You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
FFK Defection: Adesina kan sáárá sí ìwà akin Fani-Kayode, ó ní kò rọrùn fún láti kó èébì rẹ̀ jẹ
FFK ti ko eebi rẹ jẹ, Buhari dara pẹlu bo se gba ọmọ oninakuna pada sile - Femi Adesina
Bi minisita feto irinna ofurufu tẹlẹ, Femi Fani-Kayode, FFK se pada sinu ẹgbẹ oselu APC to ti kuro lọ si PDP, lo se afihan pe aja rẹ ti ko eebi ara rẹ jẹ.
Oludamọran pataki si aarẹ Buhari feto iroyin, Femi Adesina lo woye ọrọ yii ninu ọrọ apilẹkọ nipa isẹ aarẹ to maa n gbe jade lọsọọsẹ.
Adesina ni igbesẹ kiko eebi jẹ ti FFK gbe nira pupọ, aimọye ọpọ eeyan si ni ko le se iru rẹ.
- Judasi ìran Oduduwa ni Femi Fani-Kayode pẹ̀lú bó ṣe darapọ̀ mọ́ APC- Sheikh Gumi
- Yorùbá ẹ fura o! Ìwẹ̀fá ìjọba àpapọ̀ gbáà ní Fani-Kayode tó ń díbọ́n bí ọ̀kan lára wa
- Ọjọ́ tò burú jùlọ nínú ìrìnàjò oṣèlú mi ni ọjọ ti FFK darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC- Ojudu
- A kìí ṣọ̀rẹ́ èrò ká yọ̀ lọ̀rọ̀ Fani-Kayode, ajá rẹ̀ kò mọ ẹni a kìí gbó mọ́ - Salihu Lukman
- Ẹ́ yé parọ́ mọ́ mi kiri, n kò múra ìgbéyàwó, ọ̀rẹ́ lásán ni Halima - Femi Fani-Kayode fọnmú
Adesina ni "Tẹ ba woo daa daa, se o rọrun rara ki eeyan ko eebi ara rẹ jẹ? Rara o. Amọ ohun ti FFK se ree.
Ẹ wo gbogbo awọn ọrọ kobakungbe ti Fani-Kayode ti sọ si aarẹ Buhari ati ijọba rẹ, ẹgbẹ oselu APC atawọn eeyan mii to wa ninu ijọba.
Gbogbo awọn ọrọ yii ni FFK ko jẹ, se o wa dun lẹnu rẹ ni? Rara o, puẹ, eebi gan yoo maa gbe eeyan.
Nitori naa, ẹ jẹ ka kan saara si iwa akikanju to hu, iru abuda yii ko sọwọn, kii si se ọpọ eeyan lo le se iru rẹ."
Nigba to n salaye idi ti Buhari fi gba FFK pada si agbo ẹgbẹ APC, o ni oju aanu nla ni aarẹ si wo Fani-Kayode yii lati gba ọmọ oninakuna rẹ pada sile.
"Bi aarẹ Buhari se gba FFK pada, to si gbalejo rẹ nile ijọba Aso Rock, se afihan ẹmi idarijin nla, isiju aanu wo ni ati asa ẹ jẹ ki ohun to ti kọja, maa kọja lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Ká ní wọ́n fún Awolowo láyèè láti tukọ̀ Nàíjíríà ni, nǹkan kò ní rí báyìí"
- Buhari san $500 fáwọn aláwọ̀ dúdú l‘Amẹ́ríkà láti takò ẹ̀hónú wa - Yoruba/Biafra Nation
- Ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ ló fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ mí, àyàfi Dudu Heritage nìkan
- A pàdánù Ìyá Nkechi Blessing láìpẹ yìí- Toyin Abraham
- Mílíọ́nù méje èèyàn ni ìdọ̀tì inú afẹ́fẹ́ "Air polution" ń pa lọ́dọodún - WHO
- 'Ó kéré tán, Nọ́ọ̀sí alábẹ́rẹ́ 7,000 ló ń sá kúrò ní Nàìjíríà ní ọdọọ́dún'
- "Màálù tó ya sójú pópó kọlu ọ̀kadà ọkọ mí, tó sì kú ní ìkómọ ọmọ rẹ ku ọ̀la"
- Sunday Igboho kò tíì bọ́ lọ́wọ́ wa, á fi ẹ̀sùn míì kàn-án - Malami
Eeyan melo lo le se iru eyi, wọn ko pọ rara.
