Fani-Kayode: Kò sẹ́ni tó mọ ìgbà táwọn ọmọ Nàíjíríà yóò fárígá láti kọ ìyà tó ń jẹ wọ́n

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Minisita fun irinna ofurufu nigbakan ri lorilẹede Naijiria, Amofin Fẹmi Fani Kayọde ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari pe o ni alaye lati ṣe fọmọ Naijiria lori ọwọja ipaniyan to n waye ni tibu-toro orilede yii.

Ninu atẹjade kan to fi si oju opo Twitter rẹ l'Ọjọbọ, Fani Kayọde to ṣẹṣẹ sa kuro lẹgbẹ oṣelu PDP lọ APC laipẹ yii ṣalaye pe, iwọnba oṣu perete lo ku fun Muhammadu Buhari nipo aarẹ Naijiria.

O fikun pe idi ree to fi yẹ ko fi opin si gbogbo iwa ipaniyan ati ipa to n waye kaakiri Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O sọ ọ siwaju sii pe oorun to ku nita yii ṣi too sa aṣọ fun aarẹ lati wa ojuutu si iwa ipaniyan lọgọọrọ, igbesunmọmi ati inira tawọn agbebọn fi n bẹ awọn araalu wo, ki O to kuro nipo.

"Ka pa t'oṣelu ti ka sootọ. Ọgọrun eeyan ni wọn pa nipinlẹ Plateau, marundinlọgbọn mii lawọn agbebọn tun ṣa pa ni Benue. Itiju gba a leyi ko si ni awijare kankan rara."

Fani Kayọde woye pe ko sẹni mọ igba ti awọn ọmọ Naijiria yoo fariga lati kọ iya to n jẹ wọn o, tabi iye awọn eeyan tawọn agbenipa wọnyii yoo tun pa ki awọn ọmọ Naijiria to dide pẹlu ibinu pe 'O to gẹ'

Ọna abayọ, gẹgẹbi Fani-Kayode ṣe sọ:

Minisita tẹlẹ naa ni aaye ṣi wa fun ijọba apapọ labẹ Aarẹ Buhari lati ṣatunṣe ohun gbogbo to ba yẹ.

Fani ni ijọba Naijiria gbọdọ ro awọn ileeṣẹ alaabo gbogbo lagbara ko si fun wọn ni aṣẹ ti ko lẹjambakan ninu lati lọ ree koju awọn agbebọn wọnyii dipo jijoye afẹa jẹ, maa fẹ a yoo, tii fun ni loko idi ọpẹ ro.

O ni ki ijọba tun gbe igbesẹ akin lati yọju gbogbo awọn to wa nidi iwa buruku wọnyi sita, ki ijọba yee huwa bi ẹni to n gbe lẹyin awọn ọbayejẹ naa.

Ki lawọn abajade iwadii gbogbo nsọ?

Ọpọlọpọ iroyin lo n jade pe nnkan bii ẹgbẹrun mọkanla awọn eeyan lati ẹya Berom nipinlẹ Plateau lawọn agbebọn ti pa lati nnkan bii ogun ọdun sẹyin.

Bakan naa lawọn iroyin kan n sọ pe nnkan bii ileto mejidinlaadọrin lawọn darandaran Fulani ti le awọn olugbe ibẹ danu ti wọn si ti n gbe ibẹ gba ilu wọn nibẹ.

Abajade iwadi kan laipẹ yii tilẹ tun sọ pe ẹgbẹrun mẹfa lawọn eeyan eeyan to ti fi ile ati ọna wọn silẹ nitori lemọlemọ ikọlu awọn agbebọn lagbegbe ijọba ibilẹ Kanam nipinlẹ Plateau ti awọn eeyan naa si ti lọ n fi ara pamọ si awọn ọja ati ileewe kaakiri.