You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
IPOB members released: Ìjọba Nàìjíríà tu àwọn ọmọ ìkọ IPOB mẹ́ta sílẹ lẹyìn ọdún méjì àbọ ní àhámọ́
Ijọba apapọ Naijriia ti tu awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ ikọ ajijagbara Indigenous People of Biafra,IPOB, kan tawọn ọmọ ogun Naijiria mu lati ọdun 2020 silẹ.
Ni agbegbe Imo River ni ipinlẹ Abia ni wọn ti mu wọn lọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Keji 2020.
Awọn taa n wi yi, Sunday Nwafor ẹni ọdun mọkandinlọgọta;Uzonwanne Ejiofor ẹni ọdun mejidinlaadọta ati Wilfred Dike ẹni ọdun mẹrindinlogoji.
Ọdun meji le diẹ ni wọn fi wa ni ahamọ ọmọ ogun Naijiria ni 14 Brigade Nigerian Army Ohafia, ipinlẹ Abia.
- Kíló kàn? Òkú Obabìnrin Elizabeth II ti wà ní Gbọ̀ngan Westminster báyìí kí àwón èèyàn lè wá wòó láti bu ọlà ìkẹyìn fún un
- Ìjọba san owó gbà-ḿá-bínú fún àwọn tí ọlọ́pàá fi ìyà jẹ
- Wo bí ìrìnàjò Pósí Obabìnrin Elizabeth II ṣe rin títí tó fi dé sí Gbongàn Westminster...
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti mú arábìnrin ìbátan àwọn ọmọ òrukàn tí wọ́n bá òkú wọn nínú àpótí aṣọ
Ẹwẹ, ajọ ajafẹtọmọniyan Amnesty International, ti fesi si itusilẹ awọn afurasi wọn yi ti wọn si ni o jẹ nkan idunnu.
Ninu ọrọ ti ajọ naa fi si oju opo rẹ ni Facebook, Amnesty International sọ pe o ti pẹ tawọn ti n gbiyanju lati ri pe wọn tu wọn silẹ.
''Itusilẹ wọn yi ko ṣẹyin ipolongo ati ipe ki wọn tu wọn silẹ to fi mọ eleyi taa ṣe ni nkan bi oṣu meji sẹyin''
- Ìjọba mi ti ṣiṣẹ́ dáadáa, mo ṣi gbìyànjú láì náání ìṣòro ètò aàbò- Buhari-
- Ní Ilorin, Àwọn ọmọ Yahoo rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá he, wo ẹ̀ṣẹ̀ tí òfin ká mọ́ wọn lọ́wọ́
- Makinde pè fún ìkọ̀wéfipòsílẹ̀ Ayu gẹ́gẹ́ bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kí àláfíà lè jọba
- Ìdílé 9 nínú ìdílé 11 tó yẹ fún oyè Alaafin ní kí Makinde fòpin sí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nùwò sípò Alaafin
- À-wọn ará Ogbere-Tioya ké gbàjarè síjọba lórí afárá àdúgbò náà tó wó lulẹ̀
Amnesty International tẹsiwaju pe awọn rọ awọn alaṣẹ Naijiria lati safihan iroyin nipa awọn mii to wa ni ahamọ.
Wọn fi kun pe ki wọn ri pe awọn mọlẹbi ati agbẹjọro awọn to wa ni ahamọ lanfaani lati foju kan wọn.
Ijọba ko ṣalaye ohun ti o ṣokunfa itusilẹ yi bẹẹ ikọ IPOB ko ti sọ nkankan lori itusilẹ awọn wọnyi.
Ikọ IPOB jẹ ikọ to n ja fun idasilẹ orileede Biafra lati yapa kuro ni Naijiria.
Olori ikọ naa Nnamdi Kanu n ṣẹjọ lọwọ pẹlu ijọba apapọ lori ẹsun to da lori igbimọran lati ditẹ yẹ aga nidi ijọba.