Donald Trump: Ilẹ̀ Amerika nìkan ni wọ́n ń bímọ sí láti gba ìwé ìgbéèlú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Amerika, Donald Trump ti sọ wi pe oun yoo fopin si bi awọn asatipo se n bimọ si ilẹ Amerika lati gba iwe igbele.
Trump sọ eyi saaju eto idibo ti yoo waye ni ọsẹ kan si isinyin lati yan awọn asofin si Ile Igbimọ Asofin Agba ati Kekere lorilẹede naa.
Bakan naa ni wọn yoo ma dibo yan gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji ninu ipinlẹ aadọta lorilẹede Amerika.
Aarẹ Trump fikun wipe orilẹede Amerika nikan ni ọmọ ti wọn bi si ilu ti n gba iwe igbele nitori wọn bii sibẹ nikan.
Amọ, orilẹede Mexico ati Canada naa maa n fun ọmọ ni iwe igbelu nitori wọn bii si orilẹede naa.
Ẹ̀sùn apànìyàn ni wọ́n fi kan Robert Bowers'
Ọmọ ọdún 46 ni Robert ti wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó yìnbọn tó pa ènìyàn mọ́kànlá ni Sínágọ́ọ̀gù kan ni Amẹrika.
Pittsburg ni ipinlẹ Pennsylvania niṣẹlẹ yii ti wáyé ni orilẹ-ede Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eniyan lo farapa nigba ti afurasi naa da ìbọn bolẹ nile ijọsin Sinagọọgu ti wọn n pe ni: 'Tree of Life' lọjọ Abamẹta to kọja.
Awọn agbofinro ni lasiko ti ijọsin Sabbath wọn n lọ lọwọ lo kọju ibọn sawọn olujọsin naa.

Ẹsun mọkandinlọgbọn ni wọn fi kan ọkunrin ọmọ ọdun mẹrindinlaadọta yii bii didena ijọsin ati igbagbọ ẹlomii àti ipaniyan.
Oun funra rẹ naa faragbọgbẹ lasiko iṣẹlẹ nla ibi yii.
Bi ìṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ
Agbebọn kan ti ṣina fun awọn eeyan nile ijọsin kan nilu Pittsburgh Pennsylvania nigba ti wọn ṣe ijọsin lọwọ lọjọ aiku.
Awọn Ọlọ́pàa mẹta la gbọ pe o wa lara awọn to ti ku ṣugbọn awọn alaṣe ko ti sọ pato iye eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Arakunrin agbẹbọn naa gẹgẹ bi ohun ta gbọ farapa ninu ikọlu pẹlu awọn Ọlọ́pàa ti wọn si ti mu bayi si ahamọ.
Wọn ko ti darukọ agbebọn naa.

Oríṣun àwòrán, Google
Awọn Ọlọ́pàa si n to pinpin agbegbe ile ijọsin Tree of Life Synagogu ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Won ti kede bakannaa ki awọn ara adugbo ma se jade sita.
Aarẹ Trump si ti fi ọrọ sita loju opo Twitter rẹ pe oun fọkan ba iṣẹlẹ naa lọ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Isẹlẹ iyinbọn kii ṣe ohun ajoji lorileede Amerika
Lai pe yi ni Aarẹ Donald Trump ilẹ Amẹrika sọ pe asiko ti to ki ile aṣofin fọwọ si ẹkunrẹrẹ ofin ti yoo dẹkun ilokulo ibọn lawujọ.
O lede ọrọ naa nigba to'n ba agbarijọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ Democrat ati Republican sọrọ ninu ipade kan ti wọn ṣe afihan rẹ lori ẹrọ amohunmaworan.
Aarẹ Trump ni ki wọn tunbọ mu itẹsiwaju ba ayẹwo finifini ki wọn to o ta ibọn, ki wọn si sun ọjọ ori ti eeyan le ra ibon lati ọdun mejidinlogun si ọdun mọkanlelogun.
O sọ fun awọn aṣofin naa lati maṣe bẹru kikoju ẹgbẹ to'n ja fun lilo ibọn lamerika (NRA).
O sọ pe "Wọn le ni agbara lori yin, ṣugbọn wọn ko lagbara lori mi."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba ti o'n du ipo aarẹ lodun 2016, ẹgbẹ NRA fi o'ntẹ lu iyansipo Trump.
Ni ṣe ni o'n sọ ọrọ yi nipa NRA lati igba ti iṣẹlẹ iyinbọnpaniyan ti waye ni ile ẹkọ kan lọjọ kẹrinla oṣu keji ọdun yii ni Parkland, nilu Florida.













