Ìròyìn òfegè wà lára àwọn ìpèníjà tó ń dojúkọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà - Buhari

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ni iroyin ofege wa lara awon ipenija to n kona mọ ìṣoro igbesunmọmi, ti o sìn n ṣe akoba fun ilọsiwaju orilẹede Naijiria.

Buhari sọ eyi gẹgẹ bi ọkan lara agbẹnusọ rẹ, Ibrahim Gambari ṣe gba ẹnu rẹ ṣiṣọ loju ọrọ nibi ayẹyẹ ajọ UNESCO ti awọn ọdọ ṣe agbatẹru rẹ eyi to waye lọjọ Ajẹ.

Buhari ni bi Orilẹede Naijiria ba le yago fun iroyin ofege, pupọ lara awọn ìṣoro paapa julọ ìṣoro igbesunmọmi yoo wa sopin ti ilọsiwaju yoo si deba ilẹ Naijiria.

"Ti a ba le fi aye gba iroyin ti kìí ṣe ofege laye, ó jẹ ọkan lara ohun ti yoo mu atunṣe ba Orilẹede Naijiria, tí yoo si fọ ọ mọ.

"Pupọ lara awọn nnkan to fa ipenija yii ni bi iroyin ofege ṣe gba Orilẹede kan, ti o si ṣe ọpọlọpọ akoba fun Orilẹede Naijiria."

Aarẹ Muhammadu Buhari wa rọ awọn ọmọ orile-ede Naijiria lati jina si pinpin iroyin ofege kaakiri, eyi to lewu lọpọlọpọ fun ilọsiwaju ati idagbasoke orile-ede Naijiria.

"Ìjọba mi ti ṣiṣẹ́ dáadáa, mo ṣì gbìyànjú láì náání ìṣòro ètò aàbò"

Aarẹ Muhammadu Buhari ni isejọba oun ti ṣe daada fun awọn ọmọ Orilẹede pẹlu ìranlọwọ oun alumọọni to wa layika.

Aarẹ sọ eleyi nigba to ṣe ipade pọ pẹlu ìjọba ìpinlẹ Imo ninu lẹyin to ṣe ifilọlẹ awọn opopona eyi ti Gomina Hope Uzodimma ti ipinlẹ ṣe agbatẹru rẹ.

O ni isejọba ri nkan nawọ gẹgẹ bi aseyọri pẹlu bi rogbodiyan ṣe n waye lọtun losi lorilẹede Naijiria.

"Isejọba yii ti ṣe dada gidi gan. Mo ni lati sọ eleyi nitori awọn to sọ sìta kuna lati ṣe bẹẹ."

Aarẹ Buhari ni ìjọba oun lo le awọn agbebọn Boko Haram kuro ni agbegbe yatọ nigba ti ẹgbẹ oselu PDP wá ni isejọba lọdun 2015.

Aarẹ tẹsiwaju pe isejọba oun ri ọpọlọpọ isoro sugbọn ìṣe n lọ lati fi opin si gbogbo ìṣòro ti awọn ọmọ Orilẹede Naijiria dojú kọ.

"Mo wọ ìjọba nígba tí gbogbo nkan ti doju bolẹ."Ko si ina monamona, awọn opopona na ko da, epo bentiro ja walẹ sugbọn a mori bọ nibẹ."

O wa kan sara si isejọba Hope Uzodimma fun bi o ṣe ransẹ pe oun ni ẹmeji laarin ọdun kan lati wa ṣe ifilọlẹ awọn isẹ akanṣe.

Aarẹ ni ìjọba yoo tẹsiwaju lati ma ṣe iranwọ fun awọn ipinlẹ kaakiri Orilẹede Naijiria.