Akọ̀ròyìn wọ gàù fún sísọ̀rọ̀ àlùfàǹsá sí ààrẹ

Oríṣun àwòrán, AFP
Ilumọọka akọroyin kan lorilẹede Tunisia ti wọ gbaga awọn agbofinro fun sisọrọ alufansa si aarẹ orilẹede naa.
Adajọ kan paṣẹ ki wọn gbe Zied el-Heni lọ si atimọle ṣaaju igba ti igbẹjọ rẹ yoo fi bẹrẹ ni pẹrẹu.
Bi o ba jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, Zied le fi ẹwọn ọdun marun un jura.
Awọn ajafẹtọ lorilẹede Tunisia ti n kọminu lori ipo ilera akọroyin naa nitori irpyin sọ pe o ti fi igbakan ri ni arun rọparọsẹ lawn ọdun diẹ sẹyin.
Ko din ni awọn eekan lagbo oṣelu, eto idajọ, iroyin ati ọrọ aje ti awọn adajọ ti bẹrẹ igbẹjọ tabi ṣe idaj wọn fun titako Aarẹ Said.
Awọn ẹgbẹ alatako ti koro oju si awọn igbesẹ naa gẹgẹbi eyi to lọwọ kan oṣelu ninu.








