Àwọn aṣòfin UK dáwọ́ ìdìbò Brexit dúró, Boris Johnson fáàkékọ́rí

Awọn aṣofin ilẹ United Kingdom ti fariga pe awọn koni dibo loni lori igbesẹ ti o fẹ ki ilẹ Gẹẹsi kuro ninu ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu (EU).
Kete ti awọn aṣofin sọ erongba wọn di mimọ ni ohun naa fesi pe ohun yoo gbe agbadofin ti yoo jẹ ki wọn le kuro ninu EU jade ni ọsẹ to n bọ.
Ṣugbọn o ti wa di dandan bayii fun lati beere afikun ọjọti yoo kọja gbedeke ọjọ kọkanlelọgbọn (31) oṣu kẹwa ti wọn ṣadehun tẹlẹ.
Eleyi ko ṣẹyin bi awọn aṣofin ti ṣe ni awọn ko ti ṣetan lati dibo lori igbesẹ rẹ.
Bi ọrọ naa ti ṣe n waye ni ṣiṣẹntẹle
Olori orilẹ-ede yii n gbiyanju lati jẹ ki awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin fọwọsi adehun ti o ṣe pẹlu ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu, EU lori ọrọ Brexit Mo mọ̀ pé àwọn aṣòfin máa ṣatìlẹyìn tó yẹ fún mi- Boris.
Boris Johnson ṣalaye fawọn ọmọ ile igbimọ pe: Asiko ti to ki a ṣe ohun to yẹ yii nipa gbigbe igbesẹ akin nitori sisun un siwaju kọja ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa yoo lewu pupọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sugbọn awọn aṣofin n jiroro boya wọn ṣi le sun ọjọ iyọkuro Britain ni ajọ ilẹ Yuroopu siwaju sii titi UK a fi sọ awọn abadofin rẹ di ofin.
Agbenusọ fawọn Common, John Bercow ti gbe igbesẹ atunṣe pe ki wọn beere fun asiko sii ti awọn ọmọ ile ba gbaa wọle.
Awọn ti DUP ati awọn aṣofin ẹgbẹ alatako ni wọn ti ṣetan lati dibo lodi si igbesẹ Boris Johnson.
Boris Johnson to n tukọ ijọba ni London gabgbọ pe o keere tan awọn mẹsan an ninu ẹgbẹ oṣelu Labour a dibo fun oun ati awọn mọkanlelogun to ni wọn ṣe lodi soun loṣu to kọja.

Steve Baker to jẹ alaga ajọ aṣewadii nilẹ Yuroopu, atawọn ikọ Tory Brexiteers ti n parọwa fawọn ọmọ ẹgbẹ wọn.
Lati ọdun 1982 ni awọn aṣofin ti joko ile lọjọ Abamẹta gbẹyin nitori ọrọ Falklands.
Awọn aṣojuṣofun yoo ni anfaani lati beere ibeere lọwọ Boris Johnson daadaa ki wọn to le dibo titi aago meji abọ ọsan oni.
Koko inu Ọrọ akọsọ lẹnu Boris Johnson
Kete ti olori ile, Boris Johnson bẹrẹ ọrọ iṣide rẹ ni London lo ti sọ pataki iṣọkan fawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin.
Boris rọ wọn pe ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu oun lati wo aisan iṣelu UK san lasiko yii.
Ogbeni Johnson tun parọwa pe ki gbogob ile gbe igbesẹ lati fopin si ijiroro lori abadofin ọdun 2016 lonii.
O ni loju ti oun, ọna abayọ to dara julọ ni oun gbe wa siwaju ile yii ti ko si si aaye fun sisun igbesẹ yii siwaju mọ.














