṣẹ ni ibi eto adura awọn ẹlẹsin Hindu kan to waye lagbegbe Hathras ni ipinlẹ Uttar Pradesh ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Iṣẹ ti bẹrẹ lati mọ awọn eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ ni pato, ti iroyin ni ọpọ wọn jẹ obinrin ati ọmọde.
Awọn to moribọ nibi iṣẹlẹ naa ti ṣalaye bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye, ki ori to ko wọn yọ.
"Iji nla kan fẹ lasiko nibudo adura yii, eyi to mu ibẹrubojo ba ọpọ eeyan, ti wọn si n sa kijokojo titi ti wọn fi tẹ ara wọn pa"
Awọn eeyan naa, lasiko ti wọn n ba BBC sọrọ ni awọn ko tii le sọ ohun gan to ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.
Amọ oṣojumikoro kan sọ pe ẹnu ọna to yẹ ki awọn eeyan gba jade ko gba wọn latari bo ṣe di gaga.
O ni iji nla kan tun fẹ lasiko naa, eyii to mu ibẹrubojo ba ọpọ ninu awọn eeyan ọhun, ti wọn si n sa kijokojo titi ti wọn fi tẹ ara wọn pa.
Ẹni kan to wa nibẹ ṣalaye fun BBC pe gbogbo eto lo n lọ wọrọwọ ki oun to bẹrẹ si n gbọ ariwo ọpọ eeyan.
O ni “ka to wi, ka ti fọ, awọn eeyan ti bẹrẹ si n ṣubu le ara wọn lori.”
“Ọpọ eeyan ni wọn tẹ pa ti ko si si ohun ti mo le ṣe lati ran wọn lọwọ, ori lo ko emi funra mi yọ.”
"Awọn eeyan n ṣubu le ara wọn lori, ki wọn to tẹ ara wọn pa, ọmọ kekere mẹta lo ba iṣẹlẹ ọhun lọ"
Obinrin kan to tun wa nibẹ, Shakuntala, sọ fun ileeṣẹ iroyin Press Trust of India pe “Lẹyin ti iwaasu pari, awọn eeyan bẹrẹ si n rọ sita.
“Awọn eeyan ṣubu sinu gọta lẹba ọna, wọn si bẹrẹ si n ṣubu le ara wọn lori ki wọn to tẹ ara wọn pa.”
Dokita kan to ṣetọju awọn to farapa, Umesh Kumar Tripathi, sọ pe ọmọ kekere mẹta lo ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn eeyan yoo tẹ ara wọn pa ni India.
Lọdun 2018, ọkọ oju irin kan ya bara lọ pa awọn eeyan to n woran Hindu lasiko ọdun Dusshera, nibi ti ọgọta eeyan ti jade laye.
Lọdun 2013, awọn to n ṣe ọdun Hindu ni Madhya Pradesh tẹ ara wọn pa, nibi ti eeyan 115 ti jade laye.