Ọkọ àti ìyàwó lu ọmọ wọn, ọmọ oṣù mẹ́wàá pa sínú balùwẹ̀, àṣírí tú!

Stephen Boden ati iyawo rẹ Shannon pa ọmọ wọn Finley Boden lọjọ ọdun, ilé ẹjọ si ti da wọn lẹbi ẹsun pe lootọ ni wọn pa a.

Lẹyin ọjọ mọkandinlogoji ti fi ọmọ ikoko naa si ikawọ wọn ni wọn ṣe iṣẹ ibi naa.

Pẹlu iwadii ati oun ti ile ẹjọ ri, apa ifarapa to to aadoje (130) ni wọn ba ni ara ọmọ naa.

Nibayii, ile ẹjọ ti dajọ pe awọn tọkọtaya ọhun to wa lati Chesterfield, Derbyshire jẹbi ẹsun ipaniyan nile ẹjọ Derby Crown Court lọjọ Ẹti ti wọn yoo si ṣe idajọ wọn ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu karun ọdun yii.

Ile ẹjọ da wọn lẹbi lẹyin ti ile ẹjọ ṣalaye pe wọn fi ina jo ọmọ naa wọn si tun na a ni ọpọ igba.

Lara ifarapa ti Finley ni ni egungun mẹtadinlọgọta to ti kan lagọ ara rẹ, egbo mọkanlelaadọrin ati ijona lọna meji lapa osi rẹ, ọkan lara rẹ jẹ latara nnkan gbigbona, ekeji ṣeeṣe ko jẹ latara ina siga.

Ọmọ ikoko naa wo lulẹ lẹyin to ṣaisan latari ikọlu ọkan ninu ile ti ẹbi naa n gbe to dọti to si ri jakujaku ni agbegbe Holland Road, Old Whittington - nibi yii ti wọn tun pada ba igbẹ ninu yara.

Ki ni tọkọtaya ọhun ṣe?

Ọkọ atiyawo rẹ yii naa lo pe awọn oṣiṣẹ afara jọ eleto ilera ni owurọ ọjọ ọdun keresi ti wọn si gbe Finley lọ si ile iwosan nibi ti awọn dokita ti pada kede pe o ti ku.

Awọn agbẹjọro bu sẹkun nile ẹjọ

Adajọ Tipples gbiyanju lati ma bu sẹkun nigba to n ba awọn adajọ sọrọ ninu ile ẹjọ to si dupẹ lọwọ wọn pupọ fun bi wọn ṣe ro ẹjọ ọhun titi di igba ti wọn pari. Mẹri ninu awọn agbẹjọro lo bu sẹkun bi adajọ naa ṣe n sọrọ.

Nitori ati le tọju ọmọ gaan lo jẹ ki wọn gba Finley kuro lọwọ awọn obi rẹ laipẹ igba ti wọn bii ninu oṣu kejila ọdun 2020.

Ṣugbọn nigba to ya lọdun naa, wọn tun da ọmọ naa pada fun wọn lati tọju amọ pẹlu aṣẹ ile ẹjọ ọlọsẹ mẹjọ.

Ile ẹjọ pada gbọ pe awọn mejeji n rii daju pe wọn n le awọn akọṣẹmọṣẹ jina si wiwa wo ọmọ naa lati lee bo iwa ipa ti wọn n ṣe sii mọlẹ.

Fun apẹrẹ, wọn fagile ibẹwo oṣiṣẹ eleto ilera kan ni o ku ọjọ meji ti ọmọ naa ku wọn si sọ fun awọn alaṣẹ nigba ti wọn de lai sọ fun wọn pe Finley ti ni arun Covid-19, wọn ko si jẹ ki wọn wọle.

Nibayii, wọn ti gunle iwadi finifini lori jọ yii tori o ni ṣe pẹlu ọmọde.

"A n da ayẹwo naa ṣe ni ko si ni tọna lati sọ ohun gbogbo jade bayii ayafi bi a ba pari lati le rii daju pe a o sọ ohun ti ko tọ" Agbẹnusọ ijọba kan ni Derbyshire County Council sọ bẹẹ́.

Ile ẹjọ tun gbọ pe ọkọ ati iyawo ọni ọgbọn ọdun ati ọdun mejilelogun naa jẹ awọn ti wọn maa n mu igbo ti wọn si mu eyi lọkunkundun to bẹẹ ti wọn maa n ko owo lee lori ju lati na fun ọmọ wọn lọ.

Ayẹwo kan to n jẹ "Toxicology test" fihan pe wọn ba igbo ninu ẹjẹ Finley eyi to fihan pe o ṣeeṣe ko ti fa eefin igbo simu ni nnkan bii wakati mẹrinlelogun ṣaju iku rẹ, wọn sọ eyi fun ile ẹjọ.

Bakan naa, wọn fi awọn ọrọ atẹjiṣẹ ori foonu laarin ọkọ ati iyawo naa han ile ẹjọ eyi ti wọn si sọ fun adajọ pe awọn ọrọ atẹjiṣẹ wọn ko ye gaara.

Diẹ lara atẹjiṣẹ ori foonu naa ni ọgbọnjọ oṣu kejila ọdun 2020 ka bayii pe: "Ọmọ kekere yẹn ti mu mi laju silẹ lati oru mọjumọ". Ọrọ naa tun fi kun un pe: "Mo fẹ laa mọ awọn ogiri. Haha."

Agbẹjọro olupẹjọ Mary Prior KC sọ pe Boden sọ fun ibatan rẹ kan pe Finley ti maa n sọkun, to si ni oun gbọn ọn diẹ.

Ẹni naa nigba to lọ ṣe ibẹwo si Finley nileewosan ni ọjọ kọkanla oṣu kini ọdun 2021 sọ ọrọ jade pe: "Baba rẹ na a titi doju iku, Mi o daabo bo o."

Ni ti Boden, o ni o ṣeeṣe ko jẹ pe aja awọn lo fo gija le ọmọ oun, to si jẹ ki ọpọlọpọ egungun rẹ kan to si ni ibi ẹnu Finley to ya lee jẹ nnkan iṣere ti o ki bọ ẹnu funra rẹ.

Ẹwẹ, Insipẹkitọ ọlọpaa sọ pe ọkan lara awọn ibi teeyan ti le ri abo ju lagbaye ni Finley ku si eyi tii ṣe ile ara rẹ. O ni oun lero pe idajọ to n lọ lọwọ yoo kan awọn to sunmọ ẹbi Finley pẹkipẹki.