Bobrisky: Ẹ má ṣe ìdájọ́ mi, mo ṣún mọ́ Ọ́lọ́run, máà sì lọ sí Mecca láìpẹ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilumọọka ọkunrin kan to lee mura bii obinrin tabi ọkunrin, Idris Okunneye ti ọpọ eeyan mọ si Bobrisky, ti sọrọ kikun nipa igbe aye rẹ.

Bobrisky, lasiko to n kopa lori eto ori ayelujara kan pẹlu agba akọroyin kan, Dele Momodu, salaye pe ọkunrin ni oun amọ oun maa n mura bii obinrin.

Bobrisky ni ipolowo awọn ọja obinrin ti oun n ta, bii ipara, ohun ẹsọ ara ati atọwọda irun obinrin lo mu ki oun maa se bii obinrin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n salaye idi to fi yan iru iwa naa laayo, Bobrisky ni awọn iwa bii were lo n jẹ awọn ọmọ Naijiria, ẹni to ba si nhuwa to tọ, ko le e riba ti se.

Bakan naa lo salaye pe, ọdọ iya oun ni oun gbe dagba nigba ti ipinya de laarin baba ati iya oun nitori bi iya oun se lọ si Mecca, lai bun baba oun gbọ.

"Iyawo mẹta ni baba mi ni, iya mi ni iyawo kekere laarin wọn, emi si ni abikẹyin rẹ. Mama mi ls si Mecca lai sọ fun baba mi amọ nigba to de, baba mi ko jẹ ko wọle, ni ipniya fi de saarin wọn."

"Mo bẹrẹ si gbe lọdọ iya mi, to si jẹ ki n mọ nipa ise awọn obinrin pupọ. Mo maa n ba iya mi fọ awọtẹlẹ rẹ, se ounjẹ ati isẹ ile ti awsn obinrin maa n se, ibẹ si ni ise awọn obinrin ti wu mi."

Bobrisky ni oun pari ile ẹkọ fasiti, ti isẹ ko si ni oun ba pinnu lati maa huwa to yatọ si ohun ti awujọ n fẹ, eyi ti yoo pe akiyesi awọn eeyan sọdọ oun, ti yoo si tun mu owo wọle.

O fikun pe idi ree ti oun fi n ta awọn eroja obinrin, ti oun si maa n mura bii wọn, lati fa oju wsn mọra si eroja ti oun nta, ati bo se dara si lara oun.

"Irọ nla ni pe awọn ọkunrin maa n ra dukia fun mi. N ko ni ifẹ ikọkọ pẹlu ọkunrin kankan nitori owo ara mi ni mo fi ra ile ti mo n gbe ati mọto mẹta ti mo n lo."

"Mo ni obinrin kan ti mo nifẹ si sugbọn n ko setan lati kede rẹ tabi igba ta se igbeyawo. Bi obinrin kankan ba si gbe oyun wa fun mi lasiko yii, n ko ni pariwo sita, ko maa ba ko okuta ba ọja mi."

Bobrisky, ẹni to kede pe Michael Jackson ni awokọse oun, tun ni oun kii se awokọse buburu fawọn ọdọ gẹgẹ bawọn eeyan kan se ri oun, arọwa oun sawọn ọdọ si ni lati lee da duro funra wọn.

Bobrisky ni oun sun mọ Ọlọrun pupọ, ti oun si maa n gbadura si i, ko si yẹ ki awọn eeyan maa foju ẹlẹṣẹ wo oun nitori o jẹ afojusun oun lati lọ ṣe Hajj nilu Mecca.

"Emi kii mu ọti lile tabi siga, adanilaraya ni mi, mo si mọ ọna ti mo n gba lati ba Ọlọrun mi sọrọ, ẹ mase se idajọ mi."

Mo fẹ́ fi àkàrà òyìnbó ọjọ ìbímí tọrẹ- Bobrisky

Lẹ́yìn ti àwọn ọlọpàá yabo ìbí àyẹyẹ ọjọ́ ìbí Okuneye Idris Olarewaju ti gbogbo ènìyàn mọ si Bobrisky lọ́ja sátide tí ayẹyẹ naà ko si lé wáye mọ.

Bobriksky ti fí ọ̀rọ̀ léde pé òun ti ṣetan láti fi àkàrà òyìnbó tí ó yẹ fún ayẹyẹ náà tọrẹ fún tọkọ́taya tí bá fẹ́ ṣe ìyàwó láìpẹ́ yìí.

Idris sàlàyé pé ko si irú ìkorira ti oun lé rí tí yóò mu ki òun dẹ́kun iṣẹ́ rere oun.

Gẹ́gẹ́ bi ìròyìn ṣe sọ, ọ̀rẹ́ rẹ̀ Tonto Dikeh lo gbàá nimọràn pé ki o jẹ́ ki àwọn jẹ àkàrà òyínbo náà tàbi ki àwọn bun èèyàn ló ba gbé àkàrà onipele mẹ́wàá náà si ojú òpó Instagram.

Lẹ́yìn naáà ni Bobrisky bá gbe sojú òpó Instagram rẹ̀ pé "àkàrà òyìnbó yìí yẹ ki o jẹ́ tí ọjọ́ ìbí mi ki wan to wọ́gile láì nídìí. Gẹ́gẹ́ bi mo ṣe máa ń sọ pé ọkàn mi kún fún wúrà, sùgbọ́n ọ̀ps àwọn oníkorira ń wá ìsubu mí. Tí ẹ ba ni ìgbáyawo ni òpin ọ̀sẹ̀ yìí, ẹ wá gbé àkàrà oyinbo yìí"

Tí ẹ ò bá gbàgbé àwọn ọlọpàá yabo ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Bobrisky lọ́jọ́ Satide tí ayẹyẹ ọjọ ìbí náà ko fi wáye mọ