You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba san owó gbà-ḿá-bínú fún àwọn tí ọlọ́pàá fi ìyà jẹ
Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria, Human Right Commission ti san iye owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin owo dọla ilẹ okeere fun awọn ti wọn lugbadi ifiyajẹni lọwọ ọlọpaa.
Awọn eniyan mejidinlọgọta to jẹ mọlẹbi awọn wọnyii ni wọn fun ni owo gba mabinu naa.
Eyi ko ṣẹyin iwadii oniruuru ti wọn ṣe lẹyin ti awọn mọlẹbi fi aidunnu wọn han si bi ikọ ọlọpaa lorilẹede Niajiria ṣe pa awọn mọlẹbi wọn, ti awọn miran poora, ti wọn fi panpẹ mu awon elomiran lọna aitọ.
Awon ẹsun mii ti wọn fi kan awọn agbofinro:
To fi mọ gbigba ohun ini paapaa ẹka ọlọpaa ti wọn mọ si kogberegbe, ko to di pe ijọba tu wọn ka.
Olori Ajọ to n ja fẹtọ awọn ọmọ Naijiria, Tony Ojukwu ni ki awọn mọlẹbi ma ri owo naa gẹgẹ bi owo ẹmi awọn eniyan wọn .
Ojukwu salaye wi pe ko si ohun to lee ra ẹmi awọn eniyan wọn pada, amọ ẹtọ awọn mọlẹ bi ni ki ijọba san owo gba ma binu.
Bawo ni iwọde #End SARS se bẹrẹ?
Ni Osu Kẹwaa, ọdun 2020 ni ileeṣẹ ọlọpaa ẹka SARS fa rogbodiyan lorilẹede Naijiria, ti ẹgbẹgbẹrun awọn ọdọ tu jade lati tako ẹka ileeṣẹ ọlọpaa naa.
Lẹyin naa ni ijọba gbe igbimọ kalẹ to ṣewadii awọn aṣemaṣe ti ẹka SARS se ati ifiyajẹni lọna aitọ lati ọwọ awọn ọlọpaa.
Ọpọlọpọ mọlẹbi lo jade wa nigba naa lati wa sọ iriri wọn pẹlu mọlẹbi ti wọn pa abi ti wọn sọ di alaabọ ara.