Buhari siju aanu wo FFK, bii iri aanu to n ṣẹ lati ọrun amọ to ba jẹ ẹyin ni, ẹ tutọ soke, fi oju gbaa ni, tẹ si ni bi FFK ba le ku, ko lọ ku.
Amọ Buhari ko se eleyi amọ o se afihan abuda Ọlọrun ọba, tii se nini ẹmi idarijin.
Ìjọba ẹ má wòran, àjà ilé Aṣòfin tó ń jò le wó lé wa lórí - Aṣòfin sọ̀rọ̀ ṣókè!
Adari awọn ọmọ ile Aṣofin to kerejulo, Ndudi Elumelu ti kegbare pe ẹmi awọn wa ninu hila hilo pẹlu ile aṣofin to n jo le wọn lori ni gbogbo igba.
Elumelu to wa lati ẹgbẹ oṣelu PDP ni omi to n jo ni gbogbo igba le wọn lori fihan pe aja Ile Aṣofin ti baje, ti o si le wo nigba kugba.
O ni o lewu ki awọn aṣofin ma a ṣepade ijoko ile ni iru agbegbe bẹẹ lai naani ẹmi wọn to wa ninu ewu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo èèwọ̀ mẹ́wàá to fi lè bọ́ lọ́wọ́ ewu iná gáàsì
- Ondo School Without Chairs: Iléèwé kan rèé tí kò ní àga, tábìlì, olùkọ́ àti ohun èèlò ìkẹ́kọ̀ọ́
- Tá à bá ti ibodè tó wọ Naijiria, ìyà kò bá jẹ wá lásìkò Coronavirus - Buhari
- Ọ̀run yóò ya bọ́ tí ààrẹ kò bá wá láti ẹ̀kùn gúúsù Nàíjíríà - Joe Igbokwe
- Kí ló ń fa ikú ọ̀wọọ̀wọ́ lẹ́yìn Davido?
- Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Goodluck Jonathan ti sọ̀rọ̀ sókè, Ó ní wàhálà Nàìjíríà fẹ̀rẹ̀ gbẹ̀mí ìyá òun
- Ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ agbébọn Boko Haram ló ti jọ̀wọ́ ara wọn sílẹ̀- Iléeṣẹ́ ológun
- Òhun tó sẹlẹ̀ kò tó kí àjọ AMCON gbẹ́sẹ̀lé nkán ìní mí-Abdulfatai Ahmed
- "Àìsàn tó ń ṣe Iyabo Oko ti ṣàkóbá fún ọmọ ìka ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀"
- "Makinde gbà wá, àkàsù ọta ìbọn láwọn ológun Odogbo ń rọ̀jò lé wa lórí"
Adari awọn ọmọ ile Aṣofin to kere julọ naa wa kesi awọn alaṣẹ Ile Igbimọ Aṣofin lati tete wa nkan ṣe si ọrọ naa ni wara n ṣesa.
''Ohun to n ṣẹlẹ ni Ile Igbimọ Aṣofin yin n kọ mi lominu lo jẹ ki n dide sọrọ ni asiko yii.''
''Olori ile, ti ẹ ba wo yika, ẹ o ri pe omi lo yi wa ka nitori aja ile Asọfin n jo, ti a si gbọdọ wa nkan ṣe si ni kiakia, nitori ko si ẹnikẹni to le e sọ nkan to le e ṣẹlẹ.''
''Ko si igba ti a wa si ibi yii ti awọn gbalẹ-gbalẹ ko si nibẹ, ti wọn n ko omi to n jo si inu ile aṣofin, eleyii si lewu pupọ ni oju mi.''
''Ko ṣeeṣe ki a ma a ṣiṣẹ wa lojoojumọ pẹlu ojo to n rọ le wa lori yii, Abẹnugan, ẹ wa nkan ṣe si ki ọrọ to bẹyin yọ.''
Abẹnugan Ile Aṣofin nigba, Femi Gbajabiamila lasiko to n fesi si ọrọ naa ni ohun ti wọn gbọdọ mu ni ọkunkundun ni adari ọmọ ile aṣofin to kerejulọ sọ.
Igba akọkọ kọ ni yii ti Ile Igbimọ Asofin ti ma n jo loore-koore paapaa nigba ti ojo ba rọ, gbogbo agbegbe naa ni yoo kun fọfọ.