Nigeria-China Loan: Afenifere korò ojú sí ìjọba Buhari, bó ṣe ń yáwó kiri

Ẹgbẹ ọmọ bibi ilẹ Yoruba, Afenifere ti kede pe ko si ilẹ kankan ti ilẹ Yoruba yoo gbe jalẹ fun awọn tijọba apapọ jẹ ni gbese, ti wọn wa sin owo wọn.

Ẹgbẹ Afenifere kede bẹẹ lasiko to n sọ ero rẹ lori bi ile asoju-sofin se pariwo sita pe si ijọba apapọ ti ta ominira Naijiria fun ilẹ China lati fi ya owo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afenifere, Yinka Odumakin fisita lo sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe ominu n kọ awọn ọmọ Naijiria lori igbesẹ ijọba apapọ naa.

O ni "Ilẹ Yoruba ko ni gba ki ajeji kankan wa gba ilẹ rẹ kankan lati fi di owo rara nitori asise ijọba kankan to kundun ko maa ya owo kiri."

Èlé orí owóyàá China rọjú la ṣe fẹ́ gbà á - Ìjọba àpapọ̀

Bi ijọba apapọ ko ba gba owoya mọ, opin de ba isẹ idagbasoke ta n se nu u.

Yoruba ni ẹla lọrọ, ti a ko ba laa, kii tete ye ni.

Eyi lo mu ki minisita feto irinna lorilẹede yii, Rotimi Amaechi to fi n salaye fawọn ọmọ Naijiria lori idi ti ijọba apapọ se fẹ gba owoya lọwọ ilẹ China.

Amaechi, lasiko to n kopa lori eto ori mohun-maworan kan nilu Eko lo sisọ loju ọrọ yii.

O ni "ele ori owoya ti China fẹ gba kere jọjọ si tawọn orilẹede alagbara lagbaye yoku, ni ijọba apapọ se n gbe igbesẹ lati gba a.

Bakan naa, awọn ilana ta gba da owoya naa pada ati isunsiwaju akoko to yẹ ki a da owoya naa pada, ko nira rara, a si ri pe owoya ti China fẹ fun wa rọrun."

Minisita feto irinna ni bi ijọba apapọ ko ba gba owqoya ilẹ okeere nitori bawọn eeyan kan se n bu ẹnu atẹ lu, a jẹ pe opin yoo de ba awọn isẹ idagbasoke tijsba apapọ dawọle ni.

Amaechi tun lo anfaani eto naa lati ja ahesọ ọrọ kan to n lọ kiri pe Naijiria ti ta ominira rẹ fun China nitori abala ofin kan to wa ninu iwe adehun ti wọn tọwọbọ lori gbigba owoya naa.

"Abala ilana yii kan wa ninu iwe adehun naa ni lati fidi rẹ mulẹ pe orilẹede Naijiria yoo da owoya naa pada, kii si se pe a fẹ gbe ominira wa le ilẹ China lọwọ.

Bẹẹ ba gbagbe, igbimọ ile asoju-sofin to wa fọrọ adehun lo ke gbajare sita lori adehun to wa nidi gbigba owoya lọwọ ilẹ China naa, eyi tijọba apapọ buwọlu.

Igbimọ ile naa wa pinnu lati se agbeyẹwo awọn ilana to wa nidi owoya ti Naijiria ti gba sẹyin lọwọ ilẹ China atawọn orilẹede miran lagbaye.

Aarẹ laelae bẹrẹ ni China

China ti f'ọwọ si fif'opin si iye saa ti aarẹ orilẹede le ṣe, nibi igbese kan to le je ki Aarẹ Xi Jinping maa se ijọba lọ karin.

Ile Igbimọ asofin orilẹede China lo ṣe awọn atunṣe (si iwe-ofin China) to fun aarẹ naa lanfani ati ma ṣe ijọba lọ lọjọ Aiku (Sunday).

Asofin 2,964 lo f'ọwọ si atunṣe naa, nigba, ti mẹji tako ti mẹta si kọ lati dibo.

Latin nkan bi ogun ọdun sẹyin ni China ti sofin to ni ki aarẹ ma lo ju saa meji lọ lori oye.

Sugbọn Ọgbẹni Xi, to yẹ ko sọkalẹ lori oye ni ọdun 2023, o kọ lati s'afihan ẹni ti ole jẹ aarẹ lẹyin rẹ nigba ipade ẹgbẹ Kọmunisti ninu osu kẹwa.

Kaka ko se bẹẹ, ofi ẹse ara rẹ rinlẹ lori oye ni nitori wipe ẹgbẹ pinnu lati fi orukọ rẹ ati igbagbọ iselu rẹ sinu iwe-ofin ẹgbẹ oselu naa- eleyi fun ni irufẹ agbega ẹni to da ẹgbẹ naa silẹ, Chairman Mao.

Botilẹ jẹ wipe iwe ofin sọ wipe ile igbimọ asofin lo lagbara ju ni China- gẹgẹ bi oti wa ni awọn orilẹede yoku. Sugbọn opọ eeyan nigbagbọ wipe igbimọ naa yoo f'ọ̀wọ si gbogbo nkan ti wọn ba ni ko f'ọwọ si.