Alaafin's cultural ambassador: Dr Paula Gomez sọ nípa iṣẹ́ tó pa òun àti Alaafin pọ̀

"O ti to ọdun mejila ti mo ti wa pẹlu Kabiyesi, Kabiyesi fi mi jẹ oye Aṣoju Aṣa lati ọjọ yii si la ti n ṣiṣẹ lorii pipa aṣa ati iṣẹṣe mọ".

Ọmọwe Paula Gomez to ti jẹ alabaṣiṣẹpọ fun Alaafin Oba Lamidi Adeyemi to ti darapọ mọ awọn baba nla baba rẹ sọrọ ninu fọnran kan nipa gbogbo iṣẹ to pa oun ati Alaafin pọ.

Oyinbo alawọfunfun naa ninu to jade sori ayelujara ṣalaye pe titi dori gbogbo ibi iṣẹmbaye ati ojubọ lawọn ti n ṣiṣẹ lori bi ẹmi wọn yoo ṣe gun.

O ni gbogbo igba ni Oba Lamidi Kẹta maa ṣatilẹyin fun itan abalaye iran Yoruba.

"Iku Baba Yeye ni oludasilẹ ati Aarẹ ẹgbẹ ibilẹ "AṢA ORIṢA ASSOCIATION", ẹgbẹ ti o da silẹ lati da abo bo, ati lati ṣe igbelarugẹ abalaye Oriṣa".

Gẹgẹ bi Ọmọwe naa ṣe sọ, awọn akọsilẹ iṣẹṣe aṣa wọnyii ni Ọba Adeyemi pẹlu ajọṣepọ aṣoju orilẹede Naijiria si ẹka ajọ isọkan agbaye UNESCO fi ẹsẹ wọn mulẹ nipa ilu Oyo.

  • Ayẹyẹ Ọdun Ṣango nilu Oyo
  • Oriṣa dida/ / Idáàsà / Érìndínlógún
  • Ilana iṣejọba Ọba ni Oyo Alaafin - Igbákejì Òrìsà

Awọn nkan mii to ni ṣe pẹlu aṣa Yoruba ti wọn fi ẹsẹ wọn mulẹ ni gbagede agbaye ni:

Iṣẹ Ilu Ṣiṣe, finfin igba, Aṣọ Oke hihun, Ọṣẹ Dudu ṣiṣe, ayẹyẹ Ọdun Egungun, ayẹyẹ Ọdun Ifa, ayẹyẹ Ọdun Ọbaluaye.

Ki lo yẹ koo mọ nipa Oyinbo oṣiṣẹ Alaafin Oyo?

Ọmọwe Paula Gomez jẹ ọmọ orilẹede Portugal ti awọn eeyan ti pade ni aafin Alaafin Oyo lọpọ igba.

Ede Yoruba ẹnu rẹ, awo-maleelọ ni leyi to maa n fa oju awọn eeyan bo ṣe jẹ irinṣẹ pataki loju wọn bi ololufẹ́ aṣa.

Iroyin ni lati ọdun 1990 to ti de si Naijiria lo ti n gbe ni ipinlẹ Oyo to si n gbe aṣa Yoruba ga.

Gomez ni ifẹ fun ṣiṣewadii wọ inu aṣa Yoruba jinlẹ lo gbe oun de ipinlẹ Eko ni ọdun mejidinlọgbọn sẹyin eyi si jẹ lasiko to n kọ imọ ẹkọ nipa itan ni Germany.

O dun un ninu gidi gan nigba to rii pe iṣẹ pa oun ati Ikubabayeye Ọba Olayiwola Adeyemi Lamidi pọ lori aṣa iṣẹmba.

Ko to ba Alaafin ṣiṣẹ lo ti maa n sọrọ iwuri ati oun aatẹle nipa aṣa Yoruba ati bo ṣe ṣawari pe Alaafin jẹ olufẹ aṣa ati iṣẹṣe gidi gan.