Amòfin: Ata tajútajú kìí se ẹrù òfin

Ọlọ́pàá ń fín tajútajú sí àwọn èèyàn kan lára

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Àwọn eeyan kaakiri ti n sọrọ lori rẹ lori ẹrọ ayelujara
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ni ọjọ iṣẹgun ni arakunrin kan sọ lori ikanni twitter rẹ pe, awọn ọlọpa mu oun lẹyin ti wọn ba agolo ata tajutaju (pepper spray) lọwọ rẹ.

Lati igbayi si ni awọn eeyan kaakiri ti n sọrọ lori rẹ lori ẹrọ ayelujara.

Esi ti ọga ọlọpa lẹka eleti gbaroye nileeṣẹ ọlọpaa, PCRRU, ACP Abayọmi Shogunlẹ, sọ pe ẹru ofin ni Ata tajútajú, èyí tó tubọ bu epo si ẹhonu awọn eeyan lori ọrọ naa.

Nigba ti BBC Yoruba kan si amofin ajafẹtọ araalu kan, Alfred Adegoke ni, ko si ofin kan lorilẹede Naijiria to tọka si tajutaju olomi ata, (pepper spray) gẹgẹbii ohun ija oloro.

Amofin Adegoke ni, ohun ija idaabobo ara ẹni ni tajutaju olomi ata, (pepper spray) jẹ atipe, ko si ohun kan ti ofin pe ni nnkan ija oloro, bikoṣe ohun ti awọn eeyan ba fẹ loo fun ni yoo sọ ni pato ohun gan to jẹ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

"Niwọn igba ti kii ṣe pe wọn baa, to fi n ṣe isẹ́ ibi, ofo lasan ni irufẹ ọlọpaa bẹẹ n tọpasẹ rẹ.

Ata tajútajú ni ohun idaabobo ti awọn obinrin n lo, fi daabo bo ara wọn lọwọ awọn leṣebi-leṣeka ẹda, paapaa julọ awọn afipabanilo."

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Èkó, Chike Oti ni, lootọ ko si ofin to de Ata tajútajú labẹ iwe ofin orilẹede Naijiria, sibẹ awọn abala kan wa to dee.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan

" Ohun ija olóró ni a le ka Ata tajútajú sí. Ko si eeyan to laṣẹ lati loo; koda ọlọpaa pẹlu ko laṣẹ."

Ata tajútajú kii ṣe ohun ija oloro ti ofin lodi si rara

Ninu ọrọ tirẹ, ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lẹkun kọkanla, Zone XI nilu Oṣogbo, AIG Agboọla Oshodi-Glover ni, ninu iwoye toun, Ata tajútajú ko tan mọ awọn nnkan ti a lee pe ni nkan ija oloro.

Ninu ọrọ to ba BBC yoruba sọ, "ninu iwoye temi, Ata tajútajú kii ṣe ohun ija oloro ti ofin lodi si rara."