Lagos state; Ó kéré tán ẹran N328 bilionu ni àwọn ará Eko ń jẹ ní ọdọọdún

Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe o kere tan ẹran biliọnu ọọdunrun o le ni awọn ara Eko n jẹ ni ọdọọdun.

Akọwe agba ni ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to n risi ọrọ iṣẹ agbẹ, Ibironke Emokpae lo fi iroyin naa lede.

Akọwe Agba to ṣoju fun kọmisọnna nibi ipade ti wọn ti pe awọn oniṣowo lati wa dowopọ pẹlu ijọba lori eto ọṣin maluu.

Ijọba ni o ṣeni laanu pe ida aadọrun ninu ẹran yii lo n wa lati ariwa orilẹede Naijiria.

Kini ijọba Eko n ṣe lati pese ẹran labẹle?

O fikun pe ida piniṣin to ku nikan ni wọn n ṣe ni abẹle, eleyii ti ko to awọn eniyan lati jẹ.

Bakan naa ni wọn fikun un pe gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti gbe awọn eto kalẹ ni ẹka eto ọgbin ti yoo mu ki ẹka naa gbooro si ju ti tẹlẹ lọ.

Ijọba ipinlẹ Eko naa fikun un pe eto yii yoo pese ounjẹ ati eto ọgbin fun awọn eniyan ti wọn ko ni nilo ati maa lọ si ariwa Naijiria, ki wọn to le ni eto ọgbin to gbooro.

Wọn fikun un pe pẹlu eto ti ijọba Eko fẹ ṣe agbẹkalẹ rẹ yii yoo rọrun lati sin maluu ọlọgọọrọ loju kan naa, ti eyi yoo si pese ẹran lọpọ yanturu fun awọn ara ipinlẹ Eko.

Bakan naa ni yo fi opin si iyan ounjẹ ni ipinlẹ Eko ati lorilẹede Naijiria.