Nursing and Midwifery Council of Nigeria: Nàìjiíríà pẹ́lù ibi ti àwọn nọ́ọ̀sí wọn ti kúnjú òṣùwọ̀n jùlọ ní àgbáyé

Akọwe agba ajọ Nursing and Midwifery Council of Nigeria, Dr Faruk Abubakar ti ni o kere tan ẹgbẹrun meje awọn nọọsi ni wọn n kuro lorilẹede Naijiria lọ si ibomiran ni ọdọọdun.

Abubakar ni eyi fihan gbangba pe awọn nọọsi lorilẹede Naijiria pẹlu awọn to lamilaaka, ti wọn si mọ iṣẹ wọn ni iṣẹ kaakiri agbaye.

Ni ipinlẹ Delta ni Abubakar ti sọ ọrọ yii lasiko to n gba awọn nọọsi ti wọn ṣẹṣẹ ṣe idanwo abajade tan ni iyanju nipinlẹ naa.

Abubakar ni o pọn dandan ki awọn nọọsi tẹ ipa mọ iṣẹ wọn, ki idagbasoke tunbọ ma a ba wọn lẹnu iṣẹ lai ni ifasẹyin.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn onimọ ni ẹka eto ilera kaakiri Naijiria ṣe n fi orilẹede naa silẹ lọ si ibomiran nitori aiṣedede ijọba apapọ si wọn, ti wọn ko san owo oṣu wọn deede ati aipese awọn ohun elo ti wọn nilo lati ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ.

Amọ, kọmiṣọnna fun eto ilera nipinlẹ Delta, Dokita Ononye bu ẹnu atẹ lu bi awọn nọọsi ṣe n kuro ni Naijiria ni ọgọọrọ lọ si awọn orilẹede miran

Ononye ni ti ijọba ko ba bojuto ọrọ yii ni kiakia, nkan yoo tunbọ bajẹ si ni ẹka eto ilera ni Naijiria.

''O ṣeeni laanu wi pe awọn nọọsi ati dokita ti wọn gba ẹkọ ni Naijiria ni owo perete wa n kuro lorilẹede naa lọ si ibomiran lati lo lo imọ wọn fun awọn ibi ti wọn lọ tẹdo si.''

''Eleyii jẹ ibanujẹ ọkan fun awọn adari ni ẹka eto ilera lorilẹede Naijiria nitori eto ilera ti mẹhẹ sibẹ tẹlẹ.''

Kọmisọnna fun eto ilera nipinlẹ Delta wa rọ awọn nọọsi naa lati tẹpa mọ iṣẹ wọn, ki ijọba naa si gbiyanju lati mu igbega ba eto ilera ni Naijiria